Kí ló tún ṣẹlẹ̀ láàrin Portable àti Dammy, tí Olorì fi dèrò ilé ìwòsàn?

Aowran Portable ati Olori Dami

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Se ni ariwo tun gbalẹ kan lori ayelujara nipa isẹlẹ miran to waye laarin gbajumọ akọrin takansufe nni, Habeeb Okikiola, ti ọpọ eeyan mọ si Portable ati ọrẹbinrin rẹ, Olori Damilola.

Bẹẹ ba gbagbe, o to bii osu meji sẹyin ti ariwo sọ laarin awọn ololufẹ mejeeji naa nigba ti Portable figbe bọnu pe Dammy ti kuro ninu ile ti oun gba fun, tawọn mejeeji si sọ oko ọrọ sira wọn lori ayelujara.

Sugbọn iyalẹnu nla lo wa jẹ pe ariwo miran tun sọ ni irọlẹ ana lori ayelujara pẹlu fidio kan to gbalẹ kan.

Fidio naa lo n se afihan Damilola ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji, ti wọn si n pariwo pe Dammy ti daku.

Ọpọ iroyin to n lọ lori ayelujara si lo n salaye pe Dammy gbe oogun jẹ ni nitori akọtun isẹlẹ to waye laarin ọrẹkunrin rẹ, Portable.

Ki ni Portable se fun Damilola to sọ Damilola dero ile iwosan?

Gẹgẹ bi a se ri gbọ, Damilola ati Portable ni wọn n gbinyanju lati pada maa sere ifẹ lọ lẹyin ti wọn ti ja ajatuka lori ayelujara.

Fọnran akasilẹ ohun kan si ni awọn kan n pin kiri lori ayelujara, eyi ti wọn ni Portable ka silẹ, to si jẹ itakurọsọ laarin oun ati Olori Damilola.

Ninu fọnran ohun naa ni Damilola ti n se adura lakọlakọ fun Portable pe ọla rẹ yoo maa lọ siwaju.

Akasilẹ ohun ori foonu naa fihan pe Damilola ati Portable ti n pada sọrọ bii ololufẹ, ti wọn si fẹ pari ija laarin ara wọn.

Ohun ipe naa ni "A nilo lati fun awọn eeyan lọrọ sọ, ohun to yẹ ki a se lati se bayii, tọkarẹ ntọkan ni mo fi n gbadura fun ẹ."

Eyi ni ohun ti Portable kọkọ gbe sita lati fi di rẹ mulẹ pe Olori Damilola ti pada si ọdọ gẹgẹ bii ololufẹ.

Ninu fọnran naa ni Olori Damilola ti sọ fun pe ọrẹ kan n gbe ọrọ sita lori ayelujara nipa rẹ pe o ti ba ọkunrin mii lopọ nigba to kuro ni ile Portable.

"Omọ yii ni mo n fun lesi, nitori pe o ti gbọ pe emi ati ẹyin fẹ pada, o lọ n gbe igbekugbe si oju ayelujara rẹ.

"Hmmm, ẹru n ba mi, ṣugbọn se o ro pe nnkan le pada sipo laarin wa, ko ye mi mọ o."

Nigba ti wọn fọrọjumitoro ọrọ ni Portable bi Olori Damilola pe se o ti ba ọkunrin mii lopọ lẹyin to kuro ni ile oun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Olori Damilola fun lesi pe, oun se nnkan to jọmọ bẹẹ, ti ohun si setan lati fi ohunkohun bura.

"Ọmọ yii kan n ba mi jẹ nitori pe o gbọ pe mo ti pada ni."

Portable bi pe se o le lọ soju opo ayelujara, ko si se fọnran lati bura pe oun ko ba ọkunrin mi sun lẹyin to kuro ni ile rẹ.

"Mi o le pada si oju opo ayelujara lati lọ sọ ohunkohun mọ, yoo dara pe ki o gba mi gbọ pe n ko ba ọkunrin mii sun.

"Ọmọ yẹn ko fẹ ki n pada si ọdọ yin lo n se n se ibajẹ mi kiri, ko le sọ ọrọ lati ọjọ yii, o se jẹ pe oni ti mo pada si ọdọ yin, lo gbe ọrọ yii sita, ko fẹ ki n pada ni, to ba da loju, ko mu ẹri sita"

Tomije loju ni Olori Damilola se n ba Portable ololufẹ rẹ sọrọ pe ko gbagbọ ninu oun ṣugbọn Ọmọ Olalomi kọ lati gba gbogbo ohun ti Olori Damilola sọ gbọ, to si gbe gbogbo ọrọ naa sita.

Olori Damilola ni ti awọn akọroyin ba fi le gbe ohun ti Portable sọ si oju opo ayelujara, ohun ko ni pada si ile Portable mọ.

"Portable, ma pe mi mọ, jẹ ki n wa bayii, o ti fi mi sẹsin."

Lẹyin isẹlẹ naa ni awọn ọrẹ Damilola gbe digba-digba sinu mọto, ti wọn n pariwo pe o ti daku, tawọn eeyan miran si ni o gbe nnkan jẹ ni.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

"Wọn ti ya ọmọ yin, mo dẹ ti ya danu"

Lẹyin gbogbo rogbodiyan naa ni Portable kede pe o ti tan laarin oun ati Olori Damilola.

"Ti ọkunrin mii ba ba iyawo Ifa sun, o di gbere niyẹn nitori ohun to n ba oogun jẹ niyẹn.

"Pada si bo? Mo kan beere lọwọ rẹ pe se wọn ti ya ẹ tabi wọn ko ti ya ẹ, o wa dakun, ki lo de to fi dakun.

"Iwọ kọ lo ni o fẹ fẹran mi pada,"

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Ki lo sẹlẹ saaju laarin Portable ati Olori Damilola?

Ni Ọjọbọ, ọjọ Kejila, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni fidio kan gba ori ayelujara nibi ti gbajumọ akọrin takasufee ni, Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable ti n fẹsun kan ọrẹbinrin rẹ, Olori Dami.

Ninu fidio naa ni Portable ti n sọrọ lori bi oun ati Olori ṣe pade ati awọn nnkan to ṣe fun nigba ti wọn wa papọ.

O fẹsun kan olori Dami pe o kọ kuro ninu ile tí oun gba fun ní Ibadan, to si tun ko ọja kuro ní ṣọọbu tí oun gba fun.

O ṣalaye pe owo nọbì ni oun fi pade olorì Dami tawọn sì pinnu lati tẹsiwaju ninu ìrìnajo ìfẹ wọn.

Nigba to n fesi, Dami ninu fidio kan to ṣe lori ayelujara ni, tori pe ọdọọdun ni awọn obìnrin maa n loyun fun Portable ni oun ṣe kọ lati loyun fun-un.

O ni oun ko fẹ darapọ mọ ọpọ awọn obìnrin to n bimọ fun Portable ni oun ṣe kọ lati loyun fun-un, fun ọdun meji ti awọn fi wa papọ.

O ni irọ ni pe oyun jabọ lara oun ni ìgba mẹrin gẹgẹ bi Portable ṣe sọ ninu fidio rẹ.

Dami, nigba to n sọrọ nípa bi oun ati Portable ṣe pade, ní Portable lo kọkọ ba oun sọrọ lorí ayelujára tawọn fi bẹrẹ ere ìfẹ awọn.

O ṣalaye pe nitori Portable dunkoko mọ oun lati lo oun ni oun ṣe sa asala fun ẹmi ara oun torí oun ko fẹ ki awọn obí oun foju sunkun oun lasìko yii.