Àṣeyọrí mélòó ni Makinde ti ṣe gẹ́gẹ́ bíì gómìnà kó tóó fẹ́ẹ́ di ààrẹ - APC

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo ti ṣapejuwe iroyin to n ja kiri pe Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo fẹ jade jupo gẹgẹ aarẹ ninu eto idibo to n bọ gẹgẹ bii agbedẹrọ ti ko ni ẹṣẹ ni ilẹ rara.

Wale Sadare, agbẹnusọ APC sọ fun BBC pe Gomina Seyi Makinde ko ti jade sọrọ sita pe oun fẹ dibo Aarẹ, ti awọn ko si ni ọrọ kankan lati sọ bayii.

“Gbogbo eyi to wa nilẹ ko ti jẹmọ iyẹn rara, a wa o ka iroyin naa kun nnkan to ni ẹsẹ nilẹ, nigba to ba to asiko, ti Gomina Seyi Makinde ba jade sọrọ, a o mọ iru esi ti a o fọ sugbọn bayii gomina ko ti sọrọ.

“A wa kun iroyin agbelẹrọ, eyi ti wọn n se lọwọ, aṣeyọri mẹlo ni awọn ti se, ti wọn yoo fi sọ pe awọn fẹ se aarẹ, ti wọn ba dẹ sọ pe awọn fẹ se aarẹ, o ni ẹtọ gẹgẹ bii ọmọ Naijiria.

“Nnkan to kan wa bayii ni aṣeyọri ijọba Aarẹ Bola Tinubu, ti ara yoo tu ọmọ Naijiria.”

Tí Makinde bá fẹ́ẹ́ di ààrẹ Naijiria, yóò bọ́ síta sọ̀rọ̀- Agbẹnusọ Gómìnà

O ti to ọjọ mẹta bayii ti ẹnu ti n kun Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde pe o seese ko ni erongba lati jade dupo Aarẹ tabi igbakeji aarẹ ninu eto idibo to n bọ lorilẹede Naijiria.

Ṣaaju ni awọn kan ti n gbe iroyin labẹlẹ pe Seyi Makinde sọ pe ko yẹ kí awọn enìyàn maa ṣaaju ṣe oju ṣaaju tabi maa hun ọrọ pọ nitori oun gboju gboya lati sọ nnkan ti oun ba n fẹ laì gba aṣẹ lọwọ ẹnikẹni.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ Gomina, Sulaiman Olanrewaju ni Gomina Seyi Makinde ki se ẹni ti o ma fi ọrọ si abẹ awọn sọ fun araalu.

Olanrewaju ni ti Makinde ba fẹ jẹ Aarẹ, yoo jade lati wa awọn eeyan sọrọ nipa erongba rẹ.

“Gomina ko nilo awọn gbọyi sọyi lati ba sọrọ pe o fẹ se nnkan. Sugbọn ko ti sọ eyi sita.

“Ohun ti Gomina gbaju mọ lọwọ ni lo da lori ipinlẹ Oyo, to si jẹ pe ohun lo gbaju mọ

“Awọn eeyan ipinlẹ Oyo ti dibo fun Gomina lati tukọ titi wọ 2027, iṣẹ yẹn ni Gomina gbajumọ bayii

“Iṣẹ ti wọn yan gomina fun, ni o n gbe jumọ.”

Olarenwaju ni ko si nnkan to jẹ pe Gomina Seyi Makinde n gbajumọ iṣẹ nitori o ni erongba lati di Aarẹ sugbọn o ni gomina n sisẹ ti wọn yan fun un gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Oyo.

“Nnkan ti wọn yan Gomina ni lati sisẹ fun ipinlẹ Oyo, oun si ni gomina n se lọwọ, ki se pe nitori aarẹ.

“Gomina fẹ mu awọn araalu kuro ninu isẹ ati osi.

“Isẹ ti awọn eeyan Gomina fun ni o n se lọwọ yii jẹjẹ bii gomina ipinlẹ Oyo.”