Ta ni Olabisi Ejide Balogun, tí ikú rẹ̀ ń gbomi lójú ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà?

Oríṣun àwòrán, BalogunOlabisiEjideInstagram
Ṣé ni ori ayelujara, paapaa oju opo Instagram n gbona ni irọlẹ ọjọ Aiku ana, fún ọrọ arò àti ibanikẹdun eyi to n ṣe ọpọlọpọ eeyan ni haaa-jin.
Ọrọ ibanikẹdun naa ko si se lẹyin iku ilumọọka obìnrin kan, ti ọpọ mọ orukọ rẹ si Olabisi Ejide Balogun eyi to jade si igboro.
Ọpọ awọn oṣere tíátà sì ni wọn bọ si ori ayelujara lati sọrọ lori iku to pa oloogbe naa pẹlu oniruuru ọrọ ibanikẹdun.
Èyí si lo mu ki àwọn olólùfẹ́ wọn maa beere pe Ta ni Ejide tí ọ̀pọ̀ àwọn osere tíátà yìí ń ṣe ìdárò ikú rẹ?

Oríṣun àwòrán, IamkemikoredeInstagram
Idi ree ti BBC Yorùbá fi tọpinpin láti mọ si nipa gbajúmọ̀ olóògbé yìí àti irú ikú tó pa á.
Nínú iwadi wá, gẹgẹ bi ohun ti ọpọ to kẹdun lori iku rẹ sọ, arabinrin naa kii ṣe oṣere tíátà amọṣa o jẹ ẹni to sun mọ ọpọlọpọ awọn oṣere Tiata lorilẹede Naijiria, paapaa julọ awọn to n ṣe tiata lede Yoruba.
Awọn to mọ ọ tilẹ sọ wi pe ọkan lara awọn to sunmọ gbajumọ aṣiwaju ẹgbẹ awakọ lorilẹede Naijiria ni, Musiliu Ayinde Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ ni.

Oríṣun àwòrán, Saje tiologaInstagram
Lara àwọn òṣèré tíátà to daro Olabisi Ejide Balogun naa ni Madam Saje tí ó lọga àti Kemi Korede.
Ṣe ni àwọn osere tíátà naa si gbe àwòrán abẹla to ń jo soju opo wọn, ti wọn si n taraporo pe irawọ miran tun ja lulẹ.
Eeyan miran toun pẹlu daro rẹ, @jauntypayne naa fi idi eyi mulẹ ninu ọrọ idaro tirẹ pe owurọ ọjọ Abamẹta to kọja ni loogbe naa ṣi n sọ fun oun pe “oun ko ni gbọ awawi kankan bi ko ba wa si ibi ayẹyẹ naa ni Ọjọbọ.”















