Ààrẹ Cameroon padà sí ilé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, CRTV
- Author, Paul Njie
- Role, BBC News, Yaoundé
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Aarẹ orilẹede Cameroon Paul Biya, ẹni ọdun mọkanlelaadọrun ti o ti pada si orilẹede naa, ti wọn si ri ni ita gbangba fun igba akọkọ laarin ọsẹ mẹfa.
Ọpọ lo ti n gbe iroyin pe o ṣeeṣe ko jẹ pe Aarẹ naa ti jade laye nitori ọjọ ori rẹ.
Sugbọn ni ọjọ Aje, ileeṣẹ momaworan kan fi fọnran bi aarẹ Biya se n balẹ si paapa ofurufu ni olu ilu orilẹede naa, Yaounde lati orilẹede Switzerland.
Ijọba Cameroon i fofin de awọn akọroyin pe wọn ko gbọdọ gbe iroyin nipa eto ilera Aarẹ Biaya lati ọdun 1982.
Ọpọ igba ni iroyin ti n lọ kiri nipa Aarẹ Biya pe o ti jade laye.
Fọnran ọjọ Aje yii ṣafihan Aarẹ Biya ni aṣọ suutu to n ma n wọ , ti ara rẹ si ji pepe.
Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an ni wọn ri Aarẹ Biya ni ita gbangba gbẹyin nigba to kopa ninu ipade China ati Afrika niluu Beijing.
Lati igba naa, ijọba ti ọpọ ti n gbe ogun ti pe ki wọn sọrọ nipa ipo aarẹ naa wa.
Ọpọ awọn amugbalẹgbẹ Biya ni wọn jẹ ko di mimọ pe alaafia ni Aarẹ Biya wa, to si rin irinajo lọ si ilu Geneva.
Nigba to balẹ, ọpọ awọn osisẹ ijọba lo lọ ki kaabọ ni paapa ofurufu.
Bi Biya se pada yii ni o seese ko fa ipe ninu ẹgbẹ oṣelu rẹ pe o fẹ lọ fun ṣaa ọdun meje mii.
Bo tilẹ jẹ pe Biya ko ti sọrọ boya yoo jade dupo sugbọn awọn ẹgbẹ alatako ni awọn ọna to n tọ ti fihan pe ko fi fẹ fi ipo naa silẹ.















