Ta ni Éric Chelle tí àjọ NFF kéde gẹ́gẹ̀ bíi akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun fún Super Eagles Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, SoccerNet NG/Facebook
Ajọ to n dari ere idaraya lorileede Naijiria, Nigeria Football Federation, NFF ti kede gbajugbaja agbọọlu orileede Mali nni, Éric Sékou Chelle gẹgẹ bi akọnimọ-ọn-gba tuntun fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles.
Éric Chelle ni yoo jẹ akọni-mọ-ọn-gba kẹta fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, latigba ti Jose Peseiro ti kọwe fipo silẹ ninu oṣu Kẹta, ọdun 2024.
Ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni ajọ NFF kede Éric Chelle, lẹyin bii wakati meloo kan ti Aarẹ Ibrahim Gusau ti sọ ninu fọnran kan wi pe iyansipo ọhun yoo waye laipẹ jọjọ.
"Igbimọ iṣakoso ajọ Nigeria Football Federation ti buwọ lu ẹni ti igbimọ Technical and Development Sub-Committee yan, Ọgbẹni Éric Sékou Chelle gẹgẹ bi akọni-mọn-ọn-gba fun ẹgbẹ agbabọọlu agba, Super Eagles," NF sọ ninu atẹjade to fi sita.
"Nibi ipade to waye niluu Abuja l'Ọjọbọ, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2025, igbimọ NFF Technical and Development Sub-Committee ti kede iyansipo akọni-mọn-ọn fun ẹgbẹ agbabọọlu orileede Mali tẹlẹ, gẹgẹ bi akọni-mọ-ọn-gba tuntun fun Super Eagles. Orukọ ti wọn fi ranṣẹ yii ni igbimọ iṣakoso agba fun ajọ NFF buwọ lu lọjọ keje, oṣu Kinni."
Gẹgẹ bi Aarẹ NFF, Gusau ṣe sọ, o ni iṣẹ Chelle yoo bẹrẹ loju ẹsẹ fun igba akọkọ nibi idijẹ 2024 African Nations Championship to fẹẹ waye lorileede Tanzania, Kenya ati Uganda, nibi ti Naijiria yoo ti koju orileede mẹtadinlogun laarin ọjọ kinni si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Chelle, ti gba ife ẹyẹ marun-un fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Aiglons ti orileede Mali, to si ti ṣakoso awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii GS Consolat, FC Martigues, Boulogne ati MC Oran.
Ọdun 2022 ni Chelle ti n ṣakoso ẹgbẹ agbabọọlu Aiglons.
Chelle ko ipa to jọju ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika to waye lọdun 2023, ṣugbọn to pada jabọ sọwọ ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Ivoy Coast ni ipele to kọgun si aṣekagba.
Lara awọn iṣẹ ti Chelle yoo maa ṣe ni lati gbe ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagle kuro ni ipele karun-un ti wọn wa lori tabili, lati yege fun idije ife ẹyẹ agbaye to maa waye lọdun 2026.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa Eric Chelle
Eric Chelle ni akọni-mọn-ọn-gba fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Aiglon ti orileede Mali nibi idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika (AFCON 2023) to waye ni Côte d'Ivoire.
Oun lo gbe ẹgbẹ agbabọọlu naa de ipele to kọgun si aṣekagba, iyẹn quarter-final, eyi to jẹ apẹẹrẹ nla nla fun orileede Mali.
Chelle ni itara rere fun iṣẹ to yan laayo, pẹlu bo ṣe daku lọ gbọrangandan nibi ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Ivory Coast lọdun naa, to si jẹ pe igbakeji rẹ lo pada lọ fi omi gbe e dide.
Ko to di pe o gba ipo akọni-mọn-ọn-gba fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Mali lọdun 2022, Chelle ti dari ọpọlọpọ ẹgbẹ agbọọlu kekeeke ninu idije ilẹ Faranse.
Lara wọn si ni GS Consolat, FC Martigues, ati Boulogne, nibi to ti lo ipo ati awọn iriri rẹ lati fi gbe awọn ẹgbẹ agbabọọlu naa die ipele to ga.
Idije ife ẹyẹ marun-un ọtọọtọ ni Chelle ti farahan fun ẹgbẹ agbabọọlu agba lorileede Mali gẹgẹ bi agbabọọlu.
Bo tilẹ jẹ pe orukọ rẹ ko rinlẹ daadaa lasiko to n gba bọọlu fun Mali, sibẹ, awọn ipa to jọju to ko lawọn asiko to fi gba bọọlu fun awọn ikọ ẹgbẹ agbọọlu ilẹ Faranse bii Martigues, Valenciennes, Lens, Istres, ati Chamois Niortais ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.
Awọn iriri rẹ to ni lawọn ẹgbẹ agbabọọlu naa lo fun un ni ipilẹ rere si irin ajo akọni-mọ-ọn-gba.
- "Oṣù Kíní, ọdún 2025 ló yẹ kí ọmọ mi rìnrìnàjò lọ sí òkè òkun, àmọ́ FMC Owo paá"
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà márùn ún tó ti gbàmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ l'Afirika ṣaájú Lookman
- Nǹkan mẹ́wàá tí o kò mọ̀ nípa Ademola Lookman tó gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ ní Africa
- Wo àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa CAF Awards tí yóò wáyé lónìí
Awọn ireti

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Ipenija nla ni ipo ti Chelle ṣẹṣẹ gba yii yoo jẹ fun, nitori pe yoo ṣiṣẹ takuntakun lati ri ipo nla di mu lati yege fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lọdun 2026
Ipo karun-un ni Naijiria wa lori tabili kẹta, ti wọn ko si tii bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ti wọn ti gba.
Adojukọ rẹ yoo bẹrẹ nigba to ba n koju awọn orileede bii Rwanda ati Zimbabwe ninu ifẹsẹwọnsẹ lati yege fun idije ife ẹyẹ naa.
Awọn ifẹsẹwọnsẹ yii ṣe pataki fun Naijiria lati le jẹ ki wọn bọ si ipele ti yoo mu won yege fun idije ife ẹyẹ agbaye
Awọn ololufẹ ere idaraya, paapaa lorileede Naijiria ni wọn ti n ni ireti wi pe Chelle yoo lo awọn iriri pẹlu Mali lati le jẹ ko ṣiṣẹ takuntakun, koda, labẹ ipenija nla, lati gbe Naijiria de ipele giga
Iwa jibiti ati ajẹbanu ni Chelle ti wọn kede – Ogunsiji

Oríṣun àwòrán, Michael-Azeez Ogunsiji
Alaga ẹgbẹ akọroyin ere idaraya, Sports Writers Association of Nigeria (SWAN), ẹka tipinlẹ Ogun, Kọmureedi Michael-Azeez Ogunsiji nigba to n ba BBC YORUBA sọrọ, o ni ki awọn ọmọ Naijiria ma ṣe reti ohun rere kan lati ọdọ Éric Chelle, nitori pe saa rẹ ko dara.
Ogunsiji sọ pe iwa ajẹbanu ati jibiti ti ajọ NFF fẹẹ bo mọra lo jẹ ki wọn yan Chelle, ẹni ti ko ni ipa rere kan ri gẹgẹ bi akọni-mọn-ọn-gba fun Super Eagles.
"Ko si ireti kankan tabi idunnu kankan ti Éric Chelle fẹẹ fun wa gẹgẹ bi akọni-mọn-ọn gba lorileede Naijiria. Iwa jibiti ati ajẹbanu lo jẹ. Wọn mọn-ọn-mọ gba Éric Chelle lati rii pe wọn fi pari iṣẹ iwa jibiti, madaru, iṣe-owo baṣubaṣu ati iji-owo ko ni," Ogunsiji sọ fun BBC.
"Wọn mọ pe ti awọn ba lo ọmọ Naijiria gẹgẹ bi akọni-mọ-ọn-gba, aṣiri owo ti wọn fẹẹ jigbe maa tu sita. Ti ẹ ba foju inu wo, ko si laakaaye kankan to fi han wa pe Éric Chelle dara ju Augustine Eguavoen, Samson Siasia, Emmanuel Amunike wa lọ.
"Taani Chelle ninu ere bọọlu ilẹ Afrika? Ki ni awọn aṣeyọri rẹ pẹlu Mali ati ninu ita ere bọọlu? Ko si ẹgbẹ agbabọọlu to ti ṣakoso rẹ ri, to le fọwọ sọya pe ipa toun ko nibẹ ree. Mali ti wọn tiẹ n sọ yii, njẹ wọn ti gba ife ẹyẹ ilẹ adulawọ tabi ti agbaye ri, ti wọn fi wo o pe oun lo kaju oṣuwọn lati dari Super Eagles," Ogunsiji fi kun ọrọ rẹ.
Siwaju sii lo sọ pe ohun itiju ati igbaju lo jẹ ninu ilana ere idaraya Naijiria lati yan Chelle, nitori pe ere idaraya ilẹ Mali ko le duro lati figagbaga pẹlu ti Naijiria.
O tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn akọni-mọn-ọn-gba to dantọ lagbaye ti wọn le dari iru awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Real Madrid, Chelsea, Arsenal lo yẹ ki wọn maa foju wo lati dari Super Eagles, "kii ṣe awọn igbayi-laarọ akọni-mọn-ọn-gba lo yẹ ki wọn maa wa kaakiri.
"Iwa itabuku ati idọti gba a ni fun awa ti a jẹ ololufẹ ere bọọlu ati akọroyin ere idaraya lorileede Naijiria lati yan iru eeyan bii Chelle lati wa tukọ Supers Eagles, ọna lati fi ko owo jẹ lasan ni," Ogunsiji sọ bẹẹ.
"Ko ba dara ki wọn da Eguavoen wa pada tabi Ben Ogunmodede ti ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars, bi wọn ko ba ti le lọ gba oyinbo alawọ funfun ti ori rẹ pe, to si mọ iṣẹ daadaa. Kii ṣe dandan lati gba akọni-mọ-ọn-gba bi wọn ko ba ti le gba awọn tori wọn pe. A ko nilo akọni-mọn-ọn-gba lati ilẹ Afrika.
"Ko si ipa rere kankan ti a fẹẹ reti lati ọdọ Chelle fun Super Eagles, nitori pe ko ni aṣeyọri kankan to le tọka si gẹgẹ bi akọni-mọn-ọn-gba."
Super Eagles ṣi le peregede fun idije ife ẹyẹ agbaye pẹlu Chelle - Obadimu

Oríṣun àwòrán, Adeyemi Obadimu Dekunle/Facebook
Ọgbẹni Adeyemi Obadimu, toun naa jẹ sọrọsọrọ ere idaraya nigba to n ba BBC YORUBA sọrọ jẹ ko di mimọ pe kii ṣe akọni-mọn-ọn-gba ni iṣoro to n koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, bi ko ṣe ajọ NFF, ati pe oun nigbagbọ pe ikọ ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣi le peregede fun idije ife ẹyẹ agbaye tọdun 2026 ti Chelle ba ri iranlọwọ to yẹ gba.
Obadimu to jẹ Olootu agba fun iroyin NewsExtra sọ fun BBC pe oun nigbagbọ pe iyatọ yoo wa fun Super Eagles, gẹgẹ bi awọn ipa to ti ko lawọn ẹgbẹ agbabọọlu to ti n bọ, paapaa ti Mali.
"Iyatọ yoo wa daradara bi mo ṣe wo o. Awọn irin ajo rẹ nidi ere idaraya fi han pe o ni ida marundinlaadọta lo fi yanranti. Iru akọni-mọn-ọn-gba bii tiẹ lo le tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria," Ọbadimu sọ bẹẹ.
"Ki awọn NFF gbaruku tii, ki wọn ma si ṣe maa la lee lọwọ pe agbabọọlu kan ni ko lo, tabi agbabọọlu kan ni ko yọ kuro. Ko si ma ṣe gba owo lati maa gba agbabọọlu tuntun, bi ko ṣe pe awọn to kaju oṣuwọn ni ko lo, to ba fẹẹ ṣe aṣeyọri.
"Bi ẹ ba wo Super Eagles daadaa, ẹ maa rii pe a ko ni awọn to le di ọwọ aarin wa ti a mọ si 'mildfielder' mọ rara. Ki wọn fi silẹ lati wa ọdọ ti wọn ṣi ni ẹjẹ tutu ati itara lati gba bọọlu.
"Awọn alakoso ajọ NFF ti a ti n ni lati ibẹrẹ, wọn kii fun awọn akọni-mọ-ọn-gba ni agbara lati pinnu lori ohun to ba fẹ. Iwa ajẹbanu ti pọ ju. Mo lero pe ti NFF ba fi Chelle silẹ, yoo ṣe daadaa."
Ni ti ipo karun-un ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria wa lori tabili lati peregede fun idije ife ẹyẹ agbaye tọdun 2026, Ọbadimu sọ pe ko si nnkan ti ko le ṣelẹ.
"Awa ti a n gba bọọlu, ti a si mọ bo ṣe rii, mo nigbagbọ pe Naijiria ṣi le peregede fun idije ife ẹyẹ agbaye to n bọ, pẹlu awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku lati gba."















