Fídíò bí ìbúgbàmù tó wáyé ní Ibadan ṣe ṣẹlẹ́ àti álàyé ìrírí àwọn tó ṣojú wọn nìyí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹlẹ ibugbamu kan ti waye ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ni ilu Ibadan.
Gẹgẹ bi awọn kan to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe sọ iro ibugbamu naa rinlẹ de awon agbegbe kaakiri ilu Ibadan ni nnkan bii agogo mẹjọ alẹ to waye.Oriṣiiriṣii nkan lawọn eeyan ti n sọ pe o ṣe okunfa ibugbamu to rinlẹ eleyii to waye lalẹ ana ọjọ Iṣẹgun lopopona Dejo Oyelese lagbegbe Bodija niluu Ibadan.
Ọpọ eeyan niluu Ibadan ni wọn sọ pe awọn gbọ iro ati didun ibugbamu naa bo tilẹ jẹ pe ọpọ ninu wọn lo n gbe ni adugbo to jina si ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Awọn kan tiẹ sọ pe ilẹ riri lo ṣẹlẹ niluu Ibadan pẹlu bi ọpọ ile ti mi titi kaakiri ilu Ibadan nigba ti ibugbamu ọhun ṣẹlẹ.
'Mama mi ṣeṣe ninu ibugbamu naa'
Ẹlomiran tun sọ pe iya oun ṣeṣe ninu iṣẹlẹ naa tori ile to wa lẹgbẹ ibi ti ibugbamu yii ti waye ni mama oun n gbe.
O ṣalaye pe iya oun ti n gba itọju nile iwosan bayii.
Awọn kan tiẹ sọ pe ilẹ riri lo ṣẹlẹ niluu Ibadan pẹlu bi ọpọ ile ti mi titi kaakiri ilu Ibadan nigba ti ibugbamu ọhun ṣẹlẹ.



