Akọrin ẹ̀mí tó pa ọmọ wa tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, gé ẹ̀yà ara rẹ̀ ní ekìrí lọ́nà àádọ́ta sínú àpò mẹ́fà, ó fẹ́ ṣè é jẹ ni - Ẹbí Olóògbé

Oríṣun àwòrán, Salome Adaidu/ Facebook, Teaser .T/ TikTok
Bi iroyin iku ọmọbinrin agunbanirọ nni, Salome Adaidu ti wọn ni ọkunrin kan, Timilẹyin Ajayi, ṣa pa ṣe n tan kalẹ, bẹẹ ni ọlọkan-o-jọkan alaye nipa afurasi naa ti n jade si i.
Salome, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), pade iku ojiji nigba to ṣabẹwo si Timilẹyin lagbegbe Papalana, Karshi, nipinlẹ Nasarawa.
Ọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii ni ọwọ ba Ajayi lasiko ti wọn lo fẹẹ ju ori Salome nu, lẹyin to pa a tan to si kun ara rẹ wẹlẹwẹlẹ.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa ko ti i gbe Ajayi lọ si kootu fun ẹsun ipaniyan.
Ṣugbọn wọn ṣe afihan rẹ fawọn akọroyin lọjọ kẹrinla oṣu Kin-in-ni yii pẹlu ada ati ọbẹ to ni oun lo lati fi pa Salome.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, Ramhan Nansel, ṣalaye pe awọn yoo gbe afurasi naa lọ si kootu bi iwadii ba pari.
Ẹka to n wadii iwa ọdaran, nileeṣẹ ọlọpaa Nasarawa ni Timilẹyin wa bayii.
Ṣùgbọ́n ta gan-an ni Timilẹyin Ajayi?
Akọrin ẹmi ni Timilẹyin Ajayi, ẹni ọgbọn ọdun ni.
Ipinlẹ Kogi ni wọn ti bi i, ni Aarin-gbungbun Ariwa orilẹede Naijiria.
Timileyin ṣalaye pe aṣoju awọn to n fi owo ilẹ okeere da okoowo lori ayelujara (cryptocurrency agent), loun.
Bo tilẹ jẹ pe ko sọ igba to ti n ṣe òwò ọhun bọ.
O ni o ti fẹrẹ to ọdun kan ti oun ati Oloogbe Salome Adaidu ti n fẹ ara wọn bọ.
O ni ṣugbọn ajọṣepọ naa ko ja geere, nitori awọn ki i rira deede.
Ṣugbọn awọn ẹbi Adaidu tako eyi, wọn ni ọmọ awọn ki i ṣe ololufẹ afurasi yii rara.
Loju opo TikTok rẹ, Timileyin kọ ọ sibẹ pe ayaworan sinima loun.
O tun ni oun maa n ṣe awọn eto lori ayelujura, oludari ẹka iroyin ayelujara lo tun pe ara ẹ, bẹẹ lo ni oun n ya aworan fidio, oun si tun maa n ṣe akọsilẹ orin.
'Èkìrí tó gé ẹran ara náà sí lé ní àádọ́ta'
Ninu ọrọ ẹgbọn Oloogbe Salome, iyẹn Esther Adaidu, obinrin naa fi omije ṣalaye pe:
" Awa o mọ ọmọkunrin ti wọn n pe ni Timi yii ri o.
A o tiẹ ri i ri, afigba to pa aburo wa to si kun ara rẹ wẹlẹwẹlẹ.
" Idajọ ododo la n beere lori ọkunrin to jokoo kalẹ yii o, nitori oun lo pa aburo mi, o si tun jẹwọ bẹẹ fun mi."
'Ó fẹ́ẹ́ jẹ èkìrí ẹran tó gé yẹn ni'
Bakan naa ni ẹni to jẹ ẹgbọn fun Salome lọkunrin,
Samson Adaji Adaidu, ṣalaye pe awọn ko fẹ nnkan kan lọdọ ọlọpaa ju ki wọn ṣeto bi idajọ ododo yoo ṣe waye lọ.
" O ti ri ọmọ wa ba laye jẹ, ki i ṣe pipa lasan lo pa a, o tun ge e si wẹwẹ, o ju ida aadọta lọ to pin ẹran naa si i.
Tẹ ẹ ba si foju inu wo gbogbo nnkan yii, o n pese ẹran yẹn kalẹ fun jijẹ ni, nitori niṣe lo ge e to si di i kalẹ sinu lailọọnu to to mẹfa.'
Bẹẹ ni ẹgbọn Oloogbe Salome Adaidu wi.
Agunbanirọ to n sinru ilu lọwọ ni Oloogbe Salome Adaidu, ileeṣẹ Ma-dami-dofo (Insurance) kan lo ti n sinru ilu l'Abuja, ki iku ojiji too mu un lọ.
Mo pa ọ̀rẹ́bìnrin mi torí ó ń fẹ́ ẹlòmíràn pẹ̀lú mi, n kò kábàmọ́ọ̀ ikú rẹ̀ – Akọrin ẹ̀mí Timileyin Ajayi

Oríṣun àwòrán, Timileyin Ajay/Salome Adaidu
Timileyin Ajayi, ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa ọrẹbinrin rẹ ti ṣalaye eredi to fi wu iwa laabi naa.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ni ẹka CID to wa ni ọọfisi ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa ni afurasi naa jẹwọ bẹẹ.
Timileyin sọ pe oun pa ọdọbinrin ọhun latari pe o n fẹ ọkunrin mii pẹlu oun, ati pe oun ko kabamọ iku rẹ.
Nigba ti awọn akọroyin beere lọwọ rẹ pe ṣe lootọ lo pa obinrin naa, o ni ootọ ni.
Timileyin sọ pe "Mo ṣekupa a nitori awa mejeji ko ri aye fun ara wa, kii ṣe ohun ti mo gba lero tẹlẹ amọ o ti ṣẹlẹ naa niyẹn.
"Kii ṣe pe mo ni lọkan tẹlẹ lati pa amọ o n fẹ ẹlomiran pẹlu mi.
"Ọpọ nnkan nipa rẹ lo maa n fi pamọ fun mi; ori ẹrọ ilewọ rẹ ni mo ti ri pe o maa n ba awọn ọkunrin mii sọrọ, eredi ree ti mo fi gbe igbesẹ naa."
Afurasi ọhun sọ siwaju si pe oun ko kabamọ pe oun ṣe sekupa oloogbe naa.
Ẹwẹ, ẹgbọn oloogbe, Esther Adaidu ti sọ pe awọn mọlẹbi wọn ko mọ pe aburo oun n ṣere ifẹ pẹlu afurasi naa.
Esther sọ pe "Awa ko mọ ọgbẹni Timileyin yii rara, a ko tii foju ganni rẹ ri titi di igba ti wọn pe wa o ṣekupa aburo wa, to si ge ẹya ara rẹ.
"Awa gẹgẹ bii mọlẹbi n beere idajọ ododo lori ọrọ yii nitori oun lo pa aburo mi, o si ti jẹwọ fun."
Ọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kini, ọdun 2025 yii ni ọwọ tẹ Timileyin pẹlu ori ọrẹbinrin rẹ ọhun, Salome Eleojo Adaidu.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Salome, agunbanirọ lo si n ṣe niluu Abuja ṣaaju iku rẹ.
Salome pade iku ojiji lasiko to lọ ṣabẹwo sile afurasi to wa lagbegbe Papalana, ni New Karshi to wa ni ijọba ibilẹ Karu nipinlẹ Nasarawa.
Ọwọ́ tẹ akọrin ẹ̀mí pẹ̀lú orí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Collage
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọwọ ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Nasarawa ti tẹ akọrin ẹmi kan, Timileyin Ajayi, lori ẹsun pe o pa ọrẹbinrin rẹ, to si tun ge ẹya ara rẹ.
Salome Enejo, tii se ẹni ọdun mẹrinlelogun, lo jẹ agunbanirọ nilu Abuja, ti wọn si fura si Ajayi pe o fẹ fi se etutu ni.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ni Nasarawa, Ramhan Nansel salaye fawọn akọroyin pe awọn olujọsin kan ni ọwọ tẹ Ajayi lagbegbe Orozo to paala pẹlu ilu Abuja ati Nasarawa.
Awọn olujọsin naa lo fura pe ara Ajayi ko balẹ, ti irinsi rẹ si mu ifura lọwọ bo se duro si ẹba odo, o tun gbe baagi kan lọwọ, ninu eyi to gbe ori ọrẹbinrin rẹ naa si.
Nansel fikun pe wọn doola ẹmi afurasi naa, kawọn araalu ma baa se lese lasiko ti wọn ri pe ori eeyan lo gbe lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Collage
Nigba to n ba akọroyin Punch sọrọ, asaaju awọn olukọ ẹkọ Bibeli ati akọwe ijọ, Caleb Umaru salaye pe ọkan ninu awọn ọmọ ijọ naa lo fura si Ajayi lẹba odo to duro si.
Ọmọ ijọ naa si lo ke pe awọn ọmọ ijọ yoku nigba to ri Ajayi to ju baagi ọwọ rẹ sinu odo eyi ti wọn tete lọ gbe, ti wọn si ba ori obinrin ti wọn ge ninu rẹ.
"A fẹ pari isin ni deede aago mọkanla aarọ ọjọ Isẹgun ni isẹlẹ naa waye.
Ọgbẹni Victor lo yaju lasiko ti a n gbadura lọwọ, to si kofiri Afurasi naa to n rin tifura-tifura leti odo to wa lẹba ile ijọsin naa pẹlu baagi kan to gbe dani.
Kia ni Victor pe arakunrin Amos lati wa wo nnkan to ri, ti wọn si ri ọkunrin naa ju apo ọwọ rẹ sinu odo.
Nigba ti wọn bii pe ki lo wa ninu apo to ju sinu odo, o ni ko si nkankan ninu rẹ, nigba ti ko si dahun gbogbo ibeere ti wọn n bi, wọn ba fi silẹ lati wọnu sọọsi lọ.
Afurasi naa wa sare kuro leti odo yii, to si fẹsẹ fẹ amọ se ni wọn gba ya a, lati tete ra mu, ko to sa lọ, ti eeytan kan si sare wọnu odo lati gtbe apo to ju sinu rẹ."
Umaru tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe wọn ni ki Ajayi si apo naa lati mọ ohun to wa ninu rẹ amọ ko da wọn lohun, lẹyin naa ni wọn fa le awọn ọlọpaa to de sibi isẹlẹ naa, lọwọ.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ninu alaye rẹ, Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Nasarawa ni awọn se iwadi awọn lọ sile afurasi naa, ti wọn si ri iyoku ara oloogbe naa ninu ile ọhun, ti wọn ti sa jalajala.
"Lasiko iwadi wa ninu ile afurasi naa, a ri apo meji ti wọn ko ẹya ara oloogbe naa si, a sawari rẹ pe agunbanirọ ni obinrin naa, ti a si ti kan sawọn obi rẹ.
Awọn araalu ti se afurasi naa lese, to si farapa yannayanna lasiko ti a de sibi isẹlẹ naa, a si ti gbe lọ sile iwosan nibi to ti n gba itọju.
















