Ìwádìí ikú Mohbad dá ariwo, omíjé sílẹ̀ láàrin Yomi Fabiyi àti ìyá Mohbad

Yomi Fabiyi, Mohbad, ìyá Mohbad

Oríṣun àwòrán, BBC/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níṣe ni ọ̀rọ̀ di gbọ́nmi si omi ò to láàárín ìyá Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad tó ti di olóògbé àti gbajúmọ̀ òṣèré nnì, Yomi Fabiyi, níbi ètò kan tó wáyé lọ́jọ́rú ní ìpínlẹ̀ Eko.

Fabiyi, níbi àpérò àwọn akọ̀ròyìn tó wáyé ní ilé ìtura Raddison Blu tó wà ní Ikeja ìpínlẹ̀ Eko, ṣàlàyé àwọn nǹkan tó mọ nípa ikú Mohbad.

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 ni ìròyìn ikú akọrin tàkasúfèé náà gbòde sí ìyàlẹ́nu ọ̀pọ̀ èèyàn, táwọn èèyàn sì ń pè fún ìwádìí nípa okùnfà ikú ọmọ náà.

Nínú àlàyé rẹ̀ lórí ohun tó mọ̀ láti ìgbà tí ìwádìí ikú Mohbad ti bẹ̀rẹ̀, Yomi Fabiyi sọ níbi ètò náà pé àbúrò Mohbad, Adura Aloba kọ àtẹ̀jíṣẹ́ sí òun lórí ìkànnì Tiktok.

Ó ní Adura Aloba, nínú àtẹ̀jíṣẹ́ náà sọ fún òun pé, òun mọ nǹkan tó pa ẹ̀gbọ́n òun.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí Adura kàn sí òun lórí Tiktok ló sọ fún òun pé òun ní fídíò kan lórí fóònù tó ṣafihàn nǹkan tó ṣokùnfà ikú Mohbad.

"Adura ló fi fídíò kan ránṣẹ́ sí mi èyí tó ṣàfihàn bí ìyàwó Mohbad, Wunmi Aloba àti Mohbad ṣe ń ní ìfaǹfà nínú ilé, tó sì ti Mohbad ṣubú láti orí òkè ilé wọn"

Òṣèré náà sọ pé Adura sọ fún òun pé kí òun tó le fi ẹ̀rí náà kalẹ̀, òun máa gbà mílíọ̀nù mẹ́ta náírà, tó sì fi fídíò ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta ránṣẹ́ sí òun.

"Fídíò náà ṣàfihàn bí ìyàwó Mohbad, Wunmi Aloba àti Mohbad ṣe ń ní ìfaǹfà nínú ilé, tó sì ti Mohbad ṣubú láti orí òkè ilé wọn."

Ó fi kun pé, òun mú fídíò náà àtàwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tó wáyé láàárín àwọn méjéèjì lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ fi àwọn ẹ̀rí náà hàn.

Ó ní àgọ́ ọlọ́pàá ni wọ́n ti sọ fún òun pé, kìí ṣe Adura ló fi àtẹ̀jíṣẹ́ náà ránṣẹ́ sí òun bíkòṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Damola, tí Adura ta fóònù tó ń lò tẹ́lẹ̀ fún, ni ó kọ àtẹ̀jíṣẹ́ náà sí òun.

Fabiyi ní òun kò rí kí àwọn ọlọ́pàá gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí ẹ̀rí tí òun gbé síwájú wọn, ni òun fi pe àpérò ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn àgbáyé tí òun pè náà.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ó yẹ kí ẹ̀rí náà le mú àwọn ọlọ́pàá jí gìrì sí ojúṣe wọn ni, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bí òun ṣe rò rárá.

"Àwọn ọ̀rọ̀ tí Yomi Fabiyi ń sọ náà le ṣàkóbá fún Adura, n kò sì fẹ́ kí wọ́n pa á, bí wọ́n ṣe pa Mohbad ẹ̀gbọ́n rẹ̀"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí Yomi Fabiyi ń sọ yìí kò tẹ́ ìyá Mohbad lọ́rùn rárá, tó sì ní kí Fabiyi má fẹ̀sùn kan Adura Aloba rárá lórí ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

Ìyá Mohbad ní tó bá jẹ́ pé Adura mọ nǹkankan nípa ikú Mohbad, ó máa ti lọ sọ fún àwọn ọlọ́pàá tipẹ́tipẹ́ pàápàá ilé ẹjọ́ bí ìgbẹ́jọ́ lórí ikú ọmọ náà ṣe ti ń wáyé.

Ó sọ fún Yomi Fabiyi pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń sọ náà le ṣàkóbá fún Adura àti pé òun kò fẹ́ kí wọ́n pa Adura, bí wọ́n ṣe pa ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

"Damola ló fi orúkọ Adura kọ àtẹ̀jíṣẹ́ sí Yomi Fabiyi, mo fẹ́ gbe lọ sílé ẹjọ́ tẹ́lẹ̀ àmọ́ ó bẹ̀ mí pé òun kò mọ̀ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe máa rí nìyẹn.

"Ó dàbí pé wọ́n kàn fẹ́ ba ọmọ mi lórúkọ jẹ́ ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti sọ pé òun kò mọ nǹkankan lórí ẹ̀sùn yìí àmọ́ Fabiyi tún pe ìpàdé akọ̀ròyìn yìí le lórí.

Adura kò ní mọ nǹkan tó pa ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kó dákẹ́ láti ọjọ́ yìí.

Àmọ́ Yomi Fabiyi fun lésì pé, àtẹ̀jíṣẹ́ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí òun lọ jẹ òun lọgún àti pé òun kò ní ohunkóhun lòdì sí ọmọ náà.

O níọ̀nà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé Mohbad lọ́jọ́ tó jáde láyé, ni òun ń wá.

"Nígbà tí mo rí àtẹ̀jíṣẹ́ náà, mo rò pé ó fẹ́ ran ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ́wọ́ ni, tó bá jẹ́ pé ẹlòmíràn ló fi àtẹ̀jíṣẹ́ náà ránṣẹ́ sí mi, ẹ ò ní máa sọ nǹkan tí ẹ̀ ń sọ yìí," Yomi Fabiyi fèsì.