Ìdí tí mo fi súre fún Portable rèé, kìí ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò - Olori Dami

Oríṣun àwòrán, Officialqueen_dami/Instagram
Awuyewuye lori ọrọ to n lọ laarin gbajumọ akọrin takasufe n ni, Habeeb Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable ati ọrẹbinrin rẹ, Olori Damilola, ko tii tan nlẹ lẹyin ti Dami tun gbe fidio kan jade eyi to fi ṣalaye idi to fi sure fun akọrin naa ninu fọnran kan to lu ori ayelujara pa.
Ṣaaju ni fọnran kan ti kọkọ lu ori ayelujara pa eyi to ṣafihan bi Dami ti n ṣe adura fun Portable, ti wọn si jọ n sọrọ lori ati pada Dami sọdọ Portable.
Ọpọ eeyan lori ayelujara lo koro oju si Dami pe o n gbero lati pada sọdọ Portable lẹyin gbogbo nnkan to ti ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji siwaju.
Amọ, Dami ṣalaye bi ọrọ naa sẹ jẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Mandy to jẹ alẹnulọrọ lori itakun ayelujara Instagram.
Dami sọ pe oun ko figba kankan gbero lati pada sọdọ Portable, o ni Portable lo funra rẹ sọ foun pe toun ko ba sure foun, ọna ko le la pada.
''Portable ni ṣe mo ri fidio kan to ṣafihan bi oun ṣe lọ wẹ lodo pẹlu ọti ẹlẹrindodo.
O ni wọn ti sọ foun pe oun nilo ire lati ẹnu Dami ki nnkan to le dara foun pada.
Portable tun sọ pe wọn tun foun lọjọ mẹta lati gba mi pada, ṣugbọn mo sọ fun un wi pe ko le ṣee ṣe.
Awọn ẹbi mi tun sọ fun Portable wi pe o gbọdọ wa ṣe ojuṣe rẹ ki n to le pada sọdọ rẹ, oun naa si gba bẹẹ.''
Dami sọ ninu fidio to wa lori Instagram naa wi pe oun kilọ fun Portable wi pe ko gbọdọ gbe fidio adura toun ba ṣe fun un sori ayelujara, amọ, o ni ko gbọ.
Adura ti mo ṣe fun Portable ko le adabi... – Dami
Olori Alaafin tẹlẹ ti wa sọ pe adura toun ṣe fun Portable ko le gba, adabi to ba jẹ pe ko sọ foun pe adura lati ẹnu oun lo le jẹ ki nnkan yi pada si rere foun loku.
Dami fikun ọrọ rẹ pe Portable ni oun ti fẹ maa ni aarun ọpọlọ diẹdiẹ pẹlu bi nnkan ṣe ri foun bayii.
''Portable ni lati igba ti mo ti lọ laye oun ti dojuru ti ko si ogo foun mọ.
Portable fẹ wa lo mi lati yanju gbogbo wahala to n fa pẹlu awọn ara Ibadan.''
Dami ni Portable fẹ fi oun gbayi lo jẹ ko gbe ọrọ tawọn jọ sọ jade lori ayelujara, ati wi pe ko gbe awọn ọrọ tawọn ti jọ sọ ṣaaju lati ibi tọrọ ti bẹrẹ jade.
Dami ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe oun o le pada sọdọ Portable tori o tumọ si pe oun pada sibi eebi oun ni.
O ni adura toun ṣe fun Portable ko ni itumọ tori ṣiṣe ti ba akọrin naa.
Dami Portable lo fenu ara rẹ sọ pe iya oun ti bẹrẹ si ba oun ja tori o gbọ pe oun fẹ pada eleyii ti ko si ri bẹ.
Olori Dami wa kepe Portable lati gbe gbogbo ọrọ tawọn mejeeji jọ sọ sori ayelujara lai ṣe ọkankan ku.
Ki lo sẹlẹ saaju laarin Portable ati Olori Damilola?
Ni Ọjọbọ, ọjọ Kejila, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni fidio kan gba ori ayelujara nibi ti gbajumọ akọrin takasufee ni, Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable ti n fẹsun kan ọrẹbinrin rẹ, Olori Dami.
Ninu fidio naa ni Portable ti n sọrọ lori bi oun ati Olori ṣe pade ati awọn nnkan to ṣe fun nigba ti wọn wa papọ.
O fẹsun kan olori Dami pe o kọ kuro ninu ile tí oun gba fun ní Ibadan, to si tun ko ọja kuro ní ṣọọbu tí oun gba fun.
O ṣalaye pe owo nọbì ni oun fi pade olorì Dami tawọn sì pinnu lati tẹsiwaju ninu ìrìnajo ìfẹ wọn.
Nigba to n fesi, Dami ninu fidio kan to ṣe lori ayelujara ni, tori pe ọdọọdun ni awọn obìnrin maa n loyun fun Portable ni oun ṣe kọ lati loyun fun-un.
O ni oun ko fẹ darapọ mọ ọpọ awọn obìnrin to n bimọ fun Portable ni oun ṣe kọ lati loyun fun-un, fun ọdun meji ti awọn fi wa papọ.
O ni irọ ni pe oyun jabọ lara oun ni ìgba mẹrin gẹgẹ bi Portable ṣe sọ ninu fidio rẹ.
Dami, nigba to n sọrọ nípa bi oun ati Portable ṣe pade, ní Portable lo kọkọ ba oun sọrọ lorí ayelujára tawọn fi bẹrẹ ere ìfẹ awọn.
O ṣalaye pe nitori Portable dunkoko mọ oun lati lo oun ni oun ṣe sa asala fun ẹmi ara oun torí oun ko fẹ ki awọn obí oun foju sunkun oun lasìko yii.















