Wọ́n gé ẹsẹ̀ ọ̀tún mi lójú ogun, mo ja ogun náà parí àmọ́ ìjọba kò san owó àjẹmọ́nú wa lójú ogun lẹ́yìn àádọ́ta ọdún – Ajagunfẹ̀yìntì

Nasiru Salami

Oríṣun àwòrán, Channels

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajagunfẹyinti kan, to tun kopa ninu ogun abẹle Naijiria, Nasiru Salami, ti ṣalaye bi iya ṣe n jẹ awọn ajagunfẹyinti ni Naijiria.

Baba ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin naa sọ pe oun ko ni gba ki ọmọ oun kankan drapọ ileesẹ ọmọ ogun Naijiria lailai.

Ọrọ naa lo jẹyọ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels ni iranti ayẹyẹ ayajọ awọn ologun ni Naijiria.

Baba agba naa ṣalaye bo ṣe darapọ mọ ileeṣẹ ologun lọdun 1967, ti wọn si ran lọ soju ogun lẹyin idanilẹkọo ọsẹ mẹfa pere.

"Wọn ge ẹsẹ mi ọtun loju ogun, mo si tun pada soju ogun lati jagun"

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Salami sọ pe oṣu mọkanla gbako loun lo loju ogun Biafra laarin ọdun 1967 si ọdun 1970.

O tun ṣalaye bo ṣe padanu ẹsẹ rẹ ọtun loju ogun naa, eyii to mu ki wọn ge ẹsẹ naa, to si tun pada soju ogun lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

O ni "Lọwọ yii o, mi o le gba ki eyikeyi ninu awọn ọmọ mi darapọ mọ ileeṣẹ ologun Naijiria.

"Emi ni baba wọn, wọn si n wo mi bayi bi aye mi ṣe ri, eyii ti kii ṣe bi wọn ṣe lero.

"Wọn maa fẹ ki n ju bi mo ṣe wa yii lọ ki n si kun fun ayọ atawọn nnkan mii ti yoo mu inu wọn dun.

Bawo ni mo ṣe le mu ori wọn wọn wu lati darapọ ileeṣẹ ologun pẹlu bi aye mi ṣe ri yii.

"Ijọba ko tii san owo ajẹmọnu ogun ti a ja lati aadọta ọdun o le diẹ sẹyin"

Salami tẹsiwaju pe "Meji ninu awọn ọmọ mi lo ti kẹkọọ jade ni fasiti, mo ti sọ fun wọn pe; ẹ maṣe ronu pe ẹ maa darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun.

Ti ẹ ba fẹ darapọ mọ wọn, ẹ darapọ awọn ọmọ ogun ofurufu tabi ọmọ ogun ori omi, mi o ṣiṣẹ pẹlu wọn ri o.

Amọ mo maa n ri wọn, mo si n gbọ pe wọn ṣetọju wọn daadaa."

Ọkunrin ọhun, to jẹ akọwe ẹgbẹ awọn ajagunfẹyinti Nigerian Legion, nipinlẹ Eko ni eeyan to le ni 24,000 lo wa ninu ẹgbẹ ọhun, ti ijọba apapọ ko si tii san owo ajẹmọnu ogun ti wọn ja lati aadọta ọdun o le fun wọn.

O tun mẹnuba awọn owo ifẹyinti rẹ, atawọn owo mii to yẹ ki ijọba ti san fun amọ ti ko san.

Salami pari ọrọ rẹ pe ọdun 1983 loun fẹyinti lẹnu iṣẹ, ijọba si ṣe ọpọ ileri fun oun eyi to kọ lati muṣẹ lati ọdun naa titi di oni yii.

Lẹyin naa lo rọ ijọba ko san owo to jẹ awọn ajagunfẹyinti, paapaa ajẹmọnu awọn to kopa ninu ogun abẹle ọdun 1966.