Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ọmọ Ọba mẹsan-an lo ti jade bayii lati tako iyansipo Alaafin Oyo tuntun, Ọba Abimbola Owoade
Ọmọọba Sina Afolabi ti idile Adeitan, lo fi atẹjade kan sita lorukọ awọn idile mẹsan-an ọhun nipa ọrọ ọhun
Awọn ọmọ Ọba naa ti a mọ si 'Atiba mẹsan-an', ṣapejuwe iyansipo Owoade bii ohun to tabuku aṣa iṣembaye ilẹ Oyo
Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
Mi o kabamọ pe mo ge ori ori ọrẹbinrin mi, o si ni idi ti mo fi pa a
Akọrin ẹmi, Timileyin Ajayi ti ọwọ ọlọpaa tẹ lori iku ọrẹbinrin rẹ l'Abuja lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin
O ni oju oloogbe naa ko gbebikan, bẹẹ lo n fẹ ẹlomiran pẹlu oun, loun ṣe gbẹmi rẹ
Awọn ẹbi oloogbe naa ti bere fun idajọ ododo
Ni South Korea
Awọn agonfinro ti fi panpẹ ofin mu Aarẹ Yoon Suk Yeol nile rẹ
Lẹyin ti wọn fẹsun aṣilo ipo kan an
Ilẹ aṣofin ilẹ naa ti dibo lati yọ nipo, wọn si ti ni ko lọ rọọku nile
Nnkan bii ẹgbẹrun kan agbofinro lo gun ile rẹ lati fi ofin mu