Njẹ́ báńkì rẹ̀ ń ṣe ṣége-ṣège bí? Wo ọ̀nà tí o lè gbà láì làágùn rárá

Àjọ tó ń mójútó ẹ̀tọ́ àwọn oníbàárà ní Nàìjíríà, Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC) ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ilé ìfowópamọ́ GTB, MTN àti ilé iṣẹ́ ìrìnnà òfurufú Air Peace fún títẹ ẹ̀tọ́ àwọn oníbàárà mọ́lẹ̀.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn oníbàárà àwọn iléeṣẹ́ yìí ṣe ń fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń ṣe ségesège láti bíi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn.
Láti bíi oṣù kan sẹ́yìn ni àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ GTB ti ń kojú ìṣòro kan sí òmíràn pàápàá tí wọ́n bá fẹ́ gba owó jáde kúrò ní àkáǹtì wọn.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní àwọn kò rí owó àwọn gbà jáde, tí àwọn mìíràn sì ń fẹ̀sùn kàn pé iye tí áàpù ilé ìfowópamọ́ náà ń gbé jáde fún àwọn yàtọ̀ sí iye tí àwọn ní níbẹ̀ gan.
FCCPC nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ìkànnì ayélujára X lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kìíní, oṣù Kejìlá, ní àwọn ti ń wádìí ilé ìfowópamọ́ GTB, MTN àti Air Peace lórí ẹ̀sùn táwọn èèyàn fi ń kàn wọ́n.
Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ọjọ́ Kẹta sí ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kejìlá ni ìwádìí náà yóò fi wáyé àti pé ìwádìí àwọn wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó gbé àjọ àwọn ró.
Wọ́n ní èyí yóò fún àwọn ní àǹfàní láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ àti láti mọ ọ̀nà tí wọ́n yóò fi wá ojútùú sáwọn ìpèníjà tí wọ́n ń kojú ní kíákíá.
Bákan náà ni wọ́n ní ìgbésẹ̀ àwọn yìí ṣàfihàn ìfarajìn àjọ náà láti dá ààbò bo ẹ̀tọ́ àwọn oníbàárà ní gbogbo ẹ̀ka.
Wọ́n wá rọ àwọn èèyàn láti máa fi ìwà kò tọ́ táwọn iléeṣẹ́ bá ń hù tó àwọn létí lórí àwọn ìkànnì ayélujára kí àwọn fi le máa gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ lórí wọn.
Wo ọ̀nà tí o lè fi fẹjọ́ ilé ìfowópamọ́ rẹ sùn tí wọ́n bá ń ṣe ségesège

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣáájú ni ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, Central Bank of Nigeria (CBN) ti gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fún àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ láti lè fi ẹjọ́ àwọn ilé ìfowópamọ́ náà sùn tí wọ́n bá ń ṣe ségesège.
CBN ní èèyàn le fi ẹjọ́ ilé ìfowópamọ́ sùn yálà ilé ìfowópamọ́ ńlá tàbí àwọn kéréje.
Àwọn ìgbésẹ̀ tí o ní láti gbé nìyí:
Kọ́kọ́ kàn sí ilé ìfowópamọ́ rẹ
Tí o bá ní ìpèníjà pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ rẹ, ohun tí ó nílò láti kọ́kọ́ ṣe ni láti kọ́kọ́ lọ sí ilé ìfowópamọ́ náà láti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ òun tí ò ń kojú.
Lẹ́yìn èyí ni wà á fún wọn ní ọ̀sẹ̀ méjì láti fi yanjú ohun to fẹ́ kí wọ́n ṣe náà.
Kàn sí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn oníbàárà ní CBN
Tí ilé ìfowópamọ́ rẹ kò bá kàn sí ẹ pé àwọn rí ẹ̀sùn tó fi ṣọwọ́ sí wọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tàbí tí wọ́n kọ̀ láti yanjú ìṣòso náà láàárín ọ̀sẹ̀ méjì, ó ní ẹ̀tọ́ láti lọ fẹjọ́ sun CBN.
Ẹ̀ka tó ń rí sí àwọn oníbàárà ní CBN ni wà á mú ẹjọ́ rẹ lọ ìyẹn Consumer Protection Department.
O lè kọ àtẹ̀jíṣẹ́ sí wọn lórí ìkànnì [email protected] tàbí kí o kọ lẹ́tà tí wà á darí sí adarí ẹ̀ka Consumer Protection Department ní CBN ní ìpínlẹ̀ rẹ.
Bákan náà ni o le fẹjọ́ ilé ìfowópamọ́ rẹ sun FCCPC lórí ìkànnì ayélujára wọn gbogbo.















