"Makinde ti tàpá sí òfin àti àṣà ìlú Oyo lórí ìyànsípò Aláàfin, yóò kábàmọ̀ ohun tó ṣe lọ́jọ́ iwájú"

Seyi Makinde, Alaafin Abimbola Owoade ati awọn afẹnifẹre
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Aṣoju ẹgbẹ awọn ọmọ ilu Oyo, Dimeji Fabiyi ti sọ pe gomina Seyi Makinde ti tapa si aṣa ilu Oyo, yoo si kabamọ igbesẹ rẹ lọjọ iwaju.

Fabiyi lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise.

O ni "Ohun to ṣẹlẹ laarin ọjọ diẹ sẹyin jẹ ohun to ba eeyan ninu jẹ pupọ, ilu Oyo ko kere lara awọn ilu to ni aṣa julọ nilẹ Yoruba.

"Pẹlu ohun to ṣẹle nilu Oyo bayii, mo gbagbọ pe gomina Makinde ti ṣe awọn nnkan ti ko yẹ ko ṣe, eyii ti ko si ni le ṣatunṣe rẹ titi lai.

"Mo gbadura pe yoo dagba, ko si pe nnkan bii ọgọrun tabi aadọrin ọdun loke eepẹ, nigba to ba wo ẹyin wo, yoo kabamọ igbesẹ to gbe yii."

"Makinde tapa si ofin to rọ mọ jijẹ Alaafin ti wọn kọ lọdun 1961"

Fabiyi sọ pe Makinde gbe igbesẹ to tako aṣa ati alakalẹ bi wọn ṣe n joye Alaafin ilu Oyo.

O ni o tun tapa si ofin to rọ mọ igbesẹ bi wọn ṣe n jẹ oye naa eyii ti wọn kọ lọdun 1961.

O ni ofin naa ti ṣalaye ojuṣe Oyomesi, awọn afọbajẹ, ijọba ati gbogbo awọn ti ọrọ kan nipa oye Alaafin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Oyomesi ni agbara lati yan ọmọ oye gẹgẹ bii ofin ṣe fun wọn lagbara.

O pari ọrọ rẹ pe Oyomesi kọ lẹta si ijọba Oyo, wọn si ṣe gbogbo ohun to yẹ ki wọn ṣe lati yan Alaafin, amọ gomina Makinde kọ lati fọwọ si ẹni ti Oyomesi mu to si ṣe ifẹ inu rẹ.

Àkọlé fídíò, Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó fara gbá nínú ìbúgbàmù Ibadan lẹ́yìn ọdún kan?

A fún Makinde ní ọgbọ̀n ọjọ́ láti gba ọ̀pá àṣẹ padà lọ́wọ́ Owoade - Ọmọọba Gbadegẹsin, Oyomesi

Awọn afọbajẹ marun un ati ẹni ti wọn n fẹ ko gori itẹ Alaafin, Ọmọọba Lukman Gbadegesin ti fun gomina Seyi Makinde ni ọgbọn ọjọ pere lati wọgile iyansipo Akeem Owoade gẹgẹ bii Alaafin Oyo tuntun.

Ọrọ naa lo jẹyọ ninu lẹta kan ti wọn kọ si gomina ọhun lọjọ kẹrinla, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii.

Agbẹjọro wọn, Kunle Sobaloju, SAN, lo kọ lẹta ọhun lorukọ Gbadegesin.

Wọn ni awọn ko faramọ bi Makinde ṣe gbe ọpa aṣẹ fun Owoade, o si gbọdọ wọgile igbesẹ naa laarin ọgbọn ọjọ si ọjọ ti awọn kọ lẹta naa, bi bẹẹ kọ, awọn yoo gba ile ẹjọ lọ.

Alaafin Owoade, Seyi Makinde ati Ọmọọba Gbadegesin

Makinde, dẹkun biba orukọ wa jẹ pẹlu ẹsun gbigba riba lati yan Alaafin, eyi ti ko yẹ ọọfisi gomina - Oyomesi

Awọn afọbajẹ ọhun tun kilọ fun Makinde ninu lẹta mii pe ko dẹkun ati maa ba orukọ awọn jẹ pẹlu ẹsun pe awọn gba riba lati yan Alaafin.

Wọn ni o ṣeni laanu pe Makinde le maa sọrọ kobakungbe si awọn lori afẹfẹ eyii ti ko yẹ ọọfisi gomina.

Lẹyin naa ni wọn wa sọ siwaju si pe ki Makinde ṣọra ko ma baa ṣẹ si ofin ibanilorukọjẹ.

Lẹta naa ni "A fẹ ki o mọ pe o le jẹjọ ẹsun ibanilorukọ ti o ba ṣẹ lasiko rẹ ni ọọfisi, o si le foju bale ẹjọ lẹyin saa lori ohun ti o ṣe ni ọọfisi."

Awọn afọbajẹ naa ni Basorun ilu Oyo, Oloye Yusuf Ayoola; Laguna ilu Oyo, Oloye Wakeel Akindele; Akinniku ilu Oyo, Oloye Hamzat Yusuf; Oloye to n duro fun Asipa Oyo, Wahab Oyetunjii; ati Alapinni ilu Oyo, Oloye Gbadebo Mufutau.

Wo ohun to ti waye saaju laarin Makinde, Oyomesi ati Gbadegesin lori iyansipo Alaafin

Ti ẹ ko ba gbegbe, ọsẹ to kọja ni Makinde kede Ọmọọba Owoade to n fi orilẹede Canada ṣebugbe gẹgẹ bii ẹni ti yoo jẹ Alaafin tuntun, to si gbe ọpa aṣẹ le lọwọ lọwọ Aje ọsẹ yii.

Igbesẹ naa waye lẹyin ọjọ kan ti Sobaloju ti kọkọ sọrọ ninu atẹjade kan, ninu eyi to ti kilọ fun Makinde lati bọwọ fun ẹjọ ti wọn pe lori ọrọ oye Alaafin naa.

Gbadegesin sọ fun Makinde ninu atẹjade naa pe ko gbọdọ kede ọmọ oye miran yatọ si Gbadegesin ti awọn afọbajẹ marun un ọhun ti buwọlu ṣaaju.

Amọ lasiko ti Makinde n gbe ọpa aṣẹ fun Owoade, o ni awọn kan gba riba lati kede Gbadegesin gẹgẹ bii ọmọ oye eyii ti ko bojumo.

O si fi kun pe gbogbo awọn to lọwọ ninu gbigba riba naa ni yoo foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, Láyé àtijọ́, Èṣù ni wọ́n máà ń pe ìlu Àgídìgbo, kò sí ibi tí wọn ti lù ú, tí ìjà kìí bẹ́ sílẹ̀ - Onílù Àgídìgbo

Ọmọọba mẹ́sàn-án miran tun tako ìyànsípò Owoade gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin Oyo

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe ko din ni ọmọ ọba mẹsan-an lati idile ọlọba ipinlẹ Oyo ti wọn ti koro oju si iyansipo Alaafin Oyo tuntun bayii, Ọba Abimbola Owoade.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinla oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni wọn fi ẹhonu han ninu atẹjade kan ti wọn fi sita.

Ọmọọba Sina Afolabi, ti idile Adeitan, lo fi atẹjade naa sita lorukọ awọn idile mẹsan-an yooku.

Awọn ọmọ ọba mẹsan-an naa ti a mọ si 'Atiba mẹsan-an', ṣapejuwe iyansipo Owoade bii ohun to tabuku aṣa iṣembaye Oyo.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan Gomina Seyi Makinde to fi Alaafin naa jẹ.

"Bi Makinde ṣe fi Ọmọọba Owoade jẹ, jẹ ọna kan to tabuku ori itẹ Alaafin Oyo"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade awọn Atiba mẹsan-an ni wọn ti ṣalaye, pe ọrọ Awiṣẹ Agbaye, Ọjọgbọn Wande Abimbola, to n gbe lorilẹ-ede America ni Gomina Makinde tẹle.

Awọn ọmọ ọba yii sọ pe Ọjọgbọn Wande Abimbola lo sọ fun Makinde pe Owoade ni Ifa mu bii Alaafin Oyo tuntun.

Wọn fi kun un pe eyi ni gomina tẹle, to fi fi Owoade jọba.

Bi wọn ṣe wi, iyansipo yii tako aṣa iṣẹdalẹ Oyo nikan kọ, ṣugbọn o tun jẹ titẹ ofin loju mọlẹ.

" Ipo Alaafin Oyo ki i ṣe yẹpẹrẹ ni gbogbo ilẹ Yoruba. Awa Atiba Mẹsan-an tako ilana ti ijọba ipinlẹ Oyo fi yan Omooba Owoade gẹgẹ bii Alaafin.

" Wọn gbọdọ da a duro ki wọn si ṣe ohun to yẹ lati yan Alaafin tuntun.

" Bi Gomina Makinde ṣe fi Ọmọọba Owoade jẹ, jẹ ọna kan to tabuku ori itẹ Alaafin Oyo.

" Awa Atiba mẹsan-an ko fẹ ẹ. A bọwọ fun Ọjọgbọn Abimbola to bi Ifa leere, sugbọn bi wọn ba fẹẹ ko akoyawọ lojuu gbogbo eeyan, ki wọn waa beere lọwọ Ifa lojude Ogun niluu Oyo nibi''

"Bi a ba f'oju inu wo o, awọn ọba kan to yẹ ko maa gba aṣẹ lọwọ Alaafin ko ni i ṣe bẹẹ mọ bayii, wọn ko ni i bọwọ fun un, nitori wọn a maa ri i bii ẹni ti wọn ko yan sipo lọna to yẹ.

" Ẹ ma sọ ipo Alaafin di yẹpẹrẹ mọ wa lọwọ''

Bẹẹ ni atẹjade naa wi.

Bakan naa ni Atiba mẹsan-an rọ awọn Oyomesi, ti Basorun Yusuf Akinade n lewaju wọn, lati yanju aawọ to wa laaarin wọn.

Abimbola Owoade

Oríṣun àwòrán, Abimbola Owoade

"Ẹhonu wa duro lori ọna ti wọn fi yan Owoade sipo Alaafin eyi to tako bi wọn ṣe n ṣe e latilẹ niluu Oyo"

Yatọ si Ọmọọba Sina Afolabi, awọn mẹjọ miran ti wọn tun tako iyansipo Owoade ni:

Ọmọọba Remi Azeez (Tella Okitipapa); Ọmọọba Lamola Olanite (Olanite); Ọmọọba Agboin Adelabu (Adelabu); Ọmọọba Raji Adeniran (Adeniran);Ọmọọba Nureni Taiwo (Tella Agbojulogun); Ọmọọba Muftau Adejare Adesokan (Adesokan Baba Idode);Ọmọọba Adesiyan (Adesiyan); ati Ọmọọba Bello Rasheed (Abidekun).

Gbogbo awọn ọmọ ọba yii ni wọn ni awọn ko faramọ Abimbola Owoade, wọn ni iyansipo rẹ tako ọna ifọbajẹ ilu Oyo Alaafin.

Wọn fi kun un pe awọn ko ba Owoade tabi Ọmọọba Lukman Gbadegesin, ondupo ti awọn Oyomesi kọkọ yan, ja, nitori wọn lẹtọọ gẹgẹ bii ọmọ ọba lati dupo.

Awọn Atiba mẹsan-an sọ pe ehonu awọn duro lorii pe ọna ti wọn fi yan Owoade sipo Alaafin tako bi wọn ṣe n ṣe e latilẹ niluu Oyo.

Wọn ni ki wọn yi i pada, ki Alaafin tuntun jẹ.Awọn wọnyi ni iṣi keji ninu awọn ọmọọba Oyo, ti yoo tako iyansipo Owoade Abimbola.

Awọn marun-un ni wọn ti kọkọ dide tẹlẹ, ti wọn ni awọn ko forukọ Owoade ranṣẹ s'ijọba.

'Ọ̀rọ̀ Àwíṣẹ Àgbáyé, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wande Abimbola ni Makinde tẹle, òun ló sọ fún Makinde pé Owoade ni Ifá mú'

Àkọlé fídíò, "Ọmọ oṣù méje ni ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ bọ́ọ̀lù gbígbà, ikọ̀ Chelsea, Napoli ti ránṣẹ́ sí i lọ́mọ ọdún mẹ́ta"

Oyomesi dá padà fún Makinde nípa ẹ̀sùn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lórí yíyan Alaafin

Aworan Bashorun Oyo ati Gomina Oyo

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn afọbajẹ niluu Oyo, Oyomesi ti kesi gomina ipinlẹ Oyo lati jawọ ninu fifi ilọkulọ lọ awọn afọbajẹ lori iyansipo Alaafin tuntun.

Bẹẹ ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Oyo labẹ iṣakoso Gomina Seyi Makinde, kede Omooba Owoade gẹgẹ bii alaafin tuntun ni ọsẹ to kọja, ti wọn si gbe ọpa aṣẹ fun ni ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun 2024.

Nigba ti Gomina n sọrọ nibi ayẹyẹ gbigbe ọpa aṣẹ fun Alaafin tuntun, Makinde ni gbogbo awọn to gba owo abẹtẹlẹ lori yiyan Alaafin lo maa foju wina ofin.

"Ọdun 2022 ni ipo Alaafin ṣofo, a si n mura eto idibo nigba naa, awọn eeyan wa sọ fun mi pe mo gbọdọ buwọlu ẹni ti yoo di Alaafin, bi bẹẹ kọ, awọn eeyan ilu Oyo ko ni dibo fun mi.

"Mo wa da wọn lohun pe, mi o bikita nipa ibo awọn eeyan fun mi bi ko ṣe nipa ṣiṣe ohun to tọ fun ilu Oyo, awọn eeyan Oyo si dibo fun mi daadaa, mo si gbagbọ pe wọn ko ni jawọ tilẹyin wọn fun mi.

"Ẹ jẹ ki n sare sọ ni ṣoki nipa awọn to fẹ doju aṣa wa bolẹ ni Oyo, ijọba ko ni sinmi. A o pe wọn lẹjọ.

"Wọn yoo foju wina ofin lori owo ti won ti gba ayafi ti wọn ba pada lọ ba kabiesi fun idariji.

"Ti Kabiesi ba forijin wọn, emi naa yoo darijin wọn."

"A lero pe Gomina yoo fun wa ni ọwọ to yẹ wa lori ọrọ Alaafin"

Ninu lẹta kan ni agtbẹjọro Oyomesi, Kunle Sobaloju kọ si ijọba ipinlẹ Oyo, fẹsun kan Gomina ipinlẹ pe o n sọrọ odi lati tabuku awọn Oyomesi to n di opo aṣa ati ise Oyo.

Lẹta ọhun ni Bashorun Oyo, Oloye agba Yusuf Akinade Ayoola Layinka, Oloye agba Wakeel Akindele Oyodepo, Lagunna Oyo, Oloye agbe Hamzt Yusuf, Akinniku Oyo, Oloye Wahab Oyetunji ati Oloye Gbadebo buwọlu .

Ninu lẹta naa to tẹ BBC News Yoruba lọwọ, awọn Oyomesi kọminu lori ọrọ ti Gomina sọ ni ita gbangba , to si fẹsun kan awọn Oyomesi pe wọn gba riba lori iyansipo Alaafin Oyo.

"A mọ pe Ọlọla julọ lẹtọ lati duro ti igbesẹ rẹ ni ile ẹjọ ṣugbọn a n rọ Gomina lati pese ẹri lori gbogbo ohun to sọ nipa Oyomesi.

"Oyomesi, ni ibọwọ fun ipo Gomina ni a ṣe kọ lati ma ba Gomina pariwo nitori o tabuku si aṣọ aponle.

"A n rọ gomina lati jawọ ninu sisọ ohun ti ko mọ, ti ẹri ba wa lọwọ gomina pe awọn afọbajẹ gba riba, a gba ni imọran lati mu wa si ile ẹjọ nibi ti wọn yoo ti yanana rẹ ni ẹkunrẹrẹ.

Oyomesi ni awọn n rọ Gomina ipinlẹ Oyo lati se suuru lori ọrọ yii, ko si jẹ ki ileẹjọ yanju ọrọ to wa ni iwaju rẹ.

"Oyomesi duro lori ofin ati ibọwọ fun ipo rẹ, a lero pe iwọ yoo fun wa ni ọwọ to yẹ wa lori ọrọ yii.

"Awọn Oyomesi duro le lori aṣa ilẹ Oyo. Gomina ni lati mọ pe a le pe lẹjọ lori pipa irọ mọ Oyomesi pẹlu ọfisi "