Wó kókó ọ̀rọ̀ tí Oriyomi sọ pẹ̀lú omijé lójú lẹ́yìn tí wọ́n gba béèlì rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oriyomi Hamzat
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja agbohunafẹfẹ n ni, Oriyọmi Hamzat, ti bawọn ololufẹ rẹ sọrọ lẹyin ti wọn gba beeli rẹ lọgba ẹwọn lori ọrọ awọn ọmọde marundinlogoji to ku nibi apejẹ ti Olori Ooni tẹlẹ, Naomi ṣagbatẹru rẹ niluu Ibadan.

Nigba to n bawọn ololufẹ rẹ sọrọ ni ileeṣẹ redio Agidigbo ni Ibadan lonii ọjọ Iṣẹgun, Oriyomi ni ''asiko ti mo wa yii, asiko idakẹjẹ ni.''

Niṣe ni Oriyomi n da omi loju pẹrẹ pẹrẹ bi o ti n sọrọ, koda, agidi lo fi pada bawọn ọgọọrọ ololufẹ rẹ ti wọn wa ki i kaabọ sọrọ.

Lẹyin to fi aṣọ ilewọ nu omije nu loju rẹ fun ọpọ igba ni o gbiyanju lati sọ pe ''ẹ ṣe mo dupẹ ẹ sẹ gan an ni.

Ọpọ awọn ololufẹ Oriyomi ni wọn ti n paya lati igba ti ile ẹjọ ju u sẹwọn pẹlu Olori Naomi lori iṣẹlẹ.

Lanaa ọjọ Aje ọjọ kẹtala ni ile ẹjọ giga niluu gba beeli Oriyomi ati Olori tẹlẹ Naomi.

Ohun to waye ree nile ẹjọ majisireeti lori ẹjọ Oriyomi, Naomi ati ọga ile ẹkọ

Igbẹjọ to yẹ ko waye l'owurọ ọjọ Aje ni ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku tọ n bẹ nilu Ibadan lori awọn ẹsun ti wọn fi kan gbajugbaja agbohunafẹfẹ, Oriyọmi Hamzat, Olori tẹlẹri, Naomi Ṣilẹkunọla ati alakoso ile ẹkọ ti iṣẹlẹ naa ti waye, Abdullahi Fasasi di sisun siwaju bayii nitori awọn ẹni afẹsunkan naa ti ko fi ara han nile ẹjọ.

Lẹyin igbẹjọ to waye saaju asiko yii, ile ẹjọ naa beere amọran lọwọ ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto idajọ lori awọn ẹsun ti fi kan awọn eeyan mẹtẹẹta naa, ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto idajọ si fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn mẹtẹẹta ni wọn ni ẹjọ late jẹ, ti wọn si da ọjọ kẹtala oṣu kini ọdun yii fun igbẹjọ mii.

Ṣugbọn aifi ara han awọn mẹtẹẹta lo mu ki adajọ Olubisi Ogunkanmi sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu yii.

Alaye Abdulfatai Oyedeji to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro fun alakoso ile ẹkọ 'Islamic Secondary School' ṣe fun awọn akọroyin ni pe ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku ko ni agbara lati da ẹjọ naa, ṣugbọn ile ẹjọ naa gbọdọ kọkọ gbọ tẹnu awọn eeyan ti ẹka eto idajọ pe lejọ ki wọn to fi ọrọ wọn ṣọwọ si ile ẹjọ giga to n bẹ ni agbegbe Ring Road niluu Ibadan.

Oyedeji ṣe alaye siwaju sii wi pe ohun to ṣeeṣe ko ṣẹlẹ ti awọn ẹni ti wọn fi ẹsun kan ba fi ara han nile ẹjọ Majistreeti Iyaganku lọjọ kẹtadinlogun oṣu yii ni ki ile ẹjọ fun ni anfani lati wi tẹnu wọn boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn. Lẹyin eyii sini ile naa yoo fi ẹjọ ṣọwọ si ile ẹjọ giga to n bẹ niluu Ibadan.