Kókó ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbúrawọlé Donald Trump àti bí ayẹyẹ náà yóò ṣe lọ lọ́jọ́ Aje

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii ni Aarẹ Amẹrika tuntun, Donald Trump yoo pada sile ijọba, White House.

Lara ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ naa ni iburawọle, ayẹyẹ ati idaraya lati owọ awọn olorin atawọn ologun.

Lọjọ kan naa ni igbakeji Aarẹ, JD Vance yoo ṣe iburawọle pẹlu Trump loju gbogbo aye.

Bo tilẹ jẹ pe inu oṣu Kọkanla ọdun to kọja ni Trump bori ibo Aarẹ, ọjọ Aje ọhun ni yoo joko sori aga Aarẹ.

Ṣaaju akoko yii ni Trump ti kọkọ wa nipo naa gẹgẹ bi Aarẹ karundinlaadọta ilẹ Amẹrika laarin ọdun 2017 si 2021 ki Joe Biden to gbajọba.

Ki ni yo ṣẹlẹ lọjọ naa?

Ile ijọsin St. John, to wa ni Lafayette Sqaure, ni Washington DC ni isin yoo ti kọkọ waye ki wọn to lọ mu tii ni White House.

Awọn olorin yoo ṣere lori papa to wa niwaju ile nla US Capitol ni aago mẹsan an abọ owurọ.

Nibẹ ni wọn yoo ti burawọle fun Trump, ti yoo si sọ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ yoo ṣe fun ọdun mẹrin to n bọ.

Lẹyin naa, yo wọn inu yara Aarẹ to wa lẹgbẹ ile aṣofin lọ lati tọwọ bọ awọn iwe kan.

Nigba to ba di alẹ, yoo yọju sibi apẹjẹ mẹta ọtọtọ ti wọn gbe kalẹ fun ayẹsi rẹ.

Awọn wo ni yoo ṣere lọjọ naa?

Obinrin olorin kan to ti gba ami ẹyẹ American Idol, Carrie Underwood yoo ṣere.

Olorin Opera, Christopher Macchio yoo ṣere, ọrẹ tipẹtipẹ Trump, Lee Greenwod, naa yoo tun ṣere nibẹ.

Awọn mi ti yoo tun ṣere ni Kid Rock, Billy Ray Cyrus, Jason Aldean, Rascal Flatts ati Gavin DeGraw

Bawo ni o ṣe le wo iburawọle naa?

Ijọba Amẹrika ti ṣeto tikẹẹti fun awọn ti yoo wa nikalẹ lati wo iburawọle naa niluu Washington.

Ọfe ni awọn tikẹẹti naa amọ o ṣoro lati ri tikẹẹti ọhun gba.

Ṣugbọn fun iwọ gẹgẹ bii ololufẹ BBC o le wo ayẹyẹ naa loju opo ileeṣẹ wa lori ẹrọ amohunmaworan rẹ tabi lori Facebook ati YouTube.

Awọn wo ni yoo wa nibi ti eto naa?

Nnkan bii ẹgbẹrun lọna igba eeyan ni ireti wa pe yoo peju siluu Washington lati foju lounjẹ lọjọ naa, ti ọpọ ninu wọn jẹ ololufẹ atawọn alatako Trump.

Bẹẹ naa ni awọn aṣofin ilẹ Amẹrika yoo wa nibẹ to fi mọ Aarẹ to n gbe agbara silẹ, Joe Biden ati igbakeji rẹ, Kamala Harris.

Aarẹ Amẹrika tẹlẹ, Barack Obama ati George Bush yoo wa nikalẹ lọjọ naa pẹlu.