Portable lọ fi ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò wẹ̀ lódò, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Instagram/Portablebaby
Ọrọ Habeeb Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable, lo tun ti se ohun iyalẹnu lori ayelujara eyi to mu ki ariwo tun gba ilẹ kan.
Portable, ninu fọnran fidio to gbe soju opo ikanni Instagram rẹ, lo ṣafihan bi o ṣe n fi ohun mimu ẹlẹrindodo olomi ọsan wẹ ninu odo kan.
N se ni Portable da omi ọti ẹlẹrindodo naa si ori, to si tun da sinu lodo naa.
Ọpọ awọn eeyan loju opo ayelujara lo kọminu si ohun ti Portable n se , ti awọn kan si n gbe lẹyin rẹ pe o n bọ odo ni.
@mr_t_events ni "O da mi loju pe ti wọn ba mi ki Portable lọ wẹ laarin ọja tabi nibi ti awọn eeyan pọ si, yoo lọ si ibẹ.
@adefitness042 ni "Idi ti ogo Portable ko le fi walẹ ree ṣugbọn eeyan ko mọ pe ohun to n gbe orin rẹ rin to n fi n pade awọn olorin nla bii Skepta.
@runny_kay ni Ọmọ ọgbọn, ki ẹ to gbe sita, o ti gbe ara rẹ sita
Bi ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu yii ni Portable wọ sokoto kannaa pẹlu awọn ibadan lẹyin to sọ pe wọn ko ni POP ni ile niluu Ibadan.
Awọn alakoso eto ariya ita gbangba ti gbajugbaja akọrin Fuji , Taye Currency gbe kalẹ niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo ṣalaye idi pataki ti akọrin takasufee Portable ko ṣe kọrin nibi ariya naa lẹyin ti wọn ransẹ pe ko wa kọrin saaju.
Ileeṣẹ naa ti wọn pe ni Jarule Entertainment sọ pe aabo ẹmi ati dukia awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ Taye Cureency ṣe pataki pupọ, idi ree ti wọn ko fi gba Portable laaye lati kọrin nibi eto naa.
Wọn ni awọn kan to n binu si Portable, to tun n pe ara rẹ ni Were Olorin ni wọn fẹ lo anfaani eto ariya naa lati fiya jẹ Portable, to si ṣe e ṣe ki wahala ti wọn ko lero ṣẹlẹ.
Ṣaaju asiko yii ni Portable ti sọrọ jade sita wi pe Taye Currency ti fi owo ranṣẹ si oun lati wa kọrin niluu Ibadan, to si bẹbẹ pe ki awọn ara ilu Ibadan forijin oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















