''Fifi ẹnu yẹpẹrẹ Ìṣẹ̀ṣe ni ìlú fi ń dàrú, a ti fi ọ̀nà àwọn baba ńlá wa sílẹ̀''
Idalu ni isẹlu gẹgẹ bi awọn Yoruba ṣe maa n wi, gọngọ sọ nibi ayẹyẹ ọdun Vodun to waye lorilẹede Benin nibi ti wọn ti maa n da Ifa ilu.
Onifa kan to fi ilu Ajase lorilẹede Benin Republic ṣe ibugbe, Olori Asake ni lọdọọdun ni wọn maa n difa ilu bayii.
O ni ''ti a ba wo o daadaa, a o ri pe aṣa awa Yoruba ni Ifa dida, ati pe Ifa dida yii maa n waye ni ọpọlọpọ ilu.
Kii ṣe pe nigba ti wọn ti da Ifa ni Ajase, wọn o ni da Ifa ni ibomiran mọ, awọn mii naa tun n difa lawọn ibomiran.
Ohun to ṣe pataki ni pe a o gbọdọ ko iṣẹṣe danu, nibi kiko iṣẹṣe danu ni ilu fi n daru.''
Olori Asake ni bi gbogbo nnkan ṣe n lọ laye ode oni fihan pe, ''a o tẹle ilana tawọn baba nla wa nilẹ Yoruba fi le ilẹ mọ.
Wọn ṣe etutu lẹyin Ifa ti wọn da lọdun to kọja, ilu si roju.''
Oloosa Salako Benoit naa ṣalaye wi pe ti eeyan ba n beere nkan lọwọ Oriṣa pẹlu inu mimọ, o ni ohun naa yoo tẹ eeyan ọhun lọwọ.
Olooṣa mii, Ayihoun Akwavi toun naa wa nibi ajọdun naa sọ pe ooṣa toun n sin le wo aisan were lara eeyan.
Lara awọn eto ti wọn fi dawọn eeyan lara ya ni ijo Gẹlẹdẹ nibi ajọdun ọhun.



