Ìdí gan-an tí Olóòtú ìjọba Canada, Justin Trudeau fi kọ̀wé fipò sílẹ̀?
- Author, Jessica Murphy
- Role, BBC News, Toronto
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Fun ọpọlọpọ oṣu ṣaaju ikede rẹ, ni ọpọ eeyan ti n beere lọwọ Olootu ijọba Canada, Justin Trudeau, pe ṣe yoo kọwe fipo silẹ.
Trudeau ti pinnu lati duro gẹgẹ bii olori ẹgbẹ oṣelu Liberal – pẹlu bi ede ayede ṣe n waye laarin awọn oludibo ati awọn oloṣelu.
Ọpọ gbagbọ pe Trudeau ko de le duro pẹlu bii ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ se n pariwo pe ko juwọ silẹ.
Lasiko ti Trudeau ba awọn akọroyin sọrọ, o ni orilẹede Canada nilo olori to koju oṣuwọn ninu eto idibo to n bọ,
"O si ti han gbangba si mi pe, ti mo ba n ja ija inu ile, n ko le koju oṣuwọn lati gbe apoti ibo".
Ọjọ Aje ni Trudeau kede pe oun ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii Olootu ijọba niwaju Radeau Cootage, ile ijọba to ti wa fun lati ọdun 2015.
Bakan naa lo kede pe oun yoo ṣi di iṣakoso mu gẹgẹ bii Olootu ijọba titi ẹgbẹ oṣelu Liberal yoo fi yan olori mii, ni ọjọ ti wọn ko ti kede.
Trudeau ti bere fun idaduro ile igbimọ aṣofin titi ti ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ọdun 2025.
O le ni ọdun mejila ti Trudeau lo gẹgẹ bii olootu ijọba.
Lẹyin ọdun mẹsan an, Trudeau di ọkan lara awọn olootu ijọba to pẹ ju lori ipo.
Oun nikan lo ku ninu awọn olori orilẹede ti wọn jọ bọ ṣipo lasiko kan naa bi Barack Obama, Angela Merkel, Shinzo Abe ati David Cameron.
Ninu eto idibo ọdun 2019, ẹgbẹ oṣelu Trudeau koju ijakulẹ , to tumọ si pe ẹgbẹ oṣelu Liberal nilo iranlọwọ ẹgbẹ oṣelu yooku lati le wa nipo olori.
















