Ìdí tí ètò ìbúrawọlé Donald Trump kò fi ní wáyé ní ìta gbangba

Aworan Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ninu ile ni eto iburawọle fun Donald Trump gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Amẹrika yoo ti waye lọjọ Aje, ogunjọ oṣu Kinni ọdun yii.

Trump funra rẹ lo sọ pe nitori otutu lile tawọn onimọ nipa oju ọjọ ti sọ pe yoo mu lọjọ naa ni eto ọhun ko sẹ ni waye ni ita gbangba.

Ninu ileeṣẹ ijọba Amẹrika, Capitol rotunda, ni Trump yoo ti sọrọ apilẹkọ rẹ lasiko ayẹyẹ naa.

Koda, ninu ile ni eto yiayan bi ologun fun aarẹ naa yoo ti waye ni gbagede Capital One Arena niluu Washington.

Aarẹ orilẹede Amẹrika ti wọn ṣe iburawọle fun kẹyin ni Aarẹ Ronald Regan nitori otutu lile to mu ni ileeṣẹ ijọba Capitol lasiko naa lọdun 1985.

Trump ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe oun ko fẹ ki oju ọjọ ti ko dara ṣakoba fun ẹnikẹni to ba wa nibi eto iburawọle ijọba oun.

''Oju ọjọ yoo tutu to iwọn -11c lọjọ iburawọle Trump''

Aarẹ ti Amẹrika ṣẹṣẹ dibo yan sọ pe otutu lile yii lewu fun ẹgbẹẹgbẹrun ololufẹ oun, ati fawọn agbofinro to fi mawọn ẹṣin ti yoo wa nibi eto naa.

Awọn onimọ nipa oju ọjọ ti sọ pe oju ọjọ yoo tutu de iwọn -11c lọjọ iburawọle aarẹ tuntun Amẹrika.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe iji yoo tun maa fẹ yatọ si otutu lile ti yoo gbode kan lọjọ naa.

Trump ni gbogbo eeyan ni yoo wa lai lewu ti inu wọn yoo si dun pẹlu igbesẹ toun gbe yii.

Ṣaaju eto iburawọle yii, awọn to n ṣagbatẹru eto naa ti sọ pe awọn yoo pin tikẹẹti 220,000 ati wọle si gbagede ileeṣẹ ijọba Capitol lati wo aworan bi eto naa yoo ṣe lọ.

Ọkan lara awọn to n ṣagbatẹru eto naa sọ fun BBC pe awọn eeyan ni lati wọ aṣọ to dara fun eto naa ati aṣọ to ba bi oju ọjọ yoo ṣe ru mu wa si ibi eto naa.

Bi eto iburawọle naa yoo ṣe waye ninu ile tumọ si pe awọn ti yoo wa nibi eto naa ko ni pọ.

Ti ẹ o ba gbagbe, miliọnu kan ati abọ eeyan lo wa nibi eto iburawọle Trump nigba to kọkọ wọle ibo aarẹ orilẹede Amẹrika.