A kò rí ẹ̀rí kankan pé Bobrisky sun ibòmíì yàtọ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ìdájọ́ rẹ̀ – Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Igbimọ oluwadii ti minisita fun ọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo gba kalẹ lati ṣe ọfintoto boya lootọ ni Idris ‘Bobrisky’ Okuneye ko lo akoko to yẹ ko lo lọgba ẹwọn ti gbe esi iwadii rẹ jade.
Igbimọ naa, ti akọwe agba ọọfisi Tunji-Ojo, Magdalena Ajani, dari rẹ sọ pe oun ko ri ẹri kankan pe Bobrisky sun ibomii yatọ si inu ọgba ẹwọn lẹyin idajọ rẹ.
Abajade esi naa fi kun pe Bobrisky jẹ awọn anfani kan lasiko ahamọ rẹ ninu ọgba ẹwọn meji ti wọn gbe lọ.
Nigba to n ka abajade esi naa lọjọ Aje, ọkan lara awọn ọmọ igbimọ oluwadii ọhun, Uju Agomoh sọ pe ọdaran naa pari akoko to yẹ ko lo ninu ọgba ẹwọn, ko si fi akoko kankan sun ile miran.
O ni “Igbimọ yii ko ri ẹri kankan to fi han pe ọgbẹni Okuneye sun ibomii yatọ si ọgba ẹwọn lasiko to wa ni ahamọ rẹ to bẹrẹ lọjọ kejila, oṣu Kẹrin si ọjọ karun un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, eyii to jẹ oṣu mẹfa.
“Iwadii igbimọ naa tun fi han pe Ọgbẹni Okuneye Idris gbadun awọn anfani kan nigba to wa lọgba ẹwọn ti abo rẹ kere ati ọgba ẹwọn alaabo to pọ.”
Lara awọn anfani ti wọn ni Bobrisky jẹ ni inu yara ti awọn ohun meremere wa, abẹwo lati ọdọ awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ rẹ bo ṣe wu u.
Awọn anfani mi to tun jẹ ni “Jijẹ ounjẹ to ba fẹ, anfani lati ran awọn ẹlẹwọn mii niṣẹ, ẹrọ amounjẹ tutu, ẹrọ amohunmaworan, igbagbọ tun wa pe o lanfani lati maa lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ.”
Ọgba ẹwọn Kuje ni wọn kọkọ fi ọdaran naa si tẹlẹ ki wọn gbe lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri to wa ni Apapa nilluu Eko.
Ohun to ṣokunfa iwadii akoko Bobrisky lọgba ẹwọn
Iwadii bẹrẹ lati mọ boya lootọ ni Bobrisky lo akoko rẹ lọgba ẹwọn lẹyin ti ajafẹtọ ọmọniyan kan, Very Dark Man, VDM, sọ pe ile itura ni ọdaran naa ti lo akoko rẹ.
VDM fi ohun kan lede lori ayelujara, ninu eyii ti Bobrisky ti n ba ẹnikan sọrọ to si sọ pe oun ko si ninu ọgba ẹwọn, ati pe awọn oṣiṣẹ EFCC gba owo gọbọi lọwọ oun lati wọgile ọkan lara awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ohun naa fa ori ayelujara ya, ti ọpọ si bu ẹnu atẹ lu awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC to fi mọ oṣiṣẹ ileeṣẹ ọgba ẹwọn lori iwa ajẹbanu.
Lẹyinorẹyin, ile igbimọ aṣojuṣofin ke si ọga agba ajọ EFCC, ileeṣẹ ọgba ẹwọn, Bobrisky ati VDM lati wa sọ ohun ti wọn mọ nipa ọrọ naa.
VDM yọju si awọn aṣofin ọhun amọ Bobrisky kọ lati yọju.















