Àwọn olùgbé Gaza ti ń padà sílé lẹ́yìn àdéhùn àlááfíà, àmọ́ àwókù ilé wọn ni wọ́n ń bá

Aworan awọn awoku ile kan ni Gaza.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn olugbe ilu Gaza ti n pada sile wọn lẹyin ti adehun idawọ ogun duro to waye laarin Israel ati Hamaz wọ ọjọ keji.

Bi o tilẹ jẹwipe awoku ile ni ọpọ wọn n de bọ wa ba, sibẹ pẹlu idunnu lawọn olugbe Gaza fi n pada si ilu wọn.

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan naa ni wọn sa kuro ni ilu Gaza nigba ti ikọlu Israel gbinaya fun oṣu mẹrindinlogun gbako ki alaafia to jọba ljọ Aiku.

Obinrin kan joko si ibi awoku ohun to pe ni ile rẹ nigba kan ri.

Oríṣun àwòrán, EPA

Rana Mohsen ẹni ọdun mẹtalelogoji ti oun pẹlu sa fi ilu Gaza silẹ lati lọ farasin si ilu Labalia sọ pe o ti pẹ ti awọn ti n fi oju sọna fun iru akoko yii.

"Ayọ mi kun pupọ ko si ṣe fi ẹnu sọ. A ti pada de si ile wa. Ko si ile mọ awoku erupẹ la ba, ṣugbọn sibẹsibẹ ile wa ni.

Lowurọ ọjọ Aje, aadọrun awọn ọmọ Palestine to wa ninu ahamọ ni Israel ni wọn tu silẹ lẹyin ti awọn ikọ Hamaz ti tu awọn eeyan mẹta lara ti wọn mu lasiko ikọlu ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023 silẹ.

Hamas n sọ pe ọgbọn ọmọ Palestine lawọn Israel yoo maa tu silẹ lori ọmọ Israel kọọkan ti wọn ba tu silẹ.

Khalida Jarrar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn obinrin atawọn ọmọde lo pọju ninu awọn onde ti wọn tu silẹ lọjọ Aje. Lara wọn ni Khalida Jarrar to jẹ aṣiwaju ẹgbẹ Popular Front for the Liberation of Palestine, .

Kókó ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdáwọ́ogun dúró láàrín Israel àti Hamaz
Aworan awọn ogunlende ọmọ Palestine to n mura ati pada sile wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eto idawọ ogun duro laarin Awọn ọmọ ogun Isreal ati Hamaz ni Gaza bẹrẹ lọjọ Aiku lẹyin oṣu marundinlogun ti ina ogun ti n sọ lala ni Gaza.

Nnkan bii agogo mokanla kọja iṣẹju marundinlogun owurọ lorilẹẹdẹ Israel, (iyẹn agogo mẹsan kọja iṣẹju marundinlogun owurọ GMT ) ni eto naa fidimulẹ. O yẹ ko ti bẹrẹ ni nnkan bii wakati mẹta ṣaaju sugbọn orilẹede Israel ni ko le bẹrẹ bi Hamaz ko ba fi orukọ awọn to fẹ tu silẹ ninu igbekun rẹ sita.

Hamaz ni awọn idiwọ kan lo fa a, lẹyin eyi lo fi orukọ awọn mẹta to kọkọ fẹ tu silẹ sita: Doron Stei brecher ẹni ọgbọn ọdun, Emily Damari ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Romi Gonen, ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Hamaz kọlu Israel lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023, nibi ti wọn ti pa eeyan ẹgbẹrun kan le ni igba, ti wọn si ko eeyan igba ati mọkanlelaadọta mii si igbekun.

Eyi lo ṣokunfa bi Israel pẹlu ṣe ṣigun wọ Gaza, lasiko ti emi ẹgbẹrun mẹrindinlaadọta ati ẹgbẹrin eeyan (46, 800) ti ba a lọ gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ eto ilera ro wa labẹ iṣakoso Hamaz ṣe sọ.

Awọn ọmọ Palestine ti ogun le ti n mura irinajo pada sile

Awọn ọmọ Palestine ti ogun le ti n mura irinajo pada sile

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ ilẹ Palestine ti ogun to n waye laarin Israel ati Hamaz ti sọ di atipo ni wọn ti n pada si ile wọn bayii lowurọ ọjọ Aiku.

Ogunlọgọ lo to sori ila pẹlu aṣọ at'awọn dukia han ninu awọn fọto to n jade. Bakan naa l'awọn ọkọ to lọwọọwọ, pẹlu awọn eeyan kan to n di aṣia ilẹ Palestine mu.

Awọn ohun ti a n ri niyi:

Aworan awọn ogunlende ọmọ Palestine to n mura ati pada sile wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan awọn ogunlende ọmọ Palestine to n mura ati pada sile wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan awọn ogunlende ọmọ Palestine to n mura ati pada sile wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan awọn ogunlende ọmọ Palestine to n mura ati pada sile wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ajọ iṣọkan agbaye UN sọ pe awọn ọkọ to kun fun iranwọ ounjẹ ati iyẹfun n duro lati wọ Gaza

aworan oko ajo UN

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ iṣọkan agbaye UN sọ pe awọn ọkọ to kun fun iranwọ ounjẹ ati iyẹfun n duro lati wọ Gaza

Ajọ iṣọkan agbaye UN to n mojuto awọn ogunlende ni Palestine, UNRWA sọ pe eyi wa lara awọn ohun ti wọn fẹnuko le lori ninu iwe adehun ipẹtusija naa.

Ninu atẹjade kan lori oju opo X rẹ, ajọ naa sọ pe " ẹgbẹrun mẹrin ọkọ to kun fun iranwọ lo ti wa nikalẹ lati wọ Gaza, - ilaji wọn lo ko ounjẹ ati iyẹfun".

 aweoran gaza.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Israel kede oruko awọn eeyan mẹtalelọgbọn ti Hamaz fẹ tu silẹ ni ahamọ

Orukọ awọn eeyan ti Hamaz fẹ tu silẹ ninu ahamọ ni abala akọkọ eto idawọ ogun duro to n waye laarin Israel ati Hamaz bayii ti jade.

Iseael salaye loju opo X rẹ pe awọn to kere ju at'awọn to dagba julọ lara awọn ti Hamaz ko ni ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023 wa lara awọn ti wọn yoo kọkọ tu silẹ.

Bakan naa ni wọn tun fi aworan won sita.

aworan won

Oríṣun àwòrán, screenshot