Ṣọ́jà mẹ́fà kú nínú ìkọlù ISWAP ni Borno

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti fidi ẹ mulẹ, pe ṣọja mẹfa lo jade laye ninu ikọlu awọn ẹgbẹ alakatakiti ti a mọ si 'Islamic State in West Africa' (ISWAP), to waye ni Sabon Gari, ipinlẹ Borno.
Ọjọ Satide ni ikọ agbesunmọmi naa kọlu awọn ologun.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ologun Naijiria, Ọgagun Edward Buba, fi sita laaarọ Ọjọruu, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2025, ṣalaye pe ọmọ ogun mẹfa lo ku ninu ikọlu yii, nigba ti olori awọn fijilante kan farapa.
"Ikọ naa jẹ akojọpọ ologun (Civilian Joint Taskforce), fijilante ati awọn mi-in. Wọn tete debẹ lati koju awọn agbesunmọmi ọhun. Ikọ yii ṣalabapade ado oloro, eyi to ṣe adari fijilante kan leṣẹ."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.
O fi kun un pe awọn onijihaadi agbebọn mẹrinlelọgbọn (34 jihadist fighters), ni wọn ku ninu ikọlu yii, bẹẹ ni awọn gba nnkan ija lọwọ wọn.
Ọgagun Buba sọ pe awọn agbebọn naa fẹẹ yọ sawọn sọja lojiji ni, ki wọn si gbẹsan iku olori wọn tawọn ologun pa laipẹ yii.
" Ikọlu yii ba awọn agbesunmọmi lojiji, ikọ ologun ba ero wọn jẹ lẹsẹkẹsẹ ti ikọlu naa bẹrẹ. Ikọ ologun Operation HADIN KAI gbaya awọn ọlọtẹ to n sa lọ"
"Èyi ni ìgbàkejì láàárín oṣù méji tí agbésùnmọ̀mí pa ṣọ́jà"
Ninu oṣu kọkanla ọdun 2024 ni awọn agbesunmọmi pa ọmọ ogun Naijiria to le ni mejila, lasiko awọn ikọlu kan to waye ni ibudo awọn ologun to wa ni Kareto, nijọba ibilẹ Mobbar, iponlẹ Borno.
Ikọlu eyi to ṣẹṣẹ ṣelẹ yii lo ṣikeji.
Awọn arijagba ti wọn sa sabẹ asia ẹsin Islam naa n tẹswiaju ninu kikọlu awọn eeyan agbegbe ati awọn ibudo ologun, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ oloun n sọ pe awọn n bori ogun naa.
Apa Ariwa-Ila Oorun Naijiria (Northeast) ti wa lẹnu iṣoro awọn ẹgbẹ onijihaadi yii fun igba pipẹ, bẹrẹ lati ori ẹgbẹ Boko Haram to gbajumọ ju, ati orogún wọn ti a mọ si Islamic State in West Africa (ISWAP).














