Ìdí rèé táwọn gómìnà ṣe fòǹtẹ̀ lu àtúnṣe ìlàná owó orí tuntun, bèèrè fún àtúnṣe pínpín owó orí ọjà

Oríṣun àwòrán, Nigerian governors forum
Apapọ awọn gomina ni Naijiria ti ṣatilẹyin fun atunto owo ori tuntun ti ijọba apapọ gbe igbesẹ lati ṣagbekalẹ rẹ, eyii ti awọn kan ninu wọn ti kọkọ kọ ṣaaju.
Ninu atẹjade kan lẹyin ipade ẹgbẹ awọn gomina to waye lọjọbọ ni wọn ti sọ pe awọn yoo ṣatilẹyin fun eto owo ori tuntun naa lati mu ayipada ba eto owo ori atijọ ti Naijiria n lo.
Atẹjade ọhun sọ pe "Awọn ọmọ ẹgbẹ mọ pataki ṣiṣe atunṣe si owo ori gbigba ki o le ba bi wọn ṣe n ṣe e lawọn orilẹede mii lagbaye mu."
Awọn gomina ọhun tun daba igbesẹ tuntun ti ijọba yoo fi maa pin owo to ba pa wọle lori VAT laarin awọn ipinlẹ.
Awọn gomina n fẹ pin ida aadọta owo ori, ida ọgbọn fun ipinlẹ to ba pa owo wọle julọ ati ida ogun fun ipinlẹ ti ero rẹ ba pọju
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ida 50% yoo wa fun gbogbo awọn ipinlẹ lati pin, ipinlẹ to ba pa owo wọle julọ yoo gba ida 30% nigba ti ipinlẹ ti ero rẹ ba pọju yoo gba 20%.
Atẹjade naa sọ siwaju si pe "Awọn ọmọ ẹgbẹ fẹnuko pe ijọba ko ni ṣe afikun iye owo VAT, bẹẹ ni ko ni din iye owo ori ti awọn ileeṣẹ, Corporate Income Tax (CIT) n san ku lọwọ yii."
Wọn ni eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin ati mu ki eto ọrọ aje duro dede ki nnkan ma ba a daru siwaju si.
Bo tilẹ jẹ pe ọrọ atunṣe owo ori naa fa ọpọlọpọ awuyewuye, awọn gomina ọhun sọ pe awọn fọwọ si ki awọn aṣofin maa ṣiṣẹ lọ lori ofin owo ori ọhun titi di igba ti yoo fi di ofin.
Pupọ ninu awọn to tako atunṣe owo ori tuntun naa ni awọn gomina lati iha ariwa, to fi mọ awọn adari mii ni Naijiria.
Awọn gomina ariwa naa sọ pe ile aṣofin ko gbọdọ gba abadofin naa wọle nitori yoo ṣe akoba fun iha awọn.
Amọ ṣa, Aarẹ Bola Tinubu kọ jalẹ lati wọgile aba owo ori tuntun naa, paapaa bi ijọba yoo ṣe maa pin owo VAT laarin awọn ipinlẹ.
Tinubu ni abadofin ọhun ko wa fun titako awọn eeyan kan bi ko ṣe fun anfani gbogbo ọmọ Naijiria.















