Aláàfin tuntun wọ ìlú Oyo, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Others
Pẹlu iduunu ati ayọ ni awọn ọmọbibi ilu Oyo ati awọn olugbe rẹ fi jade lati ki Kabiyesi Alaafin ti ilu Oyo titun Ọba Akeem Abimbola Owoade pada silu Oyo lẹyin ti o gba ọpa aṣẹ lọwọ Gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti Kabiyesi si yi oju abata po lẹẹmẹta lọsan-an ọjọ Aje, ọjọ Kẹtala, oṣu Kiini ọdun 2023.
Aṣa yiyi abata po ni ilu jẹ eyi ti Ọba tuntun to ba ṣẹṣẹ jẹ Alaafin maa n ṣe lati fi ki awọn ara ilu kuule tawọn ilu naa yoo si maa ki kaabọ ko to wọ Ipebi.
Gẹgẹ bi iṣe ilu Oyo, Alaafin tuntun naa ko i tii le wọ aafin titi to fi maa pari gbogbo awọn eto ati oro to jẹ mọ ipo Alaafin.
Mọgaji ile Agunloye Aguro nibi ti Alaafin tuntun naa ti jade, Alagba Owoade Adediwura fi idunnu rẹ han pẹlu bi oye Alaafin ṣe wa lati inu idile wọn.
Alagba Owoade ni ile awọn ko gba ero ti gbogbo ilu si tu jade lati ki Alaafin tuntun naa kaabọ ati pe niṣe ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ gba gbogbo ilu Oyo.
Magaji Owoade juwe Alaafin tuntunbii onisuuru eeyan ti o ko eniyan mọra, to si ni oun ni igbagbọ pe iyansipo rẹ yoo mu idagbasoke nla ba ilu Oyo.
BBC News Yoruba ṣe abẹwo si aafin Oyo lati wo bi nnkan ṣe n lọ nibẹ.
A ṣe alabaapade ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Wasiu Bolaji to jẹ Kudefu ti ilu Oyo to si ṣalaye wi pe lati igba ti Ọba Adeyemi Olayiwola ti waja ni aafin ọhun ti wa ninu ọfọ titi di asiko ti wọn kede Alaafin tuntun yii.
Kudefu ṣalaye wi pe nisẹ ni oungbẹ Ọba ti n gbẹ awọn ara ilu Oyo lati bii ọdun mẹta ti Oba Adeyemi ti wọ kaa ilẹ sun, ti inu ọpọlọpọ si n dun nisin-in tí Ọba tuntun tí de.
Alaafin yoo lo ọjọ 101 lati ṣe oro Ọba jíjẹ
Ni kete ti Alaafin tuntun wọ ilu Oyo, to si yi abata po ni ẹẹmẹta ni o wọ Ipebi lọ.
Amọ lodi si awọn aṣa ilẹ Yoruba tio ọba maa n lo ọjọ meje si ọjọ mọkanla ni Ipebi, oṣu mẹta ati ọjọ mọkanla gbako ni Alaafin Oyo maa n lo lati fi ṣoro ọba jijẹ.
Ọkan lara awọn oniṣẹṣe to wa ni aafin, Ọbadaisi Omobolade ni ko gba ẹnu ọmọ ilu Oyo kankan lati sọ ibi ti Alaafin tuntun naa wa bayii nitori bi ilu Oyo ṣe n ṣe ipebi yatọ si ti awọn ilu miran.
Omobolade salaye wi pe oṣu mẹta ati ọjọ mọkanla ni Alaafin gbogbo maa n lo ni ipẹbi gẹgẹ bi iṣe ilu Oyo.
O tẹsiwaju wi pe ko gba ẹnu ọmọ Oyo kankan lati sọ boya Kabiyesi ti wa ni ipẹbi, nitori eewọ ni lati sọ pẹ Kabiyesi wa ni ipẹbi niluu Oyo.
"Gbogbo Alaafin Oyo lo maa n ṣe oro oloṣu mẹta ati ọjọ mọkanla ti yoo si kadii rẹ nilẹ ni agbegbe Koso."
Omobolade ni oro naa ko ni di Alaafin lọwọ lati yọju si awọn nnkan pataki to yẹ ko ṣe, o ni bi o ba ti n yọju sibi awọn eto pataki ti ijọba pe e si ni yoo maa pada si ipebi titi ọjọ naa yoo fi pe.
O tun ṣalaye wi pe bi Kabiyesi ko ba pari awọn oro to yẹ ko lẹtọọ lati wọ aafin.















