Kò sí àìsàn ibà lórílẹ̀èdè Egypt mọ́ – WHO

mosquito bites

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO, ti fontẹ lu orilẹede Egypt gẹgẹ bii ọkan lara orilẹede ti ko ni arun iba mọ lagbaye.

Ọga agba WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus, sọ pe “aisan iba ti pẹ laye gẹgẹ bi orilẹede Egypt funra rẹ amọ aisan naa to gbogun ti awọn Farao atijọ ti di ohun igbagbe.”

Nnkan bii ọgọrun ọdun sẹyin lawọn alaṣẹ ni Egypt bẹrẹ igbesẹ lati pa aisan naa run nilẹ wọn.

WHO maa n fun awọn orillẹede ni iwe aṣẹ pe aisan ti dopin nilẹ wọn ti wọn ba le fi ẹri han pe aisan naa ko ran ẹlomiran fun odidi ọdun mẹta gbako.

O kere tan, aisan iba maa n pa 600,000 eeyan lọdọun, ti nnkan bii adaji wọn si jẹ ọmọ ilẹ Afrika.

Ninu atẹjade kan ti WHO fi lede lọjọ Aiku, o gboriyin fun awọn eeyan ati ijọba Egypt fun akitiyan wọn lati fopin si aisan naa.

O ni Egypt ni orilẹede kẹta ti yoo gba iwe ẹri naa lagbegbe ila oorun Mediterranean lẹyin United Arab Emirates ati Morocco.

Kaakiri agbaye, orilẹede mẹrinlelogoji lo ti gba ontẹ naa.

WHO sọ fun Egypt pe ko ṣọra gidi ki aisan naa ma ba pada si orilẹede rẹ.

Ki orilẹede kan to le gba iwe ẹro yii lọwọ WHO, o gbọdọ fi ẹri lelẹ pe aisan naa ko le ran ẹnikẹni mọ.

Bo tilẹ jẹ wọn ti n lo abẹrẹ ajẹsara bayi lati dena aisan iba, WHO sọ pe jijina si ẹfọn ni ọna kan gboogi lati dena rẹ.