Bí ogun oṣù mẹ́ẹ̀dógún ṣe mú àyípadà bá Gaza

Àwòrán ìlú Gaza
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìfẹnukò ti wáyé láti dáwọ́ ogun dúró ní Gaza àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti bàjẹ́ ní ìlú tó wà ní ẹnubodè Palestine náà láti bíi oṣù mẹ́ẹ̀dógún tí ogun fi wáyé níbẹ̀.

Israel bẹ̀rẹ̀ sí ní ju àdó olóró sí Gaza lẹ́yìn tí ikọ̀ Hamas ṣe ìkọlù sí gúúsù Israel lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 níbi tí èèyàn ẹgbẹ̀fà ti jáde láyé, tí wọ́n sì tún fi èèyàn 251 sí àhámọ́.

Israel ní àwọn ń gbìyànjú láti pa ibùdó ikọ̀ Hamas, tó ti ń ṣàkóso Gaza láti ọdún 2007, rẹ́ ṣùgbọ́n iléeṣẹ́ ètò ìlera tí ikọ̀ Hamas ń ṣàkóso rẹ̀ ní àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine 46,600 ló ti bógun lọ.

Àwọn èèyàn Gaza ni ìrètí wọn ga báyìí pé pẹ̀lú ìkéde dídáwọ́ ogun dúró náà yóò mú àláfíà jọba ní agbègbè náà àmọ́ àjọ ìṣọ̀kan àgbàyé, UN ní yóò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí ẹkùn náà padà sípò pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ti bàjẹ́ níbẹ̀.

Àwọn àwòrán tó wà ní ìsàlẹ̀ ṣàfihàn bí ìlú náà ṣe yíàdà lásìkò ogun náà.

Báyìí ni àwọn nǹkan ṣe bàjẹ́ lẹ́kun náà

Ẹkùn àríwá Gaza ni Israel kọ́kọ́ gbájúmọ́ lásìkò tí ogun náà bẹ̀rẹ̀ – wọ́n ní ikọ̀ Hamas ń fara pamọ́ sáàárín àwọn ará ìlú níbẹ̀.

Ìlú Beit Hanoun tó wà ní ìwọ̀n kìlómítà méjì láti ẹnubodè wà lára àwọn ìlú tí àdó olóró Israel kọ́kọ́ ṣe lọ́ṣẹ́ nígbà tí ogun náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.

Máàpù Gaza

Israel tẹ̀síwájú láti máa ju àdó olóró sí ìlú Gaza àtàwọn ìlú ńlá mìírà tó wà lẹ́kùn àríwá , tí wọ́n sì pàṣẹ fáwọn ará ìlú láti kúrò ní gúusù Wadi Gaza fún ààbò kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ni ju àdó olóró láti ilẹ̀ kó tó di ìparí oṣù Kẹwàá, ọdún 2023.

Síbẹ̀ náà ni wọ́n ń ju àdó olóró láti ojú òfurufú sáwọn ìlú tó wà ní gúúsù níbi táwọn tó ń sá kúrò ní ẹkùn àríwá ń sa lọ. Nígbà tó fi máa di ìparí oṣù Kọkànlá, ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tó wà ní gúúsù náà ni àdó olóró ti ṣọṣẹ́ níbẹ̀ bíi táwọn tó wà ní ẹkùn àríwá.

Máàpù Gaza

Israel pọkún bí wọ́n ṣe ń ju àdó olóró sí gúúsù àti ààrin gbùngùn Gaza ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kejìlá, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ jíju àdó olóró sí Khan Younis. Nígbà tó fi máa di oṣù Kìíní ọdún 2024, ìdajì àwọn ilé tó wà ní Gaza ni àdó olóró ti dàwó.

Máàpù Gaza

Ogun tó wáyé fún oṣù mẹ́ẹ̀dógún náà ba ìdá ọgọ́ta àwọn ilé tó wà ní ẹkùn Gaza jẹ́, tí ìlú Gaza fúnra rẹ̀ ló fara kásá ìbàjẹ́ náà jùlọ gẹ́gẹ́ àwọn onímọ̀ láti CUNY Graduate Center and Oregon State University tó ń yànnàná ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe sọ.

Máàpù Gaza

Àjọ ìṣọ̀kan àgbàyé, UN ní ìdá àádọ́rùn-ún (90%) nínú àwọn ilé tí wọ́n dàwó ló jẹ́ ilé ìgbé pẹ̀lú bí ilé 160,000 ṣe bàjẹ́ pátápátá tàwọn 276,000 sì dàwó kù láàbọ̀.

Lásìkò ogun náà, Hamas – tí Israel, UK àtàwọn míì kà kún ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí – àtàwọn abẹ́ṣinkáwọ́ rẹ̀ ń bá àwọn ọmọ ogun wọ ìjàkadì lórí ilẹ̀. Bákan náà ni wọ́n tún ń ju àdó olóró láti ojú òfurufú sí Israel.

Ìlú abẹ́ àtíbàbà

Nǹkan kò dẹrùn ní Gaza ṣáájú kí ogun tó bẹ̀rẹ̀ náà, fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Israel àti Egypt máa ń tì í pa látàrí àti ṣàmójútó àwọn tó ń wọlé jáde níbẹ̀ èyí táwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì sọ pé àwọn nílò fún ààbò.

Gẹ́gẹ́ bí ilé ìfowópamọ́ àgbàyé ṣe ṣo ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta àwọn tó wà ní orílẹ̀ èdè náà ni ìṣẹ́ àti òṣì ń bá fínra àti pé ọ̀pọ̀ wọn lo ń ṣe àtìpó láwọn ibùdó ìṣàtìpó tó jẹ́ ti àjọ UN.

Àmọ́ Gaza kò ti ẹ̀ ṣe é gbé mọ́ báyìí.

Ìlú Gaza lásìkò ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo ìlú náà ni wọ́n ti jó kanlẹ̀, àwọn ilẹ̀ tó wà fún nǹkan ọ̀gbìn ló ti di ìyẹ̀pẹ̀ lásán látàrí àwọn àdó olóró táwọn ọmọ ogun Israel jù síbẹ̀.

Ṣáájú ogun, ìlú mẹ́rin – Rafah àti Khan Younis tó wà ní gúúsù, Deir al-Balah ní ààrin gbùngùn àti Gaza City láwọn èèyàn mílíọ̀nù méjì tó wà ní Gaza ń gbé jùlọ àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ni kó rí ilé gbé mọ́.

Máàpù tó ṣàfihàn iye èèyàn tí kò nílé lorí ní Gaza

Oríṣun àwòrán, UNRWA

Ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé ni kò rí ilé gbé mọ́, tí wọ́n sì ń kó láti ibìkan bọ́ si ibòmíràn bí Israel ṣe ń yí àfojúsùn lọrí ogun náà padà.

Àwòrán sátẹ́láìtì ṣàfihàn àwọn àtíbàbà táwọn èèyàn ta ní al-Mawasi látàrí pé wọn kò ní ilé lórí mọ́. Ibi yìí ni Israel ní káwọn ará ìlú dúró sí fún ìbojúàánúwoni lọ́dún 2023.

Àwòrán báwọn èèyàn ṣe ń ta àtíbábá káàkiri Gaza

Oríṣun àwòrán, Planet Labs PBC

Àwòrán báwọn èèyàn ṣe ń ta àtíbábá káàkiri Gaza

Oríṣun àwòrán, Planet Labs PBC

Oṣù karùn-ún ọdún 2023 ni wọ́n mú àlékún bá ibi táwọn èèyàn le forí pamọ́ sí, tí wọ́n fi Khan Younis àti Deir al-Balah sì kún wọn lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìkọlù sí Rafah níbi tí èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan ń gbé.

Láti ìgbà náà ni àdínkù sì ti ń bá ibi táwọn ará ìlú le forí pamọ́ sí bí Israel ṣe ń ju àdó olóró sáwọn ibi tí ikọ̀ Hamas wà pẹ̀lú àwọn ará ìlú níbẹ̀.

Ní oṣù Kẹjọ 2024 ni UN ní èèyàn tí iye wọn tó mílíọ̀nù kan lé díẹ̀ ló ń ṣàtìpó ní al-Mawasi tí kò sì sí àwọn ohun amáyédẹrùn tó tó níbẹ̀.

Ìpèníjà oúnjẹ

Bíi mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rin èèyàn ni kò rí oúnjẹ jẹ gẹ́gẹ́ bí àjọ Integrated Food Security Phase Classification (IPC) ṣe sọ.

Ìjàbọ́ àjọ náà fún oṣù Kẹjọ ọdún 2024 sí oṣù Kẹsàn-án 2025 ní àìrí oúnjẹ tó dára jẹ lékún ní ìdá mẹ́wàá ju bí ó ṣe wà ṣáájú ogun.

Àwọn tó ń tò fún oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìdá ọgọ́rin àwọn èèyàn tó wà ní Gaza ló nílò ohun èlò amáyédẹrùn ṣáájú ogun.

Fún bíi ọjọ́ mẹ́wàá ni wọn kò fi rí àwọn ohun èlò wọ Gaza nígbà tí Israel àti Egypt ti ẹnubodè wọn pa lẹ́yìn ìkọlù ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá.

Nínú oṣù Kẹta, àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ lágbàáyé, World Food Programme ní ọ̀ọ́dúnrún ọkọ̀ ńlá tó kó oúnjẹ ló nílò láti máa wọ Gaza láti tán ìṣòro àìrí oúnjẹ tó ń bá àwọn èèyàn fínra níbẹ̀.

UN di ẹ̀bi àìrí ohun èlò pèsè fáwọn èèyàn ní Gaza ru báwọn ẹ̀ṣọ́ ológun Israel ṣe ń fòfin de àwọn tó ń pèsè àwọn oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì láti wọ Gaza.

Àwòrán bí ọkọ̀ ṣe ń wọ Gaza láti pèsè ohun amáyédẹrùn fún wọn

Oríṣun àwòrán, United Nations

Ìṣẹ́ ń peléke si

Ogun tó wáyé náà ní ipa lórí ètò ọrọ̀ ajé Gaza èyí tí ilé ìfowópamọ́ àgbàyé ní ó ti rí ìfàsẹ́yìn ní ìdá 86% ní oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ọdún 2024.

Wọ́n ní gbogbo èèyàn tó wà ní ẹkùn náà ló ń gbé nínú ìṣẹ́ àti òṣì báyìí lòdì sí ìdá 64% tó wà ṣáájú ogun.

Àwòrán bí oúnjẹ ṣe ń wọ́n sí

Oríṣun àwòrán, Christian Aid, Getty

Ẹ̀ka tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé àti ìdàgbàsókè ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé sọ pé iye nǹkan tí ogun náà bàjẹ́ ní Gaza tó $18.5bn àti pé ó máa gbà wọ́n ní ọdún 350 láti bá bí ètò ọrọ̀ wọn ṣe rí lọ́dún 2022 àyàfi tó bá tètè gbèrú ju bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìwòsàn ni kò ṣiṣẹ́ mọ́ látàrí àìsí epo, irinṣẹ́ tàbí ìkọlù tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ogun.

Àjọ ètò ìlera àgbàyé, WHO ní ilé ìwòsàn méjìdínlógún nínú mẹ́rìndínlógójì tò wà ní Gaza ló ń ṣiṣẹ́ díẹ̀ báyìí.

Gaza lẹ́yìn ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àtúnṣe Gaza

Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká ní UN (UNEP) ní ó máa gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí Gaza tó bọ̀ sípò.

UNEP ní kò sí omi tó ṣe é lò ní Gaza mọ́ báyìí nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan ìjà ogun ló ti ṣàkóbá fún ìpèsè omi.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé iye ìdọ̀tí tó ti wà níbẹ̀ báyìí tó àádọ́ta mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù ni ogun náà fà.

UNEP ní ó máa gbà wọ́n tó ọdún mọ́kànlélógún láti fi kó àwọnm ìdọ̀tí náà tán.

Máàpù bí ìdọ̀tí ṣe pọ̀ tó ní Gaza

Oríṣun àwòrán, UNEP and UNOSAT

Gaza lọ́dún 2022

Oríṣun àwòrán, Getty, IDF

Gaza lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, Getty, IDF