Ohun tí ojú mi rí lẹ́nu iṣẹ́ ológun ló sọ mí di olórin Fuji – Ayinla Kollignton

Aworan Kollington Ayinla

Oríṣun àwòrán, IG//gen.kollingtonayinla/

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja ati agbaọjẹ ninu orin Fuji, Kolawole Rasaq Ilori, ẹni ti ọpọ mọ si General Kollington Ayinla ṣalaye bii ileeṣẹ ologun se fi tipatipa le lọ sidi orin kikọ.

O sọ eyi niluu ilorin nigba to n ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ.

Kollington Ayinla ni nigba ti oun jẹ ologun, ọkan ninu awọn Ọgagun pe orukọ oun sita.

“Ẹru ti ba mi, ti n ko si mọ ohun ti mo fẹ nitori mo ro pe wọn yoo fiya jẹ wa.

“Ṣugbọn wọn mu wa lọ si Hall B, ti wọn si ni ki a mu irinsẹ orin kan ti mo le fi kọ orin sugbọn n ko mọ eyi keyi lo.

“Mo gbiyanju lati lo awọn irinsẹ orin yii sugbọn ko yẹ mi rara titi ti ọmọ ologun kan fi ri mi ri pe o ni iṣoro pẹlu lilo irinsẹ orin naa, to si ran mi lọwọ.”

Ọdun 1967 ni Kolinghton darapọ mọ ileeṣẹ ologun niluu Abeokuta nigba to lọ ṣe abẹwo si ọrẹ rẹ kan, to si ri ninuu aṣọ ologun.

“Pẹlu bi mo ṣe fi ifẹ ran si ileeṣẹ ologun, n ko ga pupọ, ti ọjọ ori mo ko si to iye ọjọ ori ti wọn n bere fun.

“Eyi fẹ ki n jawọ sugbọn mo pinnu lọkan mi, ti mo si lọ fun ayẹwo wiwọ ileeṣẹ ologun.

“O ya ẹni o n se ayẹwo lẹnu pe mo pinnu lati darapọ mọ ileeṣẹ pẹlu bi o ṣe jẹ pe o n ko ga rara, to si buwọlu mi.

“Wọn fa irun ori mi ni abẹ igi, ti wọn si fun wa ni aṣṣo ologun.”

Kolington ni oun gba ileeṣẹ ologun naa pẹlu iye meji

“Mo bẹrẹ si ni ma ronu nipa igbesẹ mi nitori aṣọ to rẹwa ni mo fi darapọ mọ ileeṣẹ ologun, n ko fẹran wahala to wa ni ibẹ.”

O ni o dun oun pupọ nigba ti wọn ko gba laaye lati kopa ninu ogun abẹle , ti wọn si fi sinu ẹgbẹ orin.”Boya wọn ba ti pami,”

Kolington ni oun ni ba oloogbe Sikiru Ayinde Barrister sọrọ pe ko darapọ mọ ileeṣẹ ologun nigba to se abẹwo si ni ọgba ọmọ ologun.