Ipò wo ni Victor Boniface wà lẹ́yìn tó ní ìjàmbá ọkọ̀?

Aworan Victor Boniface

Oríṣun àwòrán, X/boniface_jrn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ agbabọọlu Leverkusen lorilẹede Germany ti sọrọ sita lori ipo ti agbabọọlu wọn to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria, Victor Boniface wa lẹyin to ni ijamba ọkọ ni orilẹede Germany.

Agbabọọlu atamatase Super Eagles naa ni iroyin ti a gbọ swi pe ori ko yọ ninu ijamba ọkọ lẹyin wakati diẹ to pari ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Eintracht Franfurt ni ligi ilẹ Germany.

Boniface lo kọkọ gbe fọnran ati aworan ijamba naa si ori ayelujara sugbọn o ti yọ kuro loju opo rẹ lẹyin akoko diẹ.

O kọ soju opo ayelujara rẹ pe, “Ọlọrun to bi” ati “Ọlọrun ni asiko mi ko ti to.”

Ileeṣẹ iroyin Germany fi idi rẹ mulẹ pe Boniface jẹ ero ọkọ lasiko ti ijamba naa.

“Boniface wa ninu ọkọ to n lọ si paapa ofurufu Franfurt lẹyin ago meje, nibi to ti fẹ lọ pade ọrẹ rẹ nigba ti ọkọ Mercedes rẹ kọlu ọkọ nla kan.

“Boniface kọ lo wa ọkọ fun ara rẹ, o kan jẹ ero rẹ ni.

“Gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe gbe e sita, dirẹba ọkọ sọ ọwọ ọkọ nu, to si lọ kọlu ọkọ nla kan.

Nigba ti wọn bere lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Bayer Leverkusen, wọn ni, “Alaafia ni Boniface, o kan farapa diẹ ni ori rẹ. Dirẹba ọkọ ati Boniface n gba itọju ni ile iwosan , ti wọn si ti pada si Cologne.

Ninu awọn aworan ti Boniface kọkọ gbe sita, ni a ti ri ẹjẹ ni apa rẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu Leverkusen ni erongba pe yoo pada si ere bọọlu fun ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions nigba ti wọn ba koju Breast lọjọru.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post