Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sọ̀rọ̀ lórí ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ ikú Mohbad yóò bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Mohbad
Kọmiṣọna eto idajọ nipinlẹ Eko, Lawal Pedro, SAN, ti ṣeleri pe igbẹjọ iku gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa ‘Mohbad’ Aloba yoo bẹrẹ laipẹ lati fi oju gbogbo awọn to lọwọ ninu iku rẹ lede.
Pedro lo sọ bẹẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aje lori eredi ti igbẹjọ naa ṣe falẹ lati ọdun kan le sẹyin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbẹjọ naa pe to bẹẹ latari oniruru iwadii ti awọn agbofinro n ṣe.
O ni “atupalẹ ‘forensic ati toxicology’ wa lara awọn iwadii naa, eyii ti yoo jẹ gbankọgbi ẹri niwaju ile ẹjọ.”
Agbẹjọro agba naa sọ siwaju si pe ilẹ Amẹrika ni wọn ti ṣe awọn iwadii ijinlẹ ọhunc nitori awọn kọlọrọsi to dana sun ibi ti wọn ti le ṣe niluu Eko, iyẹn Lagos DNA and Forensic Centre, lasiko iwọde EndSARS ọdun 2020.
O ni eredi ree ti awọn fi lọ sẹ awọn ayẹwo naa nilẹ Amẹrika.
Pedro fidi rẹ mulẹ pe esi awọn ayẹwo naa ti de siluu Eko bayii lati ilẹ Amẹrika fun igbẹjọ.
O wa sọ siwaju si pe awọn mọlẹbi oloogbe lo n da igbẹjọ ọhun duro latari pe wọn ni awọn fẹ ṣe ayẹwo oku rẹ funra awọn.
O ni “Awọn mọlẹbi Mohbad lo n da wa duro bayii lẹyin ti wọn ni awọn yoo ṣe ayẹwo tiwọn.
“Sibẹ sibẹ, igbẹjọ naa yoo bẹrẹ laipẹ, idajọ odod yoo si waye.















