Afurasí olówò nàbì ṣekúpa òṣìṣẹ́ ilé ọtí nítorí N200

Aworan olowo nabi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Adawama ti mu obìnrin kan, ẹni ọdun mejilelọgbọn, RIyanatu Musa fun ẹsun pe o ṣekupa oṣiṣẹ ile ọtí, Yohanna Musa nitori igba naira.

RIyanatu gun Yohanna pa pẹlu ọbẹ lẹyin to kuna lati san gbese N200.

Iṣẹlẹ naa waye niluu Yola.

Nigba to n fìdí iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Adawama, Suleiman Nguroje ni ede aiyede bẹ silẹ lẹyin ti olowo nabi naa kọ lati san gbese to jẹ Yohanna to jẹ oṣiṣẹ ile ọti.

"RIyanatu jẹ wọ pe oun lo ṣekupa oloogbe lẹyin to gba ogogoro Big Ben ati Yahoo lọwọ oloogbe, to si se ileri pe oun yoo san N200 ni ọjọ kejì lẹyin to san ẹgbẹrun kan leni ẹdẹgbẹta naira.

"Eyi lo fa ija, ti RIyanatu si yọ ọbẹ gun Yohanna pa."

Nguroje ni Kọmisana fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ naa, Dankombo Morris ti palasẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, to rọ awọn lati dẹkun fífi ofin si ọwọ ara wọn