Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó fara gbá nínú ìbúgbàmù Ibadan lẹ́yìn ọdún kan?

Àkọlé fídíò, Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó fara gbá nínú ìbúgbàmù Ibadan lẹ́yìn ọdún kan?
Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó fara gbá nínú ìbúgbàmù Ibadan lẹ́yìn ọdún kan?
    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist

Ọjọ nla ni alẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrindinlogun osu Kinni ọdun 2024 ni opopna dejo Oyelese, ladugbo Bodija nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo.

Awọn olugbe agbegbe naa n mura lati wọle sun, ni ariwo ibugbamu sadede gbalẹ kan, eyi to mi ile ati ilẹ titi.

Yoruba ni a kii gbe ile ẹni, ka fi ọrun rọ, amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn olugbe agbegbe naa ni alẹ ọjọ ti a n sọ yii.

Koda, ẹni to n rin lọ ati awọn gbogbo adugbo to wa nilu Ibadan mọ pe nnkan nla kan ti sẹlẹ pẹlu ibugbamu to mu ariwo lọwọ naa.

Ijọba ni awọn eeyan kan to n wa kusa lọna aitọ to n gbe ni agbegbe naa, lo ko awọn ohun abugbamu sinu ile eyi to bu, to mu ki isẹlẹ naa waye.

Isẹlẹ ibugbamu ọhun mu ẹmi eeyan marun lọ, eeyan mẹtadinlọgọrin si fara pa nigba ti ile to to ọgọrin fara kaasa ninu isẹlẹ naa.

Ọpọ eeyan to jẹ baba onile, lo sadede di alainilelori mọ lojiji nigba naa, ti igba si yipada fun wọn.

Agbegbe ti ibugbamu ti waye

Isẹlẹ naa ti wa pe ọdun kan to waye lonii, BBC Yoruba fi ẹsẹ kan de agbegbe Bodija nilu Ibadan lati mọ bi nnkan se ri lẹyin ọdun kan.

A ba awọn eeyan to farapa tabi jẹ mọlẹbi awọn oloogbe ninu isẹlẹ naa sọrọ pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo lati mọ ibi ti nnkan de duro.

Bakan naa, a fẹ mọ iru ayipada to ti ba agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye lẹyin ọdun kan.

Tun wẹ, gbogbo ileri ti ijọba se lasiko naa fawọn eeyan to fori ko isẹlẹ ibugbamu naa, se gbogbo rẹ ni wn ti mu sẹ bi?

Yatọ si eyi, awọn afurasi to ko awọn ohun abugbamu sinu ile eyi to sokunfa isẹlẹ naa, nibo ni ẹjọ wọn de duro bayii?

Agbegbe ti ibugbamu ti waye

A dupẹ pe ko ju bayi lọ tori mo gbọ pe ni awọn agbegbe ti iru ibugbamu bayii ba ti waye, wọn maa n fi ọmọlanke ko oku awọn eeyan kuro nibẹ ni - Muyiwa Bamgbose

Olusọagutan Muyiwa Bamgbose sọ fun BBC Yoruba pe isin irọlẹ ni oun wa lasiko ti isẹlẹ ọhun waye.

O ni ohun gba ipe latọdọ awọn aladugbo oun lo pe oun pe ki oun mase pada wale.

"Mo pada wale lootọ, ti eefin si kun gbogbo agbegbe wa, a si foju ri oku eeyan marun to ku sinu isẹlẹ naa.

A dupẹ pe ko ju bayi lọ tori mo gbọ pe ni awọn agbegbe ti iru ibugbamu bayii ba ti waye, wọn maa n fi ọmọlanke ko oku awọn eeyan kuro nibẹ ni."

Idowu Fagbemi

Nigba ti mo yaju, ile karun si ile wa ni mo ti ba ara mi, mo dide nilẹ pẹlu ọgbẹ lori, amọ baba mi ku sinu isẹlẹ naa - Idowu Fagbemi

Ọdọmọkunrin ni Idowu Fagbemi, o padanu baba rẹ sinu isẹlẹ ibugbamu naa, toun naa si fara pa ninu isẹlẹ naa.

O salaye fun BBC Yoruba nipa bi isẹlẹ ibugbamu ọhun se waye, bi wọn se gbe lọ sile iwosan, ati bi baba rẹ se ku.

"Mo ti ile ẹkọ de lọjọ ti isẹlẹ naa waye ni, ile wa si lo ti ile ti ibugbamu naa ti waye.

Baba mi ri gaasi ile keji naa to n jona, o si fẹ gbe mọto wa kuro lẹ ibẹ.

Baba mi sunmọ ile naa, mo si lọ ba nibẹ, ohun ti mo ranti mọ niyẹn.

Nigba ti mo yaju, ile karun si ile wa ni mo ti ba ara mi, mo dide nilẹ pẹlu ọgbẹ lori, mo si n wa baba mi kiri.

Wọn gbe mi lọ sile iwosan, ọjọ karun si ni wọn sọ fun mi pe baba mi ti jade laye."

Agbegbe ti ibugbamu ti waye

Ijọba ko kede orukọ awọn eeyan to gbe ohun ibugbamu to bu pamọ sile, ko yẹ ki wọn se ẹjọ isẹlẹ yii ni bonkẹlẹ - Muideen Olalekan Olagunju

Ninu ọrọ tiẹ, Amofin Muideen Olalekan Olagunju naa tan imọlẹ si ohun ti oju rẹ to nipa isẹlẹ yii.

Bakan naa lo koro oju si bi awọn eeyan se n sọ lọ sibi ti isẹlẹ naa ti sẹlẹ, to si ni gbogbo awọn ẹri to yẹ ki awọn agbofinro ti tete ko nilẹ nibi isẹlẹ naa, ni ko ri bẹẹ.

"Iwadi wo ni ijọba ati ọlọpaa ti se, koda, wọn ko kede orukọ awọn eeyan to ni ibugbamu to bu.

Se iru ẹjọ yii ni eeyan maa n se ni bonkẹlẹ bi?

Sulaiman Olanrewaju, Agbẹnusọ fun gomina Seyi Makinde

Ijọba ti fun awọn eeyan agbegbe ibi ti ibugbamu naa ti waye ni owo lati fi ran wọn lọwọ fun itẹsiwaju aye wọn - Agbẹnusọ Seyi Makinde

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun Gomina Makinde salaye pe ni kete ti isẹlẹ ibugbamu naa waye, ni gomina ti se abẹwo si agbegbe naa.

"Gomina pasẹ pe ki wọn ko awọn olugbe agbegbe naa ti ko nile lori mọ lọ sile itura fun igba diẹ lati maa gbe.

Bakan naa lo sanwo iwosan awọn eeyan to fara pa.

Yatọ si eyi, ijọba ipinlẹ Oyo tun gbe igbimọ kan dide lati sewadi isẹlẹ naa, ti ijọba si fun awọn eeyan agbegbe naa ni owo lati fi ran wọn lọwọ fun itẹsiwaju aye wọn.

Awọn afurasi ti ọwọ tẹ lori isẹlẹ naa si ti wa nile ẹjọ lọwọ lọwọ.