Láyé àtijọ́, Èṣù ni wọ́n máà ń pe ìlu Àgídìgbo, kò sí ibi tí wọn ti lù ú, tí ìjà kìí bẹ́ sílẹ̀ - Onílù Àgídìgbo

Àkọlé fídíò, Láyé àtijọ́, Èṣù ni wọ́n máà ń pe ìlu Àgídìgbo, kò sí ibi tí wọn ti lù ú, tí ìjà kìí bẹ́ sílẹ̀ - Onílù Àgídìgbo
Láyé àtijọ́, Èṣù ni wọ́n máà ń pe ìlu Àgídìgbo, kò sí ibi tí wọn ti lù ú, tí ìjà kìí bẹ́ sílẹ̀ - Onílù Àgídìgbo

Yoruba ni bi owe, bi owe la n lu ilu Agidigbo, Ọlọgbọn lo n jo, ọmọran lo n mọ ọ.

Ilu Agidigbo kii se ilu to wọpọ mọ lode oni, o si loju eeyan to da mọ.

Iyalẹnu si lo jẹ nigba ti BBC Yoruba se alabapade baba kan, Raphel Atoyebi, ẹni to n lu ilu Agidigbo.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa ilu naa, Atoyebi ni ilu Agidigbo lagbara pupọ.

"Ni aye atijọ, esu ni wọn maa n pe ilu Agidigbo nitori ko si ibi ti wn ti lu u, ti wn ko ti ni ja tuka.

Ẹmu ti wọn n mu nigba naa lo maa n fa a, ti wn se maa n ja tuka.

Bi a se n lu ilu Agidigbo nigba yẹn, o yatọ si bi mo se n lu bayii nitori mo ti n lu fun Ọlọrun."

Baba Raphel Atoyebi

Bakan naa, Baba Atoyebi salaye bo se bẹrẹ si ni lu ilu Agidigbo ati awọn to kọ nisẹ ilu lilu.

"Mo bẹrẹ si ni lu ilu yii nigba ti mo wa nile, awọn ẹgbọn mi si lo kọ mi bi a se n lu ilu naa.

A maa n fi Agidigbo yẹ iyawo si, mo si ti n lu lati gbe Ọlọrun ga.

A maa n lu fun ti aye nigba naa, amọ mo n lu ninu sọọsi bayii.

Oju ko ti mi lati lu Ilu Agidigbo, inu sọọsi ni mo ti n lu."