PDP yọwọ́ nínú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní Ondo

Àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìdìbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ondo ti kéde pé àwọn kò ní kópa mọ́ nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdílógún, oṣù Kìíní ọdún 2025 ni àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò lábẹ́nú ní ìpínlẹ̀ Ondo, Ondo State Independent Electoral Commission, ODIEC mú fún ètò ìdìbò láti fi yan àwọn alága àti káhúnsílọ̀ sáwọn ìjọba ìbílẹ̀.

Kò dín ní ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́wàá tí ìrètí wà pé wọ́n máa kópa níbi ètò ìdìbò náà.

Adelé alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Ondo, Bakita Bello ló kéde ìpinnu ẹgbẹ́ náà lọjọ́bọ̀ pé àwọn kò ní kópa nínú ètò ìdìbò náà.

A ò ní ìgboyà pé ODIEC le ṣètò ìbò tí kò ní èèrú nínú - PDP

Bello, tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Akure ní PDP kò ní ìgboyà nínú àjọ ODIEC láti ṣètò ìdìbò tí kò ní ẹja n bákàn nínú.

Ó ní àwọn ti kọ̀wé sí ODIEC láti fi ìpinnu àwọn hàn lórí ìgbésẹ̀ náà.

Ṣáájú agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ìpínlẹ̀ Ondo, Leye Igbabo nínú àtẹ̀jáde kan sọ pé ODIEC kò ṣe é fi ọkàn tán láti ṣètò ìdìbò tí yóò lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.

Igbabo ṣàlàyé gbogbo àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ẹgbẹ́ àtàwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ àwọn ni ọ̀rọ̀ fi ọ̀rọ̀ náà tó létí kí àwọn tó pinnu láti yọwọ́ kúrò nínú ètò ìdìbò náà.

Ó ní àwọn ti ṣáájú fa àwọn olùdíjé mẹ́ẹ̀dógún sílẹ̀ fún ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà àtàwọn olùdíje 131 sípò káhúnsílọ̀ káwọn tó pinnu pé àwọn kò ní kópa nínú rẹ̀ mọ́.

Ó sọ pé gbogbo àwọn nǹkan táwọn ń rí àti èyí tí àwọn ń gbọ́ nípa ODIEC jẹ́ kó hàn sáwọn pé ODIEC kò lè ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ náà láì ṣe èrú.

Àmọ́ alága ODIEC, Joseph Aremo ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn pé PDP ní àwọn kò ní kópa níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.

Aremo ní gbogbo ìgbésẹ̀ táwọn ti ń gbé láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ ètò ìdìbò náà ti bẹ̀rẹ̀ ni àwọn jọ ń ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Ó sọ pé gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtà àpérò tí ODIEC ti ṣe lórí ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́ja àbámẹ́ta náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti kópa níbẹ̀.

Ó fi kun pé ṣáájú ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP ti ń gbóríyìn fáwọn lórí bí àwọn ṣe ń ṣe gbogbo ètò náà àti pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé wọ́n yí ìpinnu wọn padà lójijì.

Kò ní sí lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ lásìkò ìbò - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Ẹ̀wẹ̀,iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo ti fòfin de lílọ bíbọ̀ ní ìpínlẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kìíní ọdún 2025.

Èyí ló ń wáyé látàrí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ náà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmilayo Odunlami fi léde lórúkọ Kọmíṣánnà ìpínlẹ̀ náà, Wilfred Afolabi kò ní sí ààyé fún lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ àti ọ̀kadà lááàrín aago mẹ́fà àárọ̀ títí di aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.

Odunlami nínú àtẹ̀jáde náà ní àwọn arìnrìnàjò tó bá fẹ́ gba ìpínlẹ̀ náà kọjá nílò láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò ìrìn kó tó di ọjọ́ náà.

Ẹ̀wẹ̀, ààyè wà fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò, àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera, àwọn akọ̀ròyìn àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ tó ṣe kókó láti rìn ní ti wọn.

Ó rọ gbogbo àwọn èèyàn tí yóò lọ dìbò láti tẹ̀lé òfin, kí wọ́n sì ṣe àrídájú rẹ̀ pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.

Ó fi kun pé ìpèsè ààbò ti wà ní sẹpẹ́ láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.