Ìdí rèé tí mo fi tẹríba, kúnlẹ̀ kí Emir Ilorin - Timi Ede ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Timi of Ede/Instagram
Awuyewuye ti suyọ lori fidio kan to gba ori ayelujara kan eyi to se afihan Timi Agbale ilu Ede, Ọba Munirudeen Adesola Lawal, Laminisa Kinni to tẹriba, to si tun kunlẹ ki Emir ilu Ilorin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari.
Ọpọ ọmọ Yoruba lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu isẹlẹ naa eyi ti wọn lo tabuku ọwọ to wa fun ori ade ati ori itẹ nilẹ Yoruba.
Ọrọ naa si ti di ohun tawọn ọmọ Yoruba nile loko ati nilẹ okeere n jiroro le lori papaa julọ lori itakun ayelujara.
Ninu ọrọ tiẹ, ilumọọka onkọwe, Ọgbẹni Tunde Odesola, to jẹ ọmọbibi ipinlẹ Osun sọ pe ihuwasi Timi Agbale ilu Ede jẹ iwa agọ eyi to ba ni loju jẹ gan an.
Ọgbẹni Odesola fi aidunnu rẹ han nipa sisọ pe ''Kabiyesi ooooo, ki didinrin pẹ lori, ki irinkurin pẹ lẹsẹ, ki ijẹkukujẹ pẹ lẹnu.''
Gbajugbaja onkọwe naa ni ọfa Timi ti di nnkan ti wọn fi n mu ọti ogogoro.
O ni ko si ani-ani ni pe ''nnkan n ṣe wa'' gẹgẹ bi ọrọ agbaọjẹ oṣere Baba Wande.
Iṣẹlẹ naa tun ti jẹ kawọn eeyan maa sọ nipa ibaṣepọ to wa laarin awọn ọba ilẹ Yoruba atawọn ori-ade lati ẹkun miran lorilẹede Naijiria.
Ọpọ eeyan ni ohun ti Timi Agbale ilu Ede ṣe tabuku ilu Ede, o si tun tabuku gbogbo ilẹ Yoruba.
Amọ ṣa, awọn kan ni bi kabiyesi Timi Agbale ilu Ede ṣe kunlẹ ki Emiri ilu Ilorin kii ṣe ohun to buru rara.
Wọn ni ki awọn eeyan ma yi ọrọ naa mọ Timi lọwọ tori o buyi kun Emir Ilorin lo jẹ ko ṣe bẹẹ.
''Timi ilu Ede kunlẹ ki Emir ilu Ilorin tori ogbo ati ailera rẹ''
Aafin Timi Agbale ilu Ede ti sọrọ lori fidio to ṣafihan bi Kabiyesi Ọba Adeshola Lawal sẹ kunlẹ ki Emir ilu Ilorin eleyii ti ọpọ eeyan ti bu ẹnu ẹtẹ lu lori ayelujara.
Aafin Timi ṣalaye ninu atẹjade kan ti oludamọran kabiyesi naa lori ọrọ iroyin, Tijani Abdulraheem Adekilekun fi sita ṣalaye pe Timi Agbale ṣe apọnle Emir Ilorin lo fi kunlẹ, kii ṣe wi pe o n fi oriade wọlẹ.
Aafin Timi sọ ninu atẹjede naa wi pe ibọwọ fawọn agbalagba atawọn ọba alaye wa ninu aṣa ati iṣe Yoruba, tori naa bi kabiyesi ṣe ki Emir Ilorin wa ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣe Yoruba.
''Timi Agbale ilu Ede kunlẹ lati ki Emir ilu Ilorin nitori ai le dide Emir tori ọjọ ori tabi ilera rẹ.''
Ọgbẹni Adekilekun sọ ninu atẹjade naa pe ọpọ eeyan lo ti ṣi fidio to lu ori ayelujara pa yii tumọ.
O ni aafin Timi ilu Ede ṣe akiyesi wi pe Emir ilu Ilorin ko le dide lati ki ẹnikẹni nibi eto naa to fi mọ Timi Agbale toun naa wa nibẹ.
Aafin Timi ilu Ede wa rọ awọn eeyan to n sọrọ lori fọnran yii wi pe ki wọn bọwọ fun aṣa ati iṣe Yoruba.
''A rọ gbogbo eeyan wi pe ki wọn dẹkun sisọ ọrọ kobakungbe si Timi Agbale ilu Ede nitori fidio to ṣafihan bi kabiyesi ṣe ki Emir Ilu Ilorin.
O ṣe pataki fawọn eeyan lati mọ idi ti kabiyesi fi kunlẹ ki Emir ilu Ilorin ki wọn to maa sọrọ lori fidio to wa lori itakun ayelujara.
Timi Agbale ilu Ede si wa lara awọn ọba alaye to ti wa lati igba iṣẹmbaye nilẹ Yoruba, ko si si ẹnikan to le tabuku ipo naa.
A tun fi dawọn eeyan loju lẹẹkan si pe nnkan ti kabiyesi ṣe wa ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣe Yoruba, kii ṣe lati fi tabuku apere Timi Agbale ilu Ede,'' Aafin Timi lo ṣalaye bẹẹ ninu atẹjade ti wọn fi sita.















