Ìjàmbá iná Los Angeles pa èèyàn 24, èèyàn 16 míì d'àwátì, dúkìá bíi $275bn ṣòfò

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn onimọ nipa oju ọjọ ti sọ pe iji lile to n jẹ ki ijamba ina California pọ si yoo tun lọ soke laarin ọsẹ yii.
Awọn oṣiṣẹ panapana ko si dawọ iṣẹ duro lori ati dẹkun ina to n jo yii.
Awọn akọsẹmọṣẹ nipa oju ọjọ ni iji lile yii yoo fẹ lati alẹ ọjọ Aiku ọjọ kejila oṣu kinni titi di Ọjọru ọjọ kẹẹdogun oṣu yii.
Awọn ikọ lati ipinlẹ mẹjọ mii lorilẹede Amẹrika ati lati Canada to fi mọ Mexico lo n ṣeranwọ fawọn oṣiṣẹ panapana ni California.
Ọga agba eto ilera ni Los Angeles lo fidi rẹ mulẹ pe o ti di eeyan mẹrinlelogun to ti ku ninu ijamba ina ọhun nigba ti eeyan mẹrindinlogun mii di awati.
Ẹkun Eaton ni wọn ti ri oku eeyan mẹrindinlogun nigba ti wọn ri oku eeyan mẹjọ yoku lagbegbe Palisades.
Sibẹ sibẹ, ina yii ko tii dawọ jijo ni California, ina ọhun ni a gbọ pe o ti jo bii sare ilẹ lọna ẹgbẹrun mẹtalelogun ni agbegbe Palisades bayii.
Ida mẹtala ninu ọgọrun sare ilẹ yii ni awọn panapana tii le dẹkun ina ọhun bayii.
Ijamba ina yii jẹ ọkan lara ijamba ina to buru julọ ninu itan orilẹede Amẹrika.
Nnkan to ti ṣofo ninu ijamba ina California ni a gbọ pe o ti to bii $275bn bayii.
Iná tó ń jò ní Los Angeles mú ẹ̀mí èèyàn 16 lọ, ẹgbẹgbẹ̀rún pàdánù ilé wọn
Awọn oṣiṣẹ panpana ko sun rara niluu Los Angeles, nilẹ Amẹrika, latari ina to n jo nibẹ lati ọpọ ọjọ bayii.
A gbọ pe ina ọhun ti n jo de agbegbe ti awọn ọlọrọ ilu naa n gbe.
Lalẹ ọjọ Abamẹta ni ijọba California kede pe eeyan mọkanla lo ti jade laye latari ina to n jo lagbegbe Eaton, nigba ti eeyan marun un mii ku ni Palisades.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oṣiṣẹ panapana ti n kọlu ina Palisades lati oju ofurufu amọ ina ọhun ti jo kọja ẹgbẹrun kan eka ilẹ, o si ti n rapala wọ agbegbe Brentwood.
Awọn alaṣẹ sọ pe awọn n gbiyanju bo tilẹ jẹ pe awọn araalu kan n bu ẹnu atẹ lu igbiyanju awọn.
Igbagbọ wa pe afẹfẹ yoo gberasọ to ba di oru, eyii ti yoo ran ina ọhun lọwọ lẹyin iku eeyan mẹrindinlogun yi.
Ajọ to n ri si oju ọjọ, National Weather Service, ti kilọ pe afẹfẹ Santa Ana to tunbọ jẹ ki na ọhun pọ si yoo tun pada ṣọṣẹ loru ọjọ Abamẹta ati oru ọjọ Aiku.
Ipinlẹ meje to yi California ti ina naa ti n jo ka, to fi mọ ijọba apapọ Amẹrika, ijọba Canada ati Mexico lo ti fi ohun iranwọ ranṣẹ siluu naa.
Lindsey Horvath, to gbẹnusọ fun ijọba Los Angeles sọ pe adanu nla ni ina ọhun da siluu awọn.
Amọ ṣa, awọn panapana ti ṣe awọn aṣeyọri kan ni bi wọn ṣe kapa ida mọkanla ina Palisades to ti gba ẹgbẹrun mẹtalelogun eeka ilẹ.
Wayi o, ina naa ti ran de Mandeville Canyon, eyii to mu ki ijọba ke si awọn to n gbe lagbegbe naa lati sa asala fun ẹmi wọn.
Lara awọn to n gbe ni Brentwood, ni Mandeville Canyon ni gbajumọ oṣere ati gomina California tẹlẹ, Arnold Schwarzenegger, gbajumọ agbabọọlu alapẹre, Lebron James, atawọn eeyan jankan jankan mii.















