Ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ gbérasọ l'Ondo, àmọ́ PDP kò ní kópa nínú ètò ìdìbò náà

Eto idibo ijọba ibilẹ ipinlẹ Ondo ti gberasọ kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ naa.
Amọ, ẹgbẹ oṣelu APC atawọn ẹgbẹ mii nikan ni yoo dije ninu eto idibo naa latari bi PDP ṣe duro lori ẹsẹ wọn wi pe awọn ko ni kopa ninu eto idibo naa.
Ni deedee aago mejọ kọja isẹju marun-un aarọ ọjọ Abamẹta ọjọ kejidinlogun oṣu kinni yii ni awọn ajọ eleto idibo ODIEC ko awọn ohun elo eto idibo de ile ẹkọ St. Stephen's Anglican Primary School Ijomu niluu Akure.
Oriko naa ni wọn yoo ti pin awọn ohun elo fun gbogbo awọn osisẹ wọn ti yoo se isẹ jakejado Wọọdu kẹrin nijọba ibilẹ Gusu Akure.
Awọn oludibo naa ti wa ni ijokoo de awọn osisẹ ajọ eleto idibo ki wọn to de oriko naa.
Saaju ni ẹgbẹ Oṣelu PDP ninu atejade latọwọ adari eto iroyin ati ipolongo rẹ Leye Igbagbo kede pe Ẹgbẹ naa ko ni kopa mọ ninu eto idibo ti yoo waye ni ọjọ kejidinlogun oṣu yi.
Ikede yi waye bi eto idibo naa se ku ọjọ meji pere, to si jẹ pe gbogbo awọn oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu naa ti na owo ti wọn si ti kopa ninu gbogbo eto ki ẹgbẹ naa to kede pe wọn ko ni kopa ninu eto naa mọ.
Kìni ìdí tí ẹgbẹ PDP fi yọwọ́ nínú eto ìdìbò?
Adari eto iroyin ati ipolongo lẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo Leye Igbagbo sọ pe wọn yan lati ma kopa nitori ajọ to n bojuto eto idibo nipinlẹ Ondo ODIEC yoo ṣegbe lẹyin ẹgbẹ Oṣelu APC ninu eto naa.
O sọ pe wọn mọ daju pe, magomago yoo waye ninu eto idibo naa nitori ajọ ODIEC ko to gbangba sun lọyẹ lati seto idibo naa.
Igbagbo salaye pe wọn gbe igbese yi lẹyin ọpọlọpọ ipade pẹlu awọn adari ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo ati n'ilu Abuja.
O sọ pe wọn yan lati ma ṣe kopa nitori wọn ni igbagbọ ninu eto idibo ti ko si magomago kan ti ko si ṣegbe lẹyin ẹgbẹ Oṣelu kan ju kan lọ.
Igbagbo rọ gbogbo awọn alatileyin ẹgbẹ PDP lati ni igbagbọ ninu igbese ti ẹgbẹ naa gbe, pẹlu ileri pe ẹgbẹ naa yoo tẹsiwaju lati ma ṣe ohun ti o tọ fun idagbasoke ẹgbẹ naa.












