'Ohun ìtìjú ni pé PDP kò ní kópa nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l'Ondo'

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oluwatuyi Adekambi/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo Alaga nijọba ibilẹ Guusu Akure labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ọgbẹni Adekambi Oluwatuyi ti sapejuwe igbese PDP lati ma kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ gẹgẹ bi ohun itiju ti ko si bojumu.

Oluwatuyi lasiko to n ba BBC NEWS YORUBA sọrọ salaye pe, awọn adari ẹgbẹ naa ko ṣe ipade tabi sọ fun awọn oludije ki wọn to kede pe wọn ko ni kopa ninu eto idibo naa.

Saaju ni ẹgbẹ Oṣelu PDP ninu atejade latọwọ adari eto iroyin ati ipolongo rẹ Leye Igbagbo kede pe Ẹgbẹ naa ko ni kopa mọ ninu eto idibo ti yoo waye ni ọjọ kejidinlogun oṣu yi.

Ikede yi waye bi eto idibo naa se ku ọjọ meji pere, to si jẹ pe gbogbo awọn oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu naa ti na owo ti wọn si ti kopa ninu gbogbo eto ki ẹgbẹ naa to kede pe wọn ko ni kopa ninu eto naa mọ.

Oluwatuyi sọ pe gbogbo oludije lo ti na owo ti wọn si fi ọkan awọn alatileyin wọn balẹ pe wọn yoo jawe olubori ninu eto idibo naa.

O sọ pe ijakule nla ni igbese yi jẹ fun gbogbo awọn oludije labẹ ẹgbẹ Oṣelu PDP ati awọn alatileyin wọn.

Oludije naa sọ pe awọn adari ẹgbẹ PDP ko ni idi pataki ti wọn fi sọ pe wọn ko kopa mọ ninu eto naa, O sọ pe wọn gbọdọ ra ọwọ ẹbẹ si gbogbo awọn oludije naa ati awọn alatileyin wọn.

Oluwatuyi sọ pe " O jẹ ohun itiju ati iwa ti ko bojumu pe awọn adari ẹgbẹ wa kọ lati kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye. Titi di ọjọ ti wọn kede, wọn ko sọ fun awa oludije pe ẹgbẹ wa ko ni kopa ninu eto idibo naa.

" Gbogbo eto lati ibẹrẹ lati kopa, a gba fọọmu, ṣe ipolongo idibo fun awọn alatilẹyin wa ni ireti pe a o jawe olubori, sugbọn ireti naa jasi pabo, ti awọn adari ko si sọ ohunkohun titi di igba ti eto idibo ku ọjọ meji"

Lasiko to n dahun ibeere lori boya wọn ti ba awọn adari ẹgbẹ naa se ipade leyin ikede yii, Oluwatuyi sọ pe "a ko ni ohunkohun lati ba wọn sọ nitori pe wọn ko pe wa ki wọn to gbe igbese yi, nitori naa a ko nilo lati ba wọn ṣe ipade mọ."

Kìni ìdí tí ẹgbẹ PDP fi yọwọ́ nínú eto ìdìbò?

Adari eto iroyin ati ipolongo lẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo Leye Igbagbo sọ pe wọn yan lati ma kopa nitori ajọ to n bojuto eto idibo nipinlẹ Ondo ODIEC yoo ṣegbe lẹyin ẹgbẹ Oṣelu APC ninu eto naa.

O sọ pe wọn mọ daju pe, magomago yoo waye ninu eto idibo naa nitori ajọ ODIEC ko to gbangba sun lọyẹ lati seto idibo naa.

Igbagbo salaye pe wọn gbe igbese yi lẹyin ọpọlọpọ ipade pẹlu awọn adari ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo ati n'ilu Abuja.

O sọ pe wọn yan lati ma ṣe kopa nitori wọn ni igbagbọ ninu eto idibo ti ko si magomago kan ti ko si ṣegbe lẹyin ẹgbẹ Oṣelu kan ju kan lọ.

Igbagbo rọ gbogbo awọn alatileyin ẹgbẹ PDP lati ni igbagbọ ninu igbese ti ẹgbẹ naa gbe, pẹlu ileri pe ẹgbẹ naa yoo tẹsiwaju lati ma ṣe ohun ti o tọ fun idagbasoke ẹgbẹ naa.