Àhesọ lásán ni pé torí kí Seyi Tinubu lè dupò gómìnà ní 2027 l'Eko ni ilé fi yọ Obasa nípò - APC

Aworan Mudashiru Obasa ati Seyi Tinubu

Oríṣun àwòrán, Hon Mudashiru Obasa/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Eko ti sọrọ lori iyọnipo olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Họnarebu Mudashiru Obasa.

Ọpọ eeyan lo ti n sọ lori itakun ayelujara wi pe nitori ki ọmọ aarẹ Seyi Tinubu le lanfaani lati dije fun ipo gomina nipinlẹ Eko lọdun 2027 ni ile fi yọ Họnarebu Obasa nipo.

Amọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Họnarebu Seye Oladejo, sọ fun BBC Yoruba pe irọ to jina si ootọ lọrọ naa.

Ọgbẹni Oladejo sọ pe ahesọ ọrọ lasan lawọn eeyan n gbe kiri.

''Mo le fi da a yin loju pe rọ nla ni, ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Ṣe ẹ mọ pe ti iru nnkan bayii ba ti ṣẹlẹ, oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan maa n gbe kiri, gbọyi sọyi maa n pọ gan an.

Bo ya ohun ti a ko ba fi we ni pe lọjọ iku erin, oriṣiiriṣii ọbẹ ni a maa n ri.

Mi o tiẹ ro pe ọmọ aarẹ gan an funra rẹ ti jade lati sọ pe oun fẹ dije fun ipo gomina.

Ati pe ṣe idije gomina ọdun 2027 lo kan lọrọ wa bayii ninu ẹgbẹ APC ipinlẹ Eko?

Bi a ṣe maa kẹsẹ jari ninu iṣejọba wa ti idẹrun fi maa bawọn araalu lo jẹ wa logun bayii,'' Ọgbẹni Oladejo lo sọ bẹẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko sọ pe ''ohun to fara jọ ọrọ ibo rara ninu ẹgbẹ wa bayii ko ju ọrọ ibo ijọba ibilẹ to n bọ lọ nipinlẹ Eko.

Ọrọ idije fun ipo gomina lọdun 2027 ko tiẹ ti si ninu ọrọ wa rara ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Eko.

Bi asiko ba to lati dije fun ipo gomina, awọn agbaagba inu ẹgbẹ lo maa jokoo yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ APC ninu eto idibo ọdun 2027.''

''Yiyọ olori ile nipo ko kan ẹgbẹ APC, aarin awọn aṣofin lo wa''

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko fikun ọrọ rẹ wi pe yiyọ olori ile nipo wa laarin awọn ọmọ ile aṣofin ipinlẹ Eko.

O ni kii sẹ ọrọ ti ẹgbẹ le dasi rara ''tori awọn ni wọn mọ nnkan ti wọn ri ti wọn fi gbe igbesẹ ti wọn gbe.''

Họnarebu Oladejo sọ pe ọrọ abẹle laarin awọn aṣofin ni iyọnipo Obasa nipo olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko.

''Nigba tawọn aṣofin n yan awọn olori wọn, ẹgbẹ oṣelu APC ko bawọn da si i, bakan naa ẹgbẹ ko ni da si ọrọ naa nigba ti wọn gbe igbesẹ lati yọ olori ile nipo.

Bo ya ohun tawọn araalu to yan wọn sipo sọ fun wọn ni wọn tiẹ n ṣe nipa yiyọ olori ile nipo.

Eyi gan an tiẹ tun wa fihan wi pe eto ijọba awarawa n gberu si papaa julọ nipinlẹ Eko.''

Ọgbẹni Oladejo ni awọn aṣofin le ṣe ohunkohun to ba wu wọn labẹ ofin lai si pe ẹnikẹni di wọn lọwọ.

Lori ẹsun aṣilo agbara ati iwa ibajẹ ti wọn fi kan Obasa, agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn aṣofin naa lo mọ nnkan ti wọn ri ti wọn fi sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, "Ọmọ oṣù méje ni ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ bọ́ọ̀lù gbígbà, ikọ̀ Chelsea, Napoli ti ránṣẹ́ sí i lọ́mọ ọdún mẹ́ta"

Wo ohun mẹ́wàá nípa Mojisola Meranda, olóri ilé aṣòfin tuntun l’Eko

Mojisola Lasbat Meranda

Oríṣun àwòrán, Mojisola Lasbat Meranda

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti burawọle fun Mojisola Lasbat Meranda, gẹgẹ bi olori ile tuntun lẹyin ti wọn yọ Mudashiru Obasa bii jiga lọjọ Aje.

Obinrin naa ni obinrin akọkọ ti yoo jẹ olori ile aṣofin nilẹ Yoruba.

Ṣaaju iburawọle rẹ gẹgẹ bii olori ile ọhun, oun ni igbakeji olori naa ki wọn to fi ibo yọ Obasa nipo.

Bi wọn ṣe yọ Obasa naa ko ṣẹyin ẹsun aṣemaṣe ati aṣilo ipo ti ile ọhun fi kan an.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa ni pe o na owo ti iye rẹ to biliọnu mẹtadinlogun naira fun atunṣe geeti ile aṣofin ọhun, amọ o ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa.

Wo awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa olori ile tuntun naa

Mojisola Lasbat Meranda

Oríṣun àwòrán, Mojisola Lasbat Meranda

  • Ọjọ kini, oṣu Kẹjọ, ọdun 1980 ni wọn bi Mojisola Lasbat Meranda si idile ori ade Ojora, Aromire, Onitana, Oloto, ati Oniru niluu Eko
  • O kẹkọọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ Randle Primary School ati ile ẹkọ girama Ansar-Ud-Deen, ko to lọ si Lagos State University lọdun 2013 ati ile ẹkọ ijọba apapọ ilu Eko, UNILAG
  • Meranda ṣiṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko ati ileeṣẹ Cirrus Nigeria Limited fun ọpọ ọdun
  • O tun lo ọpọ ọdun ni ijọba ibilẹ Apapa ko to di kansẹlọ fun eto ẹkọ
  • Ọdun 2015 ni wọn dibo yan an sipo aṣofin, wọn si ti dibo yan an nigba meji ọtọtọ
  • Gẹgẹ bii aṣofin, ṣiṣe atunṣe awọn ofin to wa nilẹ tẹlẹ lo jẹ Meranda logun dipo gbigbe awọn ofin tuntun kalẹ, bẹẹ lo tun ṣe awọn akanṣe iṣe ni ẹkun to n ṣoju fun
  • O jẹ ọkan lara awọn aṣofin to n ja fun ẹtọ obinrin, to si n pe fun ki awọn obinrin maa wa nipo adari
  • Meranda ni ọkan lara awọn obinrin mẹrin to wa nile aṣofin Eko
  • Ile ọkọ ni obinrin naa wa, o si fẹran lati maa kawe lọpọ igba
  • Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kini, ọdun 2025 ni wọn dibo yan an sipo olori ile aṣofin ipinlẹ Eko lẹyin ti wọn fa Mudashiru Obasa yọ

Ilé aṣòfin Eko yọ Obasa kúrò nípò Olórí ilé

Mudashiru Obasa

Oríṣun àwòrán, Mudashiru Obasa/Instagram

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko ti yẹ àga nídìí abẹnugan ilé aṣòfin náà, Mudashiru Obasa fẹ́sùn àwọn ìwà kò tọ́ kan.

Àwọn aṣòfin méjìlélọ́gbọ̀n ló tọwọ́bọ ìwé láti yọ Obasa nípò.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, igbákejì Obasa tẹ́lẹ̀, Lasbat Meranda ni wọ́n ti búra wọlé fún báyìí láti gba ipò abẹnugan ilé aṣòfin náà.

Àwọn ìwà àjẹbánu àti ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ ni wọ́n kà sí Obasa lọ́rùn.

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní Obasa wà ní Atlanta, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lásìkò tí ìyọnípò náà wáyé.

Ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà ọdún 2015 ni wọ́n kọ́kọ́ dìbò yan Obasa gẹ́gẹ́ bí Abẹnugan ilé aṣòfin Eko.

Onírúurú àwọn ẹ̀sùn ni wọ́n ti ń kà sí Obasa lọ́rùn, tí àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánù EFCC sì ti ránṣẹ́ pè é fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àmọ́ tí wọn kò gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn kankan.

Ta ni Mudashiru Obasa?

Ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kọkànlá ọdún 1972 ni wọ́n bí Mudashiru Obasa ní Agege, ìpínlẹ̀ Eko.

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St Thomas Acquinas Primary School, Surulere, tó sì tẹ̀síwájú láti lọ sílé ẹ̀kọ́ girama Archbishop Aggey Memorial Secondary school, Mushin, Ilasamaja.

Ní ọdún 2006 ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Lagos State University.

Ọdún 1999 ló gbé àpótí ìbò láti díje fún ipò káhúnsílọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Agege lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy tó sì wọlé ìbò náà.

Láàárín ọdún 1999 sí 2002 ló fi wà ní ipò káhúnsílọ̀ náà.

Ní 2007 ló gbégbá ìbò láti lọ ṣojú ẹkùn Agege ní ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko tó sì rí ìyànsípò padà lọ́dún 2011, 2015, 2019 àti 2023.

Ní ọdún 2015 ni wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé aṣòfin Eko.

Láti ọdún 2020 ló ti ń kojú ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu àmọ́ tó jiyàn gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn.