Ọ̀pọ̀ èèyàn kú nínú wàhálà tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ bọ́ọ̀lù

Àkọlé fídíò,
    • Author, Natasha Booty & Sofia Ferreira Santos
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni eeyan mẹrindinlọgọta (56) to jade laye nibi ikọlu to waye ni papa iṣere Nzérékoré, to wa ni ilu to tobi julọ lorileede Guinea, gẹgẹ bi awọn iwe iroyin ṣe gbe e.

Olootu ijọba Guinea, Mamadou Oury Bah sọ pe niṣe lawọn eeyan n tẹ ara wọn mọlẹ lasiko ikọlu ọhun, nigba tọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna lọjọ Aiku to kọja.

Dokita kan to kọ lati darukọ ara rẹ, sọ fawọn akọroyin ileeṣẹ AFP pe, ọpọ awọn eeyan to farapa ni wọn to kalẹ sẹnu ọna ile iwosan wọn, ati paapaa ile igbokusi wọn tun kun fawọn oku.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nimba Sports Zaly / AP

Awọn ileeṣẹ iroyin orilẹ-ede naa sọ pe niṣe lawọn ọlọpaa bẹrẹ sii lo afẹfẹ tajutaju sawọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Labé, ti wọn gba lalejo, iyẹn awọn ti wọn sọ pe wọn n ju okuta fun alakoso ori papa ti a mọ si rẹfiri lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ n lọ lọwọ.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, wọn ko tii le ṣe onka iye awọn to ti ku, tabi ti wọn farapa yannayanna.

“Niṣe ni wahala naa bẹrẹ nigba ti rẹfiri naa gbe ipinnu rẹ kalẹ, eyi ti ko tẹ awọn alatako lọrun, to fi mu ki wọn yabo ori papa,” ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ lo sọ fun AFP.

Awọn fọnran ati aworan to lu ori ikanni ayelujara kaakiri ṣafihan bi ikọlu naa ṣe buru to nita papa iṣere, pẹlu bi ọpọ awọn ero iworan ṣe n gbiyanju lati fo fẹnsi wọle, to mu kawọn eeyan maa jabọ silẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC ko si tii le fidi awọn fọnran naa mulẹ funra wọn.

Awọn alakoso ẹkun naa la gbọ pe wọn n ṣiṣẹ takuntakun lati “mu ohun gbogbo pada bọ sipo”, Olootu ijọba Bah lo sọ eyi ninu atẹjade rẹ, to si tun fi kun un pe awọn oṣiṣẹ ile iwosan n gbiyanju lati ṣe itọju awọn to farapa.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn oluwoye ni wọn wa nikalẹ nigba ti ikọlu ọhun bẹrẹ nibi ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Guinea, N'zérékoré ati akẹgbẹ wọn, Labé.

Iroyin naa sọ pe ifẹsẹwọnsẹ naa lo wa lara eto lati bu ọla fun Aarẹ Mamadi Doumbouya, ẹni to gba iṣakoso lẹyin iditẹ gbajọba to waye loṣu Kẹsan an, ọdun 2021.

Ọkan lara awọn ikọlu to buru julọ ninu itan ilẹ Guinea lo waye ni papa iṣere.

Lọdun 2009, awọn eeyan mẹrindinlọgọjọ (156) ni wọn ku lẹyin ti ikọ ologun dabọn bọlẹ nibi iwọde to waye ni papa iṣere Conakry to jẹ olu-ilu orileede naa.

Ọpọ awọn eeyan ni wọn yinbọn fun, ti wọn gun, ti wọn si lu lalubami nibi ikọlu papa iṣere ọhun, nigba ti awọn oṣiṣẹ aabo ṣi afẹfẹ tajutaju sawọn eeyan to wa ni papa iṣere naa.

Ogunlọgọ awọn obinrin la tun gbọ pe wọn fipa ba lajọṣepọ.

Adari orileede naa tẹlẹ, Ọgagun Moussa Dadis Camara ni wọn ṣẹṣẹ ran lọ sẹwọn ogun ọdun lori ẹsun to lodi si iwa ọmọniyan ni ibamu pẹlu ikọlu.