Àdó olóró Israel tún pa ogún èèyàn ní Gaza lẹ́yìn àdéhùn ìdáwọ́ ogun dúró

O le ni ogun eeyan to tun padanu ẹmi wọn lalẹ ana, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii ni Gaza, lẹyin ti wọn lawọn ti dawọ ogun duro.
Gẹgẹ bi ikede to wa lati ọdọ ẹgbẹ kan to n pese aabo fun Hamas ṣe kede, mejila ninu awọn to ku lo n gbe lagbegbe Sheikh Radwan, ni Gaza.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ikọ ologun Israeli ko ti i sọ nnkan kan nipa rẹ.
Ohun to daju ni pe bi wọn ṣe kede tẹlẹ pe awọn ti jẹ ki ogun sinmi, ikọ Isreael ko ti i fi ọwọ si i.
Ikọ ologun Israel ti fi awọn ado oloro kan lelẹ, ki wọn to kede pe wọn yoo dawọ ogun duro
Bi wọn ba si fọwọ si i pẹlu, ko ni i fẹsẹ mulẹ bi ko ba di ọjọ Aiku.
Tẹ o ba gbagbe, ikọ ologun Israel ti fi awọn ado oloro kan lelẹ, ki wọn too kede pe wọn yoo dawọ ogun duro.
Titi de Lebanon ni ado oloro naa wa, nibi ti ibugbaamu to lagbara ti waye ni Beirut, ki wọn too kede pe ogun yoo dawọ duro loṣu kọkanla .
Labẹ adehun ogun tan to waye pẹlu Hamas yii, mẹtalelọgbọn (33) ninu awọn to wa nigbekun ogun ni wọn yoo tu silẹ ni Gaza.
Eyi wa fun lati ṣe paṣipaarọ pẹlu ọpọ ẹlẹwọn ọmọ Palestine ti wọn wa nihamọ lọgba ẹwọn Isreali gbogbo.
Israel àti Hamas fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró
Ni aarọ yii la mu iroyin wa pe orílẹ̀ èdè Israel àti ikọ̀ Hamas ti fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró, kí wọ́n sì tú àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀.
Ẹnìkan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ fún BBC pé ìpádé tí Olóòtú ìjọba Qatar ṣe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì ni wọ́n ti fẹnukò lórí àdéhùn náà.
Ìjọba Israel àti Hamas kò ì tíì fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún BBC àmọ́ àwọn aláṣẹ Hamas ti ṣáájú sọ fún BBC pé àwọn ti gba àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn tó ń báwọn dá sí ogun náà láti Qatar, US àti Egypt.
Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn ní Amẹ́ríkà, Donald Trump, táwọn aṣojú rẹ̀ náà wà lára àwọn tó dá sí ọ̀rọ̀ náà, kọ sójú òpó ayélujára rẹ̀ pé àwọn ti ń ṣiṣẹ́ lábẹ́nú fún àwọn tó wà ní àhámọ́ lẹ́kùn Middle East.

Oríṣun àwòrán, Getty image
Nǹkan tó wà nínú àdéhùn onípele mẹ́ta tí wọ́n fẹnukò lé lórí náà ni wọn kò ì tíì fi léde àmọ́ ìròyìn tó ń lọ ni pé àwọn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó jẹ́ ọmọ Israel tó wà ní àhámọ́ Hamas ni wọ́n máa gba ìtúsílẹ̀ ní pàṣí pààrọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Palestine tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Israel láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́fà àkọ́kọ́ tí ìdádúrọ ogun náà bá fi wáyé.
Ipele kejì ni wọ́n ti máa tú àwọn tó wà ní àhámọ́ míì sílẹ̀, tí àwọn ọmọ Israel máa kó nǹkan ìjà ogun wọn kúrò pátápátá, tí ẹ̀sọ́ pẹ̀lẹ́ yóò wáyé ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìgbà náà.
Ipele kẹta tó jẹ́ èyí tó gbẹ̀yìn ni bí wọ́n ṣe máa ṣe àtúnkọ́ Gaza èyí tó lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àti ìtúsílẹ̀ gbogbo àwọn tó bá ṣẹ́kù ní àhámọ́.
Iléeṣẹ́ ológun Israel bẹ̀rẹ̀ gbígbógun ti ikọ̀ Hamas nígbà tí ikọ̀ ṣe ìkọlù sí ẹkùn gúúsù Israel lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2022 níbi ti ẹgbẹ̀fà (1,200) èèyàn ti jáde láyé, tí wọ́n sì fi èèyàn 251 sí àhámọ́.
Èèyàn tó lé ní 46,700 ni wọ́n ti pa ní Gaza lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera Gaza tí ikọ̀ Hamas ń ṣe àkóso rẹ̀ ṣe sọ.
Èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì ni wọn kò nílé lórí mọ́ látàrí ìkọlù ọ̀hún, tí ìṣẹ́, ebi, àírí epo, oògùn lò sì ń bá àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ fínra.
Israel ní èèyàn 94 ló ṣì wà ní àhámọ́ Hamas tí ìgbàgbọ́ sì wà pé 34 nínú wọn ló ti jáde láyé. Bákan náà ni àwọn ọmọ Israel mẹ́rin kan ti wà ní àhámọ́ Hamas ṣáájú ogun yìí táwọn méjì sì ti kú nínú àwọn náà.















