"Ọmọ oṣù méje ni ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ bọ́ọ̀lù gbígbà, ikọ̀ Chelsea, Napoli ti ránṣẹ́ sí i lọ́mọ ọdún mẹ́ta"

Àkọlé fídíò, "Ọmọ oṣù méje ni ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ bọ́ọ̀lù gbígbà, ikọ̀ Chelsea, Napoli ti ránṣẹ́ sí i lọ́mọ ọdún mẹ́ta"
"Ọmọ oṣù méje ni ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ bọ́ọ̀lù gbígbà, ikọ̀ Chelsea, Napoli ti ránṣẹ́ sí i lọ́mọ ọdún mẹ́ta"

Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọmọde kan, ọmọ ọdun mẹta, ti orukọ rẹ n jẹ Tobenna Uchendu, ti ọpọ eeyan mọ si 'Star Boy'.

Ere Bọọlu ni ọmọdekunrin yii yan laayo, to si ti bẹrẹ ere bọọlu gbigba lati ọmọ osu meje.

Lọdun 2023 ni fọnran Tobenna gbalẹ lori ayelujara eyi to safihan bo se n gba bọọlu.

Tobenna Uchendu

"Ọmọ mi ti gba bọọlu pọ pẹlu Victor Osimhen, tii se agbawaju fun ikọ agbabọlu Naijiria ati Galatasaray"

Nigba to n ba BBC sọrọ, baba ọmọdekunrin naa, Obi Uchendu, ti ọpọ eeyan tun mọ si Baba Star Boy lori ayelujara salaye bi ẹbun ere bọọlu se gbilẹ lọkan ọmọ rẹ.

Uchendu ni ọmọ oun ti gba bọọlu pọ pẹlu Victor Osimhen, tii se agbawaju fun ikọ agbabọlu Naijiria ati Galatasaray.

"Awọn ẹgbẹ agbabọlu kan wa, to maa n gba iru ọmọde bayii pẹlu ọjọ ori rẹ

Eyi lo mu ki ikọ agbabọọlu Chelsea ati Napoli ransẹ pe wa,

Ọmọ mi le gba bọọlu si inu awọn, o le gba si apa ọtun tabi si osi.

O le ge ege, ti wọn ba si gbe ike silẹ, yoo ge ege wọ aarin awọn ike naa.

Mbappe tilẹ Naijiria ni wọn n pe ọmọ mi."

"Erongba mi fun Tobenna ni pe lọjọ kan, ko gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu Naijira, Super Eagles."

Nigba to n salaye bi eto igbaradi fun kikọ ere bọọlu Tobenna se maa n bẹrẹ, Uchendu ni kete ti oun ba ti ji laarọ, ni igbara ere bọọlu bẹrẹ fun ọmọ oun.

"Mo maa n se iwuri fun pe ko jẹ ka lọ gba bọọlu.

Ọmọ jẹjẹ ni Tobenna, o ni ọyaya, o maa n se awada, to si maa n yara kankan lati tete mọ ohun ti wọn ba kọ ọ.

Mo maa n kọ ni bọọlu gbigba lojoojumọ, adura mi si ni pe ki n ri ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo pese anfaani fun ẹbun rẹ lati gbera si.

Gẹgẹ bii baba, erongba mi fun Tobenna ni pe lọjọ kan, ko gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu Naijira, Super Eagles."