Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun lórí ìdájọ́ tó yọ Aminu Ado nípò Emir ìlú Kano

Aworan Emir Ado Bayero ati Sanusi.

Oríṣun àwòrán, Aminu Ado Bayero/Instagram/ Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile-ẹjọ Kotẹmilọrun to wa niluu Abuja, ti paṣẹ pe ki igbẹjọ tuntun waye lori rogbodiyan ọrọ Emir ilu Kano, eyi to n lọ laaarin Aminu Ado Bayero ati Emir Mohammed Sanusi to wa nipo naa bayii.

Igbimọ ẹlẹni mẹta kan, ti Mohammed Mustapha lewaju rẹ lo yi idajọ naa ti ile-ẹjọ giga ilu Kano gbe kalẹ loṣu Keje pada.

Idajọ igba naa lo yọ Aminu Ado Bayero ati awọn Emir mẹrin miran kuro nipo.

Ni bayii, ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ti sọ pe wọn ko fun olupẹjọ ni anfaani lati sọrọ ni kootu, pẹlu ọna ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kano gba gbọ ẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.

Ninu idajọ tuntun to waye lọjọ Ẹti, ọjọ kẹwaa, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, ile ẹjọ Kotẹmilọrun sọ pe ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano, ko ṣe otitọ ninu idajọ to ṣe.

O ni bi wọn ṣe bẹrẹ igbẹjọ lai fun Ado Bayero ni iwe to yẹ lati ibẹrẹ ko dara to, wọn ko si tun jẹ ko waa wi tẹnu rẹ fun awijare kankan.

Adajọ Mustapha sọ pe dandan ni fun gbogbo kootu lati ri i pe wọn fun awọn tọrọ kan ni anfaani lati sọ ti ẹnu wọn.

Igbimọ naa fi kun un pe, o yẹ ki wọn fun Sanusi paapaa ni iwe ti yoo fi sọ ẹhonu rẹ, ki kootu to o dajọ.

Wọn ni iwa ti ile-ẹjọ giga Kano hu yii ti tako ododo to yẹ ko wa ninu idajọ, o si di dandan ki ile-ẹjọ to ga ju bẹẹ lọ da si i.

Igbimọ yii sọ pe bii igba ti eeyan fi eto idajọ ṣe yẹyẹ ni.

'Ẹ gbé ẹjọ́ yìí fún adajọ́ tuntun'

Lati ṣe ayipada idajọ ọhun, ile ẹjọ Kotẹmilọrun paṣẹ fun Adajọ agba nile ẹjọ giga ilu Kano, lati jawọ ninu ẹjọ yii, ko si gbe e fun adajọ tuntun.

Bakan naa ni ko sọ pe ki olujẹjọ san owo itunu kankan lori ẹjọ ti Ado Bayero pe yii.

Oṣu Karun-un ọdun 2024 ni Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf, yọ Emir igba naa, Aminu Ado Bayero, kuro nipo ọba Kano, bẹẹ lo yọ awọn Emir mẹrin kan naa danu nipinlẹ ọhun.

Bi Gomina ṣe yọ Ado Bayero nipo lo da Sanusi Lamido Sanusi pada sipo Emir ilu Kano.

" O ṣe pataki lati da aṣa to ti wa ni Kano tipẹ pada, aṣa naa ti wa lati ẹẹdẹgbẹwa ọdun sẹyin (900 years).

"Fun idi eyi, a ti fagile ofin ọdun 2019 to da awọn igun ọlọba mi-in silẹ lasiko iṣakoso gomina tẹlẹ, Ganduje.

Bẹẹ ni Gomina Yusuf sọ nigba naa.