Ẹbọ ni tàbí ìpèsè? Àjòjì abọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí wọ́n ń gbé s'óríta ń kọ aráàlú l'óminú ní UK

Aworan ẹbọ ọgẹdẹ
    • Author, Harry Stevens
    • Role, BBC News, Nottingham
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ki ni ka ti gbọ pe awọn eeyan kan n gbe ẹbọ si igbooro ilu UK.

Ilu kan ni Nottingghamshire ni awọn eeyan ibẹ ti ṣadeede n ri abọ ọgẹdẹ ti wọn ti bo epo ara rẹ ni orita, ti ko si si ẹnikẹni to le sọ pato pe eeyan bayii lo gbe sibẹ.

Iwa yii lo fẹ fara jọ gbigbe ẹbọ si orita, eyi to jẹ aṣa ile Yoruba ati awọn apa ibi kan ni ilẹ Africa.

Ọjọ keji ninu osu ni awọn eeyan ma n ṣalabapade abọ ọgẹdẹ ọhun, ni oju ọna Abbey ati ni Wensor Avenue ni Beeston, ti awọn olugbe si jẹ ko di mimọ pe, o le ni ọdun kan ti awọn ti n ri nnkan yii.

"Mo ti bere kaakiri gbogbo agbegbe ṣugbọn ko si ẹnikẹni to mọ nipa ọgẹdẹ ti wọn n gbe kalẹ yii.

Aworan Arabinrin Short

"Awọn ọgẹdẹ yii ni mo ma n rii ni ọjọ keji oṣu. Mo n ma n ri ti mo ba n lọ si ibi iṣẹ mi. Mo n wa idahun si awọn ibeere mi."

Awọn Ipese ọgẹdẹ ọhun lo ti fa ọpọ ariyanjiyan ni agbegbe naa pẹlu bi o ṣe ma n run lẹyin to ba bajẹ sibi ti wọn gbe si.

Arabinrin Short gbiyanju lati gbe igbesẹ lọwọ ara rẹ.

O gbe ikilọ sita pe ki wọn ma gbe ọgẹdẹ si agbegbe naa mọ.

Ni ọjọ keji oṣu Kinni, wọn tun ri abọ ọgẹdẹ mii ni agbegbe naa ti wọn gbe silẹ.

"Mo ti wa yọ ikilọ ti mo gbe sita nitori n ko fẹ ko da bi pe ija ni tabi ko di nnkan nla," O ṣalaye.

"Mo ri pe gbigbe ọgẹdẹ silẹ jẹ nnkan pataki fun eeyan to n gbe sibẹ.

"Ṣugbọn yoo dara ti wọn ba le pada wa lati wa se atunṣe ibi ti wọn gbe si.

"Maa tẹsiwaju lati se atunṣe ibi ti wọn gbe ẹbọ naa si."