Ìyàwó àti ọmọ méjì kú, ọkọ̀ farapa lẹ́yìn tí àwọn kan sun ilé mọ́ wọn lórí l'Eko

Oríṣun àwòrán, @just_Liles
Obinrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Eniola Oduse, ati ọmọ rẹ meji, ti jade laye lẹyin ti awọn eeyan kan dana sun ile wọn to wa ni Ita Marun, ni agbegbe Ibeju Lekki, nipinlẹ Eko.
Ile iwosan ni ọkọ obinrin naa, Kehinde, wa bayii nibi to ti n gba itọju lẹyin iṣẹlẹ naa.
Iroyin ni oru ọjọ Iṣẹgun to kọja ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, asiko ti mọlẹbi naa n sun ninu ile wọn lawọn eeyan ti ẹnikẹni ko mọ sọ ina sinu ile naa lati oju ferese ni nnkan bii aago meji oru.
A gbọ pe awọn kọlọrọsi naa da epo bẹntiro yi ile naa ka ki wọn to sọ ina si.
Ibatan ọkọ oloogbe sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch ninu ifọrọwerọ kan pe, ọkọ oloogbe naa sa sita lati ke pe ara adugbo fun iranlọwọ, ki ọmọ rẹ mejeji ati iyawo rẹ to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ẹbi oloogbe ọhun, Taiwo sọ pe “nnkan bii aago meji oru ni iṣẹlẹ naa waye. Ekeji mi ati iyawo rẹ ti n sun ki awọn kan to wa da epo bẹntiro sile wọn.
“Ekeji mi ṣi fere ile wọn silẹ nitori oru to wa lode, nigba ti wọn ri pe ferese naa wa ni ṣiṣi silẹ ni wọn da bẹntiro sinu ile lati ibẹ, oorun epo naa lo ji iyawo, ki o to ji ọkọ rẹ.
“Ka to wi ka to fọ, wọn ri ti ẹnikan sọ ina sinu ile wọn.
“Kehinde sa sita pẹlu ina lara rẹ lati ke pe awọn eeyan adugbo fun iranlọwọ.”
O sọ siwaju si pe ina ti ran mọ iyawo atawọn ọmọ meji Kehinde nigba ti yoo fi pada de inu ile ọhun.
Ẹlomiran to tun jẹ mọlẹbi awọn ti iṣẹlẹ ṣẹlẹ si, Razaq, sọ pe wọn gbe tọkọtaya ọhun digbadigba lọ ile iwosan amọ ile iwosan naa kọ wọn latari bi ina ọhun ṣe jo wọn to.
Razaq sọ pe nnkan bii wakati meje lawọn fi n paara oniruru ile iwosan ki wọn to ri eyii to gba wọn wọle.
Lẹyinorẹyin, iyawo ọkunrin naa atawọn ọmọ rẹ mejeji jade laye, agbọ pe wọn ti sin oku wọn.
Ẹwẹ, gbogbo igbiyanju BBC lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, lati tunbọ tan imọlẹ si ọrọ naa ati ibi ti iwadii de duro lo ja si pabo.
Hundeyin ko fesi si gbogbo atẹjiṣẹ ti a fi ranṣẹ si.












