"Russia mú ọkọ mi sí àhámọ́, halẹ̀ láti fìyà jẹ ẹ́ bí ń kò bá ṣe alamí láti dalẹ̀ orílẹ̀èdè mi, Ukraine"

- Author, Will Vernon
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Svitlana ní òun kò gbà á lérò rí láti dalẹ̀ orílẹ̀èdè òun fún ìṣẹ̀jú kan rí.
"Ọkọ mi kò ní dáríjì mí láéláé, ó sọ bí a ṣe pàdé rẹ̀ ní ilé rẹ̀ ní Kyiv.
Láti bíi ọdún méjì ni Svitlana, ẹni ọdún méjìlélógójì ti ń rétí láti gbọ́ láti ọdọ̀ ọkọ rẹ̀, Dima, tó jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó lẹ́nu iṣẹ́ ológun tó wà ní àhámọ́ orílẹ̀èdè Russia.
Ṣàdédé ni ẹnìkan pè Svitlana, tó sọ fun pé àwọn máa ṣe ọkọ rẹ̀ dáadáa ní ẹ̀wọ̀n tó wà tàbí kí àwọn tú ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ pàápàá tó bá gbà láti dalẹ̀ orílẹ̀ èdè rẹ̀.

"Nọ́mbà Ukraine kan pè mí, mo gbe, ọkùnrin kan tó pe ara rẹ̀ ní Dmitry ló bá mi sọ̀rọ̀, èdè Russia ló fi sọ̀rọ̀," Svitlana ṣàlàyé.
Ó ní ọkùnrin náà sọ fún òun pé kí òun lọ jó iléeṣẹ́ ológun kan tàbí kí òun dáná sun ọkọ̀ ogun iléeṣẹ́ ológun Russia tàbí kí òun lọ ba àpótí iná mọ̀nàmọ́ná iléeṣẹ́ ìrìnnà ojú irin Ukraine jẹ́.
Nǹkan mìíràn tó bèèrè fún ni iléeṣẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú tàbí sọ ibi tí ohun èlò tó ń dá ààbò bo ojú òfurufú Ukraine lọ́wọ́ àwọn àdó olóró tí Russia ń jù gba ojú òfurufú.
Bí Dmitry ṣe ń ka àwọn nǹkan tó fẹ́ kó ṣe ni Svitlana rántí ohun tí ìjọba ti sọ fún wọn pé tí ẹnikẹ́ni bá pè wọ́n, kí wọ́n ya àwòrán àti gba ohun onítọ̀hún sílẹ̀, kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí.
Svitlana ṣàfihàn ohùn tó gbà àtàwọn àwòrán àtàwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tí Dmitry fi ránṣẹ́ si han BBC.
Iléeṣẹ́ ààbò Ukraine, SBU sọ fun pé kó máa bá Dmitry sọ̀rọ̀ bí ẹni pé yóò ṣe àwọn nǹkan tó fẹ́ táwọn yóò sì máa bá ìwádìí àwọn lọ.
Ìdí èyí ló ṣe sọ fun pé òun yóò lọ sọ iná sí iléeṣẹ́ ìrìnnà ojú irin.
"Ẹ̀bi rẹ ni pé à ń fìyà jẹ ọkọ rẹ"
Svitlana tẹ àwọn ohùn tó gbá sílẹ̀ fún ikọ̀ ìròyìn BBC, tí Dmitry ń ṣàlàyé bí yóò ṣe iṣẹ́ tí àwọn ran.
Dmitry, nínú ohùn tí wọ́n gbà sílẹ̀ náà sọ fún Svitlana pé kó da epo bẹntiróòlù sínú ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń tọná kan, kó lọ sí ojúkò reluwé kan láti lọ ṣe iṣẹ́ náà.
"Ri dájú pé ẹ̀rọ ayàwòrán kankan kò sí ní agbègbè náà. Wọ fìlà láti bojú láti ṣògùn àbámọ̀."
Bákan náà ló sọ fun pé kí ó pa nẹ́tíwọ́ọ̀kì orí fóònù rẹ̀ tó bá ti wà ní ibùsọ̀ kan sí méjì agbègbè tó ti fẹ́ ṣọṣẹ́ náà, kó sì fi ẹ̀rí ránṣẹ́ sóhun pé òun ti jíṣẹ́ náà.
Dmitry ní òun máa ṣe bí ó ṣe máa bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ àti pé ó lè fi ẹrù ránṣẹ́ sí i.

Ìgbà tó yá ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sọ fún Svitlana pé Russia ni ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ wà lóòótọ́, pé kó má ba sọ̀rọ̀ mọ́.
Svitlana sọ fún Dmitry pé òun ti yí ìpinnu òun padà lórí ìgbésẹ̀ náà.
Èyí ló mú kí Dmitry bẹ̀rẹ̀ sí ní dúnkokò mọ́ Svitlana pé òun máa pa ọkọ rẹ̀, tí kò sì ní ri mọ títí láé.
"Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ló fi ń sọ fún mi pé wọ́n ń fìyà jẹ ọkọ mi, èmi ni mò sì ń fà á."
" Mo máa ń rò ó pé ọkùnrin náà kò mọ ibi tí ọkọ mi wà àmọ́ ọkàn mi tún máa ń sọ nígbà míì pé tó bá mọ̀ ńkọ́?"

Oríṣun àwòrán, Ukrainian Police Service
Iléeṣẹ́ ààbò SBU sọ fún BBC pé níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn alamí Russia kò ní àǹfàní kankan tó fẹ́ ṣe fún àwọn tó wà ní àhámọ́ Russia bíkòṣe ó tún máa mú nǹkan ṣòro sí i ni.
Àwọn aláṣẹ ń rọ gbogbo àwọn ẹbí táwọn alamí náà bá ti kàn sí láti fi tó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò létí kíákíá fún ààbò tó péye.
Ó ní ẹbí tó bá gbà láti ṣe ohun táwọn alamí náà bá ní kí wọ́n ṣe, àwọn máa kà wọ́n kún ẹni tó fẹ́ gbàbọ̀dè fún orílẹ̀ èdè wọn àti pé ẹ̀wọ̀n gbére ni ìjìyà tó pọ̀ jù fún ẹṣẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Àwọn aláṣẹ máa ń ṣe àfihàn orúkọ àwọn tó bá tú àṣìrí ibi táwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Ukraine wà fún Russia.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ọwọ́ ti bà ni wọ́n ṣe é nítorí owó, táwọn mìíràn sì ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ẹbí wọn tó wà ní ìgbèkùn.

Petro Yatsenko tó jẹ́ olórí iléeṣẹ́ ológun fáwọn tó wà ní àhámọ́ ogun Ukraine ní ìdá àádọ́ta àwọn tó wà ní àhámọ́ ni àwọn alamí Russia ti kàn sí.
Petro ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn náà ni ọkàn wọn ti gbọgbẹ́, tí wọ́n sì ṣetán láti ṣe ohunkóhun láti fi gba ìtúsílẹ̀ àwọn èèyàn wọn tó wà ní àhámọ́.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dídáná sun ọkọ̀ iléeṣẹ́ ológun kìí ṣe nǹkan tó lágbára, ó le dá ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn èèyàn.
Bákan náà ló ní wàhálà ńlá ni tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àfihàn ibi tí àwọn ọmọ ogun Ukraine wà fún Russia.
Ìjọba Russia sọ fún BBC pé irọ́ ni ẹ̀sùn pé àwọn ń lo àwọn ẹbí àwọn tó wà ní àhámọ́ àwọn láti fi jagun, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kan Ukraine pé àwọn lọ ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ni wọ́n tú ọkọ Svitlana, Dima kall kúrò ní àhámọ́.
Svitlana, Dima àti ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́rin ti ń gbé papọ̀ padà láyọ̀ àti àláfíà.
Ó ní inú òun dùn gan-an nígbà tí ọkọ òun gba ìtúsílẹ̀, tó dàbí pé òun já ọkọ gbà kúrò lọ́wọ́ ikú.
Dima sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé gbogbo ìdúnkokò láti fi ìyà jẹ òun tí kò bá gbà láti ṣe nǹkan tí wọ́n ń fẹ́, ni wọn kò múṣẹ nítorí wọn kò fi ìyà jẹ òun.
Ó bá Dima lójijì nígbà tí Svitlana ṣàlàyé àwọn ìpè tó gbà fún-un.












