Wo Alàáfin 45 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀, ṣáajú Abimbola Owoade

Alaafin

Oríṣun àwòrán, omo lamurudu/asiri/facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ipo Alaafin tilu Oyo jẹ itẹ to lagbara nilẹ Yoruba, eyi to ni ọwọ gidigidi.

Laye atijọ, Alaafin lo ni ilẹ, lo ni oko, ti ọpọ ilu nla ati kekere si maa n san isakọlẹ fun.

Lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin ni awọn Alaafin ti maa n dari ilu Oyo, o si ti di Alaafin kẹrindinlaadọta ti yoo jẹ.

Alaafin kẹrindinlaadọta naa si ni Ọba Abimbola Akeem Owoade ẹni ti gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede rẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ Kẹtala, oṣu Kini, ọdun 2025 ni wọn si gbe ọpa aṣẹ fun Alaafin tuntun naa, Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade.

Iwọnyi si ni awọn Alaafin to ti jẹ ṣaaju Owoade gẹgẹ bi akọsilẹ se fi han wa.

Alaafin

Oríṣun àwòrán, Oyo state gvt

Alaafin Lamidi Olayiwola Adeyemi III

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ni Alaafin Lamidi Olayiwola Adeyemi III waja.

Ọdun mejilelaadọta lo lo lori itẹ.

Ṣugbọn, ko si bi ao ṣe sọ ọrọ Alaafin Adeyemi tabi itan ilu Oyo, ti a ko nii sọ ni pa awọn baba nla to pilẹ Oyo, to si jọba lati igba atijọ.

Oranmiyan 1210

Oranmiyan, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ Oduduwa, lo da ilu Oyo silẹ. Oun si ni ọba akọkọ to jẹ.

Ogboju jagunjagun ni.

Lasiko kan, o rinrinajo pada silu Ile-Ife, to si fi ọmọ rẹ ọkunrin, Ajaka, dele gẹgẹ bi ọba.

Ṣugbọn nigba ti ko tete pada wa, awọn afọbajẹ fi Ajaka jọba.

Itan sọ pe nigba ti Oranmiyan pada de, ìró kakaaki, feere ọba, to gbọ ni ẹnu ibode ilu, mu ko pada si Ile-Ife, nibi to ku si.

Ibi ti wọn sin oku rẹ si ni ọpa Oranmiyan wa titi di oni ni Ile-Ife.

Ajaka - 1242

Alaafin Ajaka jẹ eeyan jẹ́jẹ́, oniwa tutu. Itan sọ pe ko fẹran ogun jija rara, eyi to mu ki awọn ọba kan ni agbegbe rẹ kogun ja ilu Oyo.

Ilu pada rọ ọ loye, wọn si fi aburo rẹ ọkunrin, Sango jọba. Ajaka salọ si ilu Igboho, nibi to wa fun ọdun meje, ko to o pada silu Oyo lẹyin iku Sango.

Sango - 1252

Jagunjagun ati oninu fufu eniyan ni Sango, to si ni iwa pe ko ma a yọ ina lẹnu lasiko ti inu rẹ ba ru.

Eyi mu ki awọn araalu bẹru rẹ pupọ.

Ọdun meje ni Alafin Sango fi jọba. Ṣugbọn ọdun meje naa kun fun wahala ati ipayinkeke fun araalu Oyo, nitori ọwọ agbara to fi n dari wọn.

O mọ ewe ati egbo, o si ma n ṣe oogun pupọ, debi pe o n ranṣẹ pe àrá.

Nigba to ya, awọn afọbajẹ sọ fun pe ko fi ipo ọba silẹ, ṣugbọn dipo ko ṣe bẹẹ, Sango pokunso funra rẹ sori igi òrí kan.

Lẹyin iku rẹ ni wọn ranṣẹ pe ẹgbọn rẹ, Ajaka, pe ko pada sori itẹ.

Ajaka ni Alaafin kan ṣosọ to joye lẹẹmeji.

Aganju Sola 1277

Ọmọ Alaafin Ajaka ni aganju Sola. O si fẹran ko ma a mu awọn ẹranko igbo laaye. Itan ti ẹ sọ pe, o ni aaye amọtẹkun ninu aafin rẹ.

Lara awọn nkan ti itan sọ pe o sẹlẹ lasiko ijọba rẹ, ni bi ọmọ rẹ ọkunrin kan sẹ ni ibalopọ pẹlu iyawo rẹ. Pipa lo si pa ọmọ ọhun.

Kori - 1340

Ọmọ Alaafin Aganju, ni Kori. lasiko ijọba Alaafin Kori, ni wọn da ilu Ede ati Osogbo silẹ.

A ka ninu itan pe Kori, lo ran Timi lọ si Ede, lati ba awọn Ijẹsha ja. Lẹyin ija naa, ni Timi fi ara rẹ jọba ni Ede, eyi to mu ki oye ọba ilu Ede jẹ Timi.

Oba Kori ran Gbonka lati pa ba Timi ja, o si bori rẹ.

Nitori ki Gbonka naa ma ba a sọ ara rẹ di alagbara, Oba Kori gbiyanju lati pa a, ṣugbọn igbesẹ rẹ ja si ofo, eyi to mu ko pa ara rẹ.

Awọn miran to jẹ lyin Kori ni Oluaso (1401AD), Onigbogi (1490 - 1542), Ofinran (1542 ), Eguguojo (1550 ).

Orompoto - 1554 - 1562

Alaafin Orompoto ni obinrin kan ṣoṣo to jẹ alaafin ilu Oyo. Aburo lo jẹ fun Alaafin Eguguojo, ṣugbọn o di Alaafin nitori pe ko si ọmọ ọba to jẹ ọkunrin, lati jẹ ọba.

Itan ti ẹ sọ pe o ge ọmu rẹ mejeeji, to si ma n wọ aṣọ ọkunrin, ki awọn afọbajẹ, Oyomesi, le tẹwọ gba a.

Ogboju jagunjagun ni Orompoto, to si ṣẹgun ni ọpọ ogun ti wọn gbe ti ilu Oyo. Oju ogun Ilayi lo ku si ni ọdun 1562.

Awọn Alaafin miran to tun jẹ ni igba iwasẹ ni:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaafin Ajiboyede - 1562-1570

Abipa - 1570 - 1588

Obalokun - 1588 - 1599

Ajagbo - 1599 - 1659

Odarawu - 1658 - 1659

Alaafin Karan - 1659 - 1665

Alaafin Jayin - 1665 - 1676

Alaafin Ayibi - 1676 - 1690

Alaafin Osiyago - 1690 - 1692

Alaafin Ojigi - 1728 - 1732

Alaafin Gberu - 1732 - 1738

Alaafin Amuniwaye - 1738 - 1742

Alaafin Onisile - 1742 - 1750

Alaafin Labisi - 1750 (Oun ni Alaafin to lo ọjọ to kere ju lori itẹ. Ọjọ mẹẹdogun pere lo lo.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe pa ara rẹ. Lootọ ni wọn yan ni ọba, ṣugbọn ko de ade, nitori bi Basorun Gaa, ijoye, to lo ọwọ agbara.

Ironu lo mu ki Labisi pa ara rẹ.

Alaafin Awonbioju - 1750 (Aadoje ọjọ pere ni oun naa lo lori itẹ. Basorun Gaa to fi jọba, lẹyin Labisi, naa lo ṣekupa a, nitori pe o kọ lati dọbalẹ fun).

Alaafin Agboluaje - 1750 - 1770

Alaafin Majeogbe - 1770 - 1772

Alaafin Abiodun - 1772 - 1796 (Oun lo pada ṣẹgun Basorun Gaa ati awọn ọmọ rẹ to ti sọ ara wọn di ẹrujẹjẹ si gbogbo awọn alaafin to jẹ ṣaaju rẹ.

Ṣugbọn, ọmọ rẹ ọkunrin, Aole, lo pa a pẹlu majele. O si jọba ni ipo rẹ.

Alaafrin Aole Arogangan - 1789 - 1796

Alaafin Adebo - 1796 - 1797

Alaafin Makua - 1797

Alaafin Majeotu - 1801 - 1830

Alaafin Amodo - 1830 - 1833

Alaafin Oluewu - 1833 - 1835 (Labẹ iṣakoso rẹ ni awọn Fulani ṣẹgun Oyo igba iwasẹ, ti wọn si tu ilu naa ka)

Oyo Tuntun

Alaafin Atiba Olukuewu, to jẹ ọmọ Alaafin Abiodun Adegoolu, lo pada ko ilu Oyo tuntun jọ, ni Agọ-Ọja, to pada di ilu Oyo bayii.

O jọba laarin ọdun 1837 si 1859.

Awọn Alaafin to jẹ lẹyin rẹ ni

Alaafin Adelu (1859 - 1875)

Alaafin Adeyemi I (1876 - 1905)

Alaafin Lawani (1905 - 1911)

Alaafin Siyanbola Ọladigbolu I (1911 - 1944)

Alaafin Adeniran Adeyemi II (1945 - 1956)

Alaafin bello Gbadegesin Oladigbolu II (1956 - 1968)

Alaafin Lamidi Olayiwola adeyemi III (1971 - 2022)