Kí ló pa igbákejì akójàánu ilé aṣòfin àpapọ̀, Oriyomi Onanuga tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ìjayà?

Oríṣun àwòrán, Hon. Oriyomi Onanuga/ Facebook
Ọmọ ile igbimọ Aṣoju to n ṣoju ẹkun Ikenne/Sagamu l'Abuja, Ọnarebu Abilekọ Oriyomi Onanuga, ti jade laye.
Oloogbe Oriyomi Onanuga, ti ọpọ eeyan mọ si Ijaya, papoda l'Ọjọruu, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.
Ẹni ọdun mọkandinlọgọta, ( 59) ni.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aisan ranpẹ lo ṣe oloogbe naa to tun ṣoju ẹkun idibo Ariwa Remo, nipinlẹ Ogun, to fi jade laye.
Ileewosan kan nilẹ United Kingdom (UK) ni iroyin sọ pe Oloogbe Ijaya dakẹ si.
Abẹnugan ile igbimọ Aṣoju, Akin Rotimi, lo kede iku akinkanju obinrin ti wọn n pe ni Ijaya naa.

Oríṣun àwòrán, Hon. Oriyomi Onanuga/ Facebook.
Kókó márùn nípa ìtàn ayé Oriyomi Onanuga
Ọjọ keji, oṣu Kejila ọdun 1965 ni wọn bi Oloogbe Oriyomi Onanuga.
Oṣiṣẹ ijọba ti ki i dakẹ lori igbayegbadun agbegbe to n ṣoju fun ni.
Ọdun 2019 lo kọkọ darapọ mọ wọn nile igbimọ aṣofin, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
Oloogbe Ijaya ni alaga to n ri si ọrọ awọn obinrin ninu iṣakoso ile igbimọ naa to kọja.
Ni 2023 lo di Igbakeji akojanu(Deputy Chief Whip).
Nigba ti wọn n daro iku Onanuga, abẹnugan ile aṣoju atawọn akẹgbẹ rẹ yooku, sọ pe ọlọpọlọ pipe, onirẹle obinrin to fẹran iṣẹ gidi, lo papoda.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun, ninu atẹjade to fi daro iku Ijaya, sọ pe adanu ni iku obinrin naa jẹ fun ipinlẹ Ogun ati Naijiria lapapọ.
Ọtunba Gbenga Daniel (OGD) toun naa jẹ ọmọbibi agbegbe Remo ti oloogbe Onanuga ti wa, naa kẹdun iku Ijaya.
OGD sọ wa se apejuwe oloogbe naa bii aburo, olubanijiroro ati ẹni to n fi gbogbo igba ṣe aṣeyọri, adanu rẹ si dun oun gidigidi.
Ọpọ eeyan lo ti n daro iku oloṣelu nla ọmọ ipinlẹ Ogun naa, wọn ni ki Oluwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere.














