Ìdí rèé tí a fi ya N1.1bn bíi owó oúnjẹ àwọn òṣìṣẹ́ wa ní 2025 - JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB
Ajọ to n ri si igbaniwọle si awọn ile ẹkọ giga lorilẹede Naijiria, Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB), ti ṣalaye idi to fi ya owo to le ni biliọnu kan naira (1.1bn) sọtọ gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn oṣiṣẹ rẹ fun ọdun 2025.
Gẹgẹ bi ajọ JAMB ṣe ṣalaye, wọn ni o ṣe pataki fun awọn oṣiṣẹ awọn to n ṣiṣẹ takuntakun lati maa jẹ ounjẹ ọfẹ ẹẹkan lasiko iṣẹ.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni ajọ JAMB ṣalaye naa niwaju igbimọ to n ri si iṣuna nile igbimọ aṣoju-ṣofin.
Wọn fi kun un pe okun inu ṣe pataki fun awọn oṣiṣẹ naa ti iye wọn jẹ ẹgbẹrun meji le lọọdunrun (2,300), nitori okun inu ni a fi n gbe ti ita.
Ajọ to n ri si igbaniwọle sile ẹkọ giga naa sọ pe eto ounjẹ ọfẹ ẹẹkan lojumọ naa tun kan awọn agbalẹ to n gba ọfiisi ati awọn oṣiṣẹ to n ṣọ ọgba awọn kaakiri orilẹede Naijiria.
'A kò fẹ́ kí jàmbá ṣẹlẹ̀ sí àwọn òṣìṣẹ́ wa níbi tí wọ́n bá ti ń wa oúnjẹ kiri lásìkò iṣẹ́, la ṣe gbé èrò yìí kalẹ̀'
" A gbe ero yii kalẹ lati ri i daju pe awọn oṣiṣẹ wa to n ṣiṣẹ ẹlẹgẹ ko bọ sọwọ ewu lasiko ti wọn ba n wa ounjẹ ti wọn yoo jẹ lasiko ti iṣẹ n lọ lọwọ.
" A fẹẹ ki wọn le kọju mọ iṣẹ naa lai si pe ohunkohun di wọn lọwọ.''
Bẹẹ ni ajọ JAMB ṣalaye.
Wọn ni eto ounjẹ ẹẹkan lẹnu iṣẹ naa ti wa nilẹ tẹlẹ ni Olu ileeṣẹ JAMB. Ẹgbẹrun kan ati igba naira (1,200) ni wọn ni awọn ya sọtọ fun oṣiṣẹ kan lati na.
Ṣugbọn bi ounjẹ ṣe bẹrẹ si i wọngogo, wọn ni yoo di ẹgbẹrun meji ati igba naira (2,200) ni 2025, lai si owo ori nibẹ.
"Nitori afikun yii, owo ti yoo le pese ounjẹ fun oṣiṣẹ 2, 300 fun ọdun kan ni a foju sun pe yoo to 1.27bn. Ṣugbọn a ge e si N1.1 billion. Eyi n fihan bi a ṣe fẹran lati maa ṣọ owo naa si.''
JAMB ni ninu owo ti awọn n pa wọle labẹnu,(Internally Generated Revenue) lawọn ti fẹẹ nawo yii.
Wọn ni ki i ṣe lati apo ijọba.
Ajọ JAMB waa rọ gbogbo ẹni to ni kinni kan tabi ikeji lati ba wọn ṣe lati ma ṣe foya.
Wọn ni inakunaa kọ lawọn fẹẹ na, bi ko ṣe lati dahun si igbayegbadun awọn oṣiṣẹ awọn.














