Àwọn ọmọ Okoya yóò sọ tẹnu wọn lọ́dọ̀ EFCC lónìí lórí ẹ̀sùn àṣìlò Náírà

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X
Lonii ọjọ Aje ọjọ kẹtala oṣu Kinni ni ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ yoo ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Subomi ati Wahab Okoya lori ẹsun wi pe wọn n tabuku owo naira.
Lọsẹ to kọja ni fọnran kan lu ori ayelujara pa eyi to ṣafihan bawọn ọmọkunrin gbajugbaja oniṣowo n ni Razaq Okoya ṣe n nawo loju agbo ti ọlọpaa kan si tun bawọn gbe owo naa lọwọ.
Ninu atẹjade kan ti adele ọga agba ajọ EFCC nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Michael Wetkas, buwọlu ni ajọ naa ti ṣalaye pe ọfiisi wọn to wa lopopona 15A Awolowo niluu Eko lawọn ọmọkunrin ọhun yoo ti lọ wi tẹnu wọn lonii ọjọ Aje.
Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti bẹnu ẹtẹ lu bawọn ọmọkunrin naa ṣe n ṣe owo naira ninu fidio to ti tan kalẹ.
Ọlọpaa to bawọn ọmọ Okoya gbowo lọwọ loju agbo dero ahamọ
Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti kede pe awọn ti mu ọlọpaa to wa ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara nibi ti o ti ba awọn ọmọ ọkunrin gbajugba onisowo, Oloye Razaq Okoya gbe owo dani.
Bo ti le jẹ pe wọn ko kede ọrọ orukjọ ọlọpaa naa sita.
Ikede yii lo wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejobi gbe soju opo ikanni X rẹ lọjọ Ẹti.
Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, o ni ohun ti ọlọpaa naa se ni ko ba ofin mu, to si tabuku si ilana ti ileeṣẹ ọlọpaa n tẹle.
O jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati fi iya to yẹ jẹ ọlọpaa naa.
"Ọlọpaa to wa ninu fọnran kan ti awọn ọmọ onisowo Eko, Oloye Okoya gbe sita nibi ti wọn ti n tabuku naira ni a ti ri, ti a si ti fi si ahamọ.
"Pe ọlọpaa naa wa nibẹ lasiko ti iwa yii waye ni ko bojumu, ti a ko si ni tẹwọgba rara."
Lọsẹ to kọja ni fọnran awọn ọmọ Okoya lu sita lori ayelujara, ti ọpọ si bu ẹnu atẹlu ihuwasi awọn ọmọ naa, pẹlu igbagbọ pe ko si nnkan ti ofin le se fun nitori ipo baba wọn.
Ninu fọnran naa, Wahab ati Raheem Okoya wọ agbada funfun, ti wọn fi owo han lati fi gbe wọn tuntun sita.
Bakan naa, Ọlọpaa wa ninu fọnran naa to ba wọn gbe owo naa dani, ti awọn ọmọ mejeeji si n jo si orin ti wọn kọ.
Ọmọde lo n se wa - Raheem Okoya tọrọ aforijin fun ẹsun tita abuku si owo naira
Raheem Okoya, ọkan ninu awọn ọmọ onisowo Razaq Okoya to wa ninu fọnran to lu sita lori ayelujara ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun tita abuku si owo naira.
Ninu atẹjade to fi sori ayelujara X, o ni oun ko mọ pe iwa oun yoo da wahala silẹ, ti oun ko si ero buburu si owo naira .
"SI awọn ọmọ Naijiria, n ko mọ pe iwa mi yoo fa rogbodiyan bayii, mo se pẹlu ọkan mimọ.
"Mo n tọrọ fun aforijin ati atilẹyin yin lọwọ yii. Nko mọ pe iwa mi yoo lẹyin bayii."















