Òṣìṣẹ́ méjì tó jábọ́ sínú tánkì epo dísù l'Eko jáde láyé

Awọn oṣiṣẹ LASEMA

Oríṣun àwòrán, LASEMA/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn oṣiṣẹ meji to ja sinu tanki epo disu nile iṣẹ kan ni Ikosi, lagbegbe Oregun niluu Eko lopin ọsẹ to kọja ti jade laye.

Iwadii fihan pe ọkan lara awọn eeyan meji yii lo ṣee si ja sinu tanki epo disu naa lasiko to n ṣiṣẹ lọwọ.

Ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ṣalaye pe ẹnikeji toun naa ku ninu ìṣẹlẹ ọhun n gbiyanju lati yọ akẹgbẹ rẹ to kọkọ ko sinu tanki epo ọhun loun naa fi ko sibẹ.

Ajọ LASEMA ni awọn eeyan naa farapa yanayana, sugbon awọn oṣiṣẹ ajọ pajawiri kọkọ fun wọn ni itọju kiakia.

Lẹyin naa ni wọn gbe wọn lọ si ile iwosan fun itoju to péye.

Amọ, nigba to ya ni ajọ LASEMA sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe "awọn ọkunrin ti a doola ninu tanki epo disu ti a si gbe wọn lọ si ile iwosan ti jade laye.

Bo tilẹ jẹ pe a gbìyànju agbára wa lati ri pe wọn gbadun, o ṣeni laanu wi pe wọn pada ku."